II. Kor 10:4-6
II. Kor 10:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
(Nitori ohun ija wa kì iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;) Awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rẹ̀ ga si ìmọ Ọlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi; Awa si ti mura tan lati gbẹsan gbogbo aigbọran, nigbati igbọran nyin ba pé.
II. Kor 10:4-6 Yoruba Bible (YCE)
nítorí àwọn ohun-ìjà wa kì í ṣe ti ayé, agbára Ọlọrun ni, tí a lè fi wó ìlú olódi. À ń bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú, ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu. A sì ti múra tán láti jẹ gbogbo aláìgbọràn níyà, nígbà tí ẹ bá ti fi ara yín sábẹ́ wa.
II. Kor 10:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀. Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi. Àwa sì ti murá tan láti jẹ gbogbo àìgbọ́ràn ní yà, nígbà tí ìgbọ́ràn yín bá pé.