II. Kro 7:11-22

II. Kro 7:11-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

Solomoni si pari ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ohun ti o wá si ọkàn Solomoni lati ṣe ninu ile Oluwa, ati ninu ile on tikararẹ̀, o si ṣe e jalẹ. Oluwa si fi ara hàn Solomoni li oru, o si wi fun u pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti yàn ihinyi fun ara mi, fun ile ẹbọ. Bi mo ba sé ọrun ti kò ba si òjo, tabi bi emi ba paṣẹ fun eṣú lati jẹ ilẹ na run, tabi bi mo ba rán àjakalẹ-arun si ãrin awọn enia mi; Bi awọn enia mi ti a npè orukọ mi mọ́, ba rẹ̀ ara wọn silẹ, ti nwọn ba si gbadura, ti nwọn ba si wá oju mi, ti nwọn ba si yipada kuro ninu ọ̀na buburu wọn; nigbana ni emi o gbọ́ lati ọrun wá, emi o si dari ẹ̀ṣẹ wọn jì, emi o si wò ilẹ wọn sàn. Nisisiyi oju mi yio ṣí, eti mi yio si tẹ́ si adura ibi yi. Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ́, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo. Ati iwọ, bi iwọ o ba rìn niwaju mi bi Dafidi, baba rẹ ti rìn, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, bi iwọ o ba si ṣe akiyesi aṣẹ mi ati idajọ mi; Nigbana ni emi o fi idi itẹ ijọba rẹ múlẹ̀, gẹgẹ bi emi ti ba Dafidi, baba rẹ dá majẹmu, wipe, a kì yio fẹ ẹnikan kù fun ọ ti yio ma ṣe akoso ni Israeli. Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada, ti ẹ ba si kọ̀ aṣẹ mi ati ofin mi silẹ, ti emi ti gbé kalẹ niwaju nyin, ti ẹnyin ba si sin ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn; Nigbana ni emi o fà wọn tu ti-gbongbo-ti-gbongbo kuro ni ilẹ ti emi ti fi fun wọn; ati ile yi, ti emi ti yà si mimọ́ fun orukọ mi, li emi o ta nù kuro niwaju mi, emi o si sọ ọ di owe, ati ọ̀rọ-ẹgan larin gbogbo orilẹ-ède. Ati ile yi, ti o ga, yio di ohun iyanu fun gbogbo ẹni ti o gba ibẹ kọja; tobẹ̃ ti yio si wipe, ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi, ati si ile yi? A o si dahùn wipe, Nitori ti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, Ẹniti o mu wọn ti ilẹ Egipti jade wá, ti nwọn si di ọlọrun miran mu, ti nwọn si bọ wọn, ti nwọn si sìn wọn: nitorina li o ṣe mu gbogbo ibi yi ba wọn.

II. Kro 7:11-22 Yoruba Bible (YCE)

Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sí ilé OLUWA ati sí ilé ti ara rẹ̀, ni ó ṣe ní àṣeyọrí. Lẹ́yìn náà, OLUWA fara han Solomoni lóru, ó ní, “Mo ti gbọ́ adura rẹ, mo sì ti yan ibí yìí ní ilé ìrúbọ fúnra mi. Nígbà tí mo bá sé ojú ọ̀run, tí òjò kò bá rọ̀, tabi tí mo pàṣẹ fún eṣú láti ba oko jẹ́, tabi tí mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin àwọn eniyan mi, bí àwọn eniyan mi, tí à ń fi orúkọ mi pè, bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì wá ojurere mi, tí wọ́n bá yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú wọnyi; n óo gbọ́ láti ọ̀run, n óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n óo sì wo ilẹ̀ wọn sàn. Nisinsinyii, n óo fojú sílẹ̀, etí mi yóo sì ṣí sí adura tí wọ́n bá gbà níbí yìí. Mo ti yan ibí yìí, mo sì ti yà á sí mímọ́, kí á lè máa jọ́sìn ní orúkọ mi níbẹ̀ títí lae. Ojú ati ọkàn mi yóo wà níbẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn, bí ìwọ bá tẹ̀lé ìlànà mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o tẹ̀lé ìlànà ati àṣẹ mi, n óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀, bí mo ti bá Dafidi, baba rẹ, dá majẹmu pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli. Ṣugbọn tí o bá yipada kúrò lọ́dọ̀ mi, tí o kọ àṣẹ mi ati òfin tí mo ṣe fún ọ sílẹ̀, tí o sì ń lọ bọ oriṣa, tí ò ń foríbalẹ̀ fún wọn, n óo fà yín tu kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fun yín bí ẹni fa igi tu. N óo sì kọ tẹmpili yìí, tí mo ti yà sí mímọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi sílẹ̀, nítorí pé yóo di ohun ẹ̀gàn ati àmúpòwe láàrin gbogbo eniyan. “Tẹmpili yìí gbayì gidigidi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà náà, àwọn ẹni tó bá ń rékọjá lọ yóo máa sọ tìyanu-tìyanu pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati sí tẹmpili yìí?’ Àwọn eniyan yóo dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn sílẹ̀, tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n ń lọ bọ oriṣa, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún wọn. Ìdí nìyí tí ibi yìí fi bá wọn.’ ”

II. Kro 7:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Solomoni ti parí ilé OLúWA àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé OLúWA àti nínú ilé òun tìkára rẹ̀, OLúWA sì farahàn Solomoni ní òru ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ. “Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma bá à sí òjò, tàbí láti pàṣẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín àwọn ènìyàn mi, tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn. Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí. Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé. “Ní ti bí ìwọ bá rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, tí o sì ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ, tí ìwọ sì ṣe àkíyèsí àṣẹ mi láti ọ̀run: Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe pẹ̀lú Dafidi baba rẹ nígbà tí mo bá a dá májẹ̀mú wí pé, ìwọ kò ní fẹ́ ẹnìkan kù láti ṣe alákòóso lórí Israẹli. “Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá yípadà tí o sì kọ òfin mi sílẹ̀ àti àṣẹ tí mo ti fi fún yín tí ẹ sì lọ sókè láti lọ sin ọlọ́run mìíràn tí ẹ sì bọ wọ́n, Nígbà náà ni èmi yóò fa Israẹli tu kúrò láti ilẹ̀ mi, èyí tí èmi ti fi fún wọn, èmi yóò sì kọ̀ ilé náà sílẹ̀ èyí tí èmi ti yà sọ́tọ̀ fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ṣe ọ̀rọ̀ òwe, n ó fi ṣe ẹlẹ́yà láàrín gbogbo ènìyàn, Àti ní gbogbo àyíká ilé yìí nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni yóò di ohun ìtànjẹ; gbogbo àwọn tí ó bá sì kọjá níbẹ̀ ni yóò jáláyà, wọn yóò sì wí pé, ‘Kí ni ó dé tí OLúWA fì ṣe irú èyí sí ilẹ̀ yí àti sí ilé yìí?’ Àwọn ènìyàn yóò sì dáhùn wí pé: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ OLúWA sílẹ̀, Ọlọ́run baba wọn ẹni tí ó mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n sì ti fi ọwọ́ gba ọlọ́run mìíràn mọ́ra, wọ́n bọ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń sìn wọ́n, ìdí nìyí tí ó fi mú gbogbo ìjàǹbá náà wá sórí wọn.’ ”