II. Kor 10:11-18
II. Kor 10:11-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki irú enia bẹ̃ ki o ro bayi pe, irú ẹniti awa iṣe li ọ̀rọ nipa iwe-kikọ nigbati awa kò si, irú bẹ̃li awa o si jẹ ni iṣe pẹlu nigbati awa ba wà. Nitoripe awa kò daṣa ati kà ara wa mọ́, tabi ati fi ara wa wé awọn miran ninu wọn ti ńyìn ara wọn; ṣugbọn awọn tikarawọn jẹ alailoye nigbati nwọn nfi ara wọn diwọn ara wọn, ti nwọn si nfi ara wọn wé ara wọn. Ṣugbọn awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, ṣugbọn nipa ãlà ti Ọlọrun ti pín fun wa, ani ãlà kan lati de ọdọ nyin. Nitori awa kò nawọ́ wa rekọja rara, bi ẹnipe awa kò de ọdọ nyin: nitori awa tilẹ de ọdọ nyin pẹlu ninu ihinrere Kristi. Awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, eyini ni lori iṣẹ ẹlomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ nyin ti ndagba si i, gẹgẹ bi àla wa awa o di gbigbega lọdọ nyin si i lọpọlọpọ, Ki a ba le wasu ihinrere ani ni ẹkùn ti mbẹ niwaju nyin, ki a má si ṣogo ninu ãlà ẹlomiran nipa ohun ti o wà li arọwọto. Ṣugbọn ẹniti o ba nṣogo, ki o mã ṣogo ninu Oluwa. Nitoripe kì iṣe ẹniti nyìn ara rẹ̀ li o yanju, bikoṣe ẹniti Oluwa yìn.
II. Kor 10:11-18 Yoruba Bible (YCE)
Kí ẹni tí ó bá ń rò báyìí mọ̀ pé bí a ti jẹ́ ninu ọ̀rọ̀ tí a kọ sinu ìwé nígbà tí a kò sí lọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ náà ni a jẹ́ ninu iṣẹ́ wa nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ yín. Nítorí a kò gbọdọ̀ da ara wa mọ́ àwọn kan tí wọn ń yin ara wọn, tabi kí á fara wé wọn. Fúnra wọn ni wọ́n ṣe òṣùnwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn ara wọn, àwọn tìkalára wọn náà ni wọ́n sì ń fi ara wọn wé. Wọn kò lóye. Ṣugbọn ní tiwa, a kò ní lérí ju bí ó ti yẹ lọ. Òṣùnwọ̀n wa kò tayọ ààlà tí Ọlọrun ti pa sílẹ̀ fún wa, tí a fi mú ìyìn rere dé ọ̀dọ̀ yín. Nítorí kì í ṣe pé a kọjá àyè wa nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, àwa ni a sì kọ́kọ́ mú ìyìn rere Kristi dé ọ̀dọ̀ yín. A kò gbọdọ̀ ṣe ìgbéraga pupọ ju bí ó ti yẹ lọ lórí iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn. A ní ìrètí pé bí igbagbọ yín ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ipò wa pẹlu yín yóo máa ga sí i, gẹ́gẹ́ bí ààyè wa. A óo wá mú ọ̀rọ̀ ìyìn rere kọjá ọ̀dọ̀ yín, láì ṣe ìgbéraga nípa iṣẹ́ tí ẹlòmíràn ti ṣe ní ààyè tirẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí yóo bá ṣe ìgbéraga, Oluwa ni kí ó fi ṣe ìgbéraga. Kì í ṣe ẹni tí ó yin ara rẹ̀ ni ó yege, bíkòṣe ẹni tí Oluwa bá yìn.
II. Kor 10:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé, irú ẹni tí àwa jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ nípa ìwé kíkọ nígbà tí àwa kò sí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa sì jẹ́ nínú iṣẹ́ pẹ̀lú nígbà ti àwa bá wà. Nítorí pé àwa kò dáṣà láti ka ara wa mọ́, tàbí láti fi ara wa wé àwọn mìíràn nínú wọn tí ń yin ara wọn; ṣùgbọ́n àwọn fúnrawọn jẹ́ aláìlóye bí wọn ti ń fi ara wọn díwọ̀n ara wọ́n, tí wọ́n sì ń fi ara wọn wé ara wọn. Ṣùgbọ́n àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, ṣùgbọ́n nípa ààlà ìwọ̀n tí Ọlọ́run ti pín fún wa, èyí tí ó mú kí ó ṣe é ṣe láti dé ọ̀dọ̀ yín. Nítorí àwa kò nawọ́ wa rékọjá rárá, bí ẹni pé àwa kò dé ọ̀dọ̀ yín: nítorí àwa tilẹ̀ dé ọ̀dọ̀ yín pẹ̀lú nínú ìhìnrere Kristi. Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀. Kí a bá à lè wàásù ìhìnrere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó. “Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.” Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní ìtẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.