II. Kor 11:1-4
II. Kor 11:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo rò wí pé ẹ ó faradà díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ẹ gbà mí láàyè. Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìhìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.
II. Kor 11:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸNYIN iba gbà mi diẹ ninu wère mi: ati nitotọ, ẹ gbà mi. Nitoripe emi njowú lori nyin niti owú ẹni ìwa-bi-Ọlọrun: nitoriti mo ti fi nyin fun ọkọ kan, ki emi ki o le mu nyin wá bi wundia ti o mọ́ sọdọ Kristi. Ṣugbọn ẹru mba mi pe, li ohunkohun, gẹgẹ bi ejò ti tàn Efa jẹ nipasẹ arekereke rẹ̀, ki a maṣe mu ero-ọkàn nyin bajẹ kuro ninu inu kan ati iwa mimọ́ nyin si Kristi. Nitori bi ẹniti mbọ̀ wá ba nwãsu Jesu miran, ti awa kò ti wasu rí, tabi bi ẹnyin ba gbà ẹmí miran, ti ẹnyin kò ti gbà ri, tabi ihinrere miran, ti ẹnyin kò ti tẹwọgbà, ẹnyin iba ṣe rere lati fi ara da a.
II. Kor 11:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbà mí láyè kí n sọ̀rọ̀ díẹ̀ bí aṣiwèrè. Ẹ gbà mí láyè. Mò ń jowú nítorí yín, bí Ọlọrun tií jowú. Nítorí èmi ni mo ṣe ètò láti fà yín fún Kristi bí ẹni fa wundia tí ó pé fún ọkọ rẹ̀. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ẹ̀tàn má wọ inú ọkàn yín, tí ẹ óo fi yà kúrò ninu òtítọ́ ati ọkàn kan tí ẹ fi wà ninu Kristi, bí ejò ti fi àrékérekè rẹ̀ tan Efa jẹ. Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà.