II. Kor 10:4-5
II. Kor 10:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
(Nitori ohun ija wa kì iṣe ti ara, ṣugbọn o li agbara ninu Ọlọrun lati wó ibi giga palẹ;) Awa nsọ gbogbo ero kalẹ, ati gbogbo ohun giga ti ngbé ara rẹ̀ ga si ìmọ Ọlọrun, awa si ndi gbogbo ero ni igbekun wá si itẹriba fun Kristi
II. Kor 10:4-5 Yoruba Bible (YCE)
nítorí àwọn ohun-ìjà wa kì í ṣe ti ayé, agbára Ọlọrun ni, tí a lè fi wó ìlú olódi. À ń bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú, ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu.