II. Kor 11:19-21
II. Kor 11:19-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ẹnyin fi inu didùn gbà awọn aṣiwère, nigbati ẹnyin tikaranyin jẹ ọlọ́gbọn. Nitori ẹnyin farada a bi ẹnikan ba sọ nyin di ondè, bi ẹnikan ba jẹ nyin run, bi ẹnikan ba gbà lọwọ nyin, bi ẹnikan ba gbé ara rẹ̀ ga, bi ẹnikan ba gbá nyin loju. Emi nwi lọna ẹ̀gan, bi ẹnipe awa jẹ alailera. Ṣugbọn ninu ohunkohun ti ẹnikan ni igboiya (emi nsọrọ were), emi ni igboiya pẹlu.
II. Kor 11:19-21 Yoruba Bible (YCE)
Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi ń gba àwọn aṣiwèrè, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n! Bí ẹnìkan bá ń lò yín bí ẹrú, tí ó ń jẹ yín run, tí ó fi okùn mu yín, tí ó ń ṣe fùkẹ̀ láàrin yín, tí ó ń gba yín létí, ẹ ṣetán láti gba irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ojú tì mí láti gbà pé àwa kò lágbára tó láti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀! Ṣugbọn bí ẹnìkan bá láyà láti fi ohun kan ṣe ìgbéraga, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ bí aṣiwèrè, èmi náà láyà láti ṣe ìgbéraga.
II. Kor 11:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera! Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú.