II. Kro 7:11-16
II. Kro 7:11-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Solomoni si pari ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ohun ti o wá si ọkàn Solomoni lati ṣe ninu ile Oluwa, ati ninu ile on tikararẹ̀, o si ṣe e jalẹ. Oluwa si fi ara hàn Solomoni li oru, o si wi fun u pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti yàn ihinyi fun ara mi, fun ile ẹbọ. Bi mo ba sé ọrun ti kò ba si òjo, tabi bi emi ba paṣẹ fun eṣú lati jẹ ilẹ na run, tabi bi mo ba rán àjakalẹ-arun si ãrin awọn enia mi; Bi awọn enia mi ti a npè orukọ mi mọ́, ba rẹ̀ ara wọn silẹ, ti nwọn ba si gbadura, ti nwọn ba si wá oju mi, ti nwọn ba si yipada kuro ninu ọ̀na buburu wọn; nigbana ni emi o gbọ́ lati ọrun wá, emi o si dari ẹ̀ṣẹ wọn jì, emi o si wò ilẹ wọn sàn. Nisisiyi oju mi yio ṣí, eti mi yio si tẹ́ si adura ibi yi. Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ́, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo.
II. Kro 7:11-16 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sí ilé OLUWA ati sí ilé ti ara rẹ̀, ni ó ṣe ní àṣeyọrí. Lẹ́yìn náà, OLUWA fara han Solomoni lóru, ó ní, “Mo ti gbọ́ adura rẹ, mo sì ti yan ibí yìí ní ilé ìrúbọ fúnra mi. Nígbà tí mo bá sé ojú ọ̀run, tí òjò kò bá rọ̀, tabi tí mo pàṣẹ fún eṣú láti ba oko jẹ́, tabi tí mo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin àwọn eniyan mi, bí àwọn eniyan mi, tí à ń fi orúkọ mi pè, bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì wá ojurere mi, tí wọ́n bá yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú wọnyi; n óo gbọ́ láti ọ̀run, n óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n óo sì wo ilẹ̀ wọn sàn. Nisinsinyii, n óo fojú sílẹ̀, etí mi yóo sì ṣí sí adura tí wọ́n bá gbà níbí yìí. Mo ti yan ibí yìí, mo sì ti yà á sí mímọ́, kí á lè máa jọ́sìn ní orúkọ mi níbẹ̀ títí lae. Ojú ati ọkàn mi yóo wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.
II. Kro 7:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Solomoni ti parí ilé OLúWA àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé OLúWA àti nínú ilé òun tìkára rẹ̀, OLúWA sì farahàn Solomoni ní òru ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ. “Nígbà tí mo bá sé ọ̀run kí ó ma bá à sí òjò, tàbí láti pàṣẹ fún eṣú láti jẹ ilẹ̀ náà run tàbí rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín àwọn ènìyàn mi, tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn. Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí. Èmi sì ti yàn, èmi sì ti ya ilé yìí sí mímọ́ bẹ́ẹ̀ ni kí orúkọ mi kí ó le wà níbẹ̀ títí láéláé.