II. Kor 1:3-5
II. Kor 1:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo; Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu. Nitoripe bi ìya Kristi ti di pipọ ninu wa, gẹgẹ bẹ̃ni itunu wa di pipọ pẹlu nipa Kristi.
II. Kor 1:3-5 Yoruba Bible (YCE)
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba aláàánú ati Ọlọrun orísun ìtùnú, ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti ní ìpín ninu ọpọlọpọ ìyà Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní ọpọlọpọ ìwúrí nípasẹ̀ Kristi.
II. Kor 1:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi.