II. Kor 11:23-29
II. Kor 11:23-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iranṣẹ Kristi ni nwọn bi? (emi nsọ bi aṣiwère) mo ta wọn yọ; niti lãlã lọpọlọpọ, niti paṣan mo rekọja, niti tubu nigbakugba, niti ikú nigbapupọ. Nigba marun ni mo gbà paṣan ogoji dín kan lọwọ awọn Ju. Nigba mẹta li a fi ọgọ lù mi, ẹkanṣoṣo li a sọ mi li okuta, ẹ̃mẹta li ọkọ̀ rì mi, ọsán kan ati oru kan ni mo wà ninu ibú. Ni ìrin àjò nigbakugba, ninu ewu omi, ninu ewu awọn ọlọṣa, ninu ewu awọn ara ilu mi, ninu ewu awọn keferi, ninu ewu ni ilu, ninu ewu li aginjù, ninu ewu loju okun, ninu ewu larin awọn eke arakunrin; Ninu lãlã ati irora, ninu iṣọra nigbakugba, ninu ebi ati orùngbẹ, ninu àwẹ nigbakugba, ninu otutù ati ìhoho. Pẹlu nkan wọnni ti o wà lode, eyi ti nwọjọ tì mi li ojojumọ́, emi ko yé ṣe aniyan gbogbo ijọ. Tani iṣe alailera, ti emi kò ṣe alailera? tabi tali a mu kọsẹ̀, ti ara mi kò gbina?
II. Kor 11:23-29 Yoruba Bible (YCE)
Iranṣẹ Kristi ni wọ́n? Tí n óo bá sọ̀rọ̀ bí ẹni tí orí rẹ̀ kò pé, mo jù wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Kristi. Mo ti fi agbára ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ. Mo ti wẹ̀wọ̀n nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Wọ́n ti nà mí nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ bọ́ lẹ́nu mi ní ọpọlọpọ ìgbà. Ẹẹmarun-un ni àwọn Juu nà mí ní ẹgba mọkandinlogoji. Ẹẹmẹta ni a fi ọ̀pá lù mí. A sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan. Ẹẹmẹta ni ọkọ̀ ojú omi tí mo wọ̀ rì. Fún odidi ọjọ́ kan, tọ̀sán-tòru, ni mo fi wà ninu agbami. Ní ọpọlọpọ ìgbà ni mo wà lórí ìrìn àjò, tí mo wà ninu ewu omi, ewu lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, ewu láàrin àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ mi, ewu láàrin àwọn tíí ṣe Juu, ewu ninu ìlú, ewu ninu oko, ewu lójú òkun, ati ewu láàrin àwọn èké onigbagbọ. Mo ti rí ọ̀pọ̀ wahala ati ìṣòro. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni n kò lè sùn. Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò ń gbààwẹ̀. Mo mọ ìgbà òtútù ati ìgbà tí aṣọ kò tó láti fi bora. Láì ka àwọn nǹkan mìíràn tí n kò mẹ́nubà, lojoojumọ ni àníyàn gbogbo àwọn ìjọ wúwo lọ́kàn mi. Ta ni jẹ́ aláìlera tí n kò ní ìpín ninu àìlera rẹ̀? Ta ni ṣubú sinu ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkàn mi kò bàjẹ́?
II. Kor 11:23-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. Ní ìrìnàjò nígbàkúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkúgbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkúgbà, nínú òtútù àti ìhòhò. Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?