II. Kor 10:12-13
II. Kor 10:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe awa kò daṣa ati kà ara wa mọ́, tabi ati fi ara wa wé awọn miran ninu wọn ti ńyìn ara wọn; ṣugbọn awọn tikarawọn jẹ alailoye nigbati nwọn nfi ara wọn diwọn ara wọn, ti nwọn si nfi ara wọn wé ara wọn. Ṣugbọn awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, ṣugbọn nipa ãlà ti Ọlọrun ti pín fun wa, ani ãlà kan lati de ọdọ nyin.
II. Kor 10:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí a kò gbọdọ̀ da ara wa mọ́ àwọn kan tí wọn ń yin ara wọn, tabi kí á fara wé wọn. Fúnra wọn ni wọ́n ṣe òṣùnwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn ara wọn, àwọn tìkalára wọn náà ni wọ́n sì ń fi ara wọn wé. Wọn kò lóye. Ṣugbọn ní tiwa, a kò ní lérí ju bí ó ti yẹ lọ. Òṣùnwọ̀n wa kò tayọ ààlà tí Ọlọrun ti pa sílẹ̀ fún wa, tí a fi mú ìyìn rere dé ọ̀dọ̀ yín.
II. Kor 10:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnrawọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn. Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín.