II. Kor 1:8-10
II. Kor 1:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ará, awa kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li aimọ̀ nipa wahalà wa, ti o dé bá wa ni Asia, niti pe a pọ́n wa loju gidigidi rekọja agbara wa, tobẹ̃ ti ireti kò tilẹ si fun ẹmi wa mọ́: Ṣugbọn awa ni idahùn ikú ninu ara wa, ki awa ki o máṣe gbẹkẹle ara wa, bikoṣe Ọlọrun ti njí okú dide: Ẹniti o ti gbà wa kuro ninu ikú ti o tobi tobẹ̃, ti o si ngbà wa: ẹniti awa gbẹkẹ wa le pe yio si mã gbà wa sibẹsibẹ
II. Kor 1:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́. A ṣe bí wọ́n tí dá wa lẹ́bi ikú ni. Kí á má baà gbẹ́kẹ̀lé ara wa, bíkòṣe Ọlọrun, ni ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Nítorí Ọlọrun níí jí òkú dìde. Ọlọrun ni ó yọ wá ninu ewu ńlá náà, òun ni yóo sì máa yọ wá. Òun ni a ní ìrètí ninu rẹ̀; yóo sì tún máa yọ wá
II. Kor 1:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde: Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀