II. Kro 6:1-42

II. Kro 6:1-42 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Solomoni wipe, Oluwa ti wipe, on o ma gbe inu òkunkun biribiri. Ṣugbọn emi ti kọ́ ile ibugbe kan fun ọ, ati ibi kan fun ọ lati ma gbe titi lai. Ọba si yi oju Rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ awọn enia Israeli; gbogbo ijọ awọn enia Israeli si dide duro. O si wipe, Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ọwọ rẹ̀ mu eyi ti o ti fi ẹnu rẹ̀ sọ fun Dafidi baba mi ṣẹ, wipe, Lati ọjọ ti emi ti mu awọn enia mi jade kuro ni ilẹ Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli lati kọ́ ile, ki orukọ mi ki o wà nibẹ; bẹ̃ni emi kò yàn ọkunrin kan lati ṣe olori Israeli awọn enia mi: Ṣugbọn emi ti yàn Jerusalemu, ki orukọ mi ki o le wà nibẹ; mo si ti yàn Dafidi lati wà lori Israeli, enia mi. O si ti wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli: Oluwa si sọ fun Dafidi baba mi pe, nitoriti o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile fun orukọ mi, iwọ ṣeun li eyiti o wà li ọkàn rẹ. Sibẹ iwọ kò gbọdọ kọ́ ile na; ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio jade ti inu rẹ wá ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi. Oluwa si ti mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ; emi si dide ni ipò Dafidi baba mi, a si gbé mi ka itẹ́ Israeli bi Oluwa ti ṣe ileri, emi si ti kọ́ ile na fun orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli. Ati ninu rẹ̀ ni mo fi apoti-ẹri na si, ninu eyiti majẹmu Oluwa wà, ti o ba awọn ọmọ Israeli dá. On si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ ọwọ rẹ̀ mejeji. Nitori Solomoni ṣe aga idẹ kan, igbọnwọ marun ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni gbigboro, ati igbọnwọ mẹta ni giga, o si gbé e si ãrin agbala na; lori rẹ̀ li o duro, o si kunlẹ lori ẽkun rẹ̀ niwaju gbogbo ijọ enia Israeli, o si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji soke ọrun, O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ li ọrun tabi li aiye: ti npa majẹmu mọ́, ati ãnu fun awọn iranṣẹ rẹ, ti nfi tọkàntọkan wọn rìn niwaju rẹ. Iwọ ti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi baba mi, pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́; ti iwọ si ti fi ẹnu rẹ sọ, ti iwọ si ti fi ọwọ rẹ mu u ṣẹ, bi o ti ri loni yi. Njẹ nisisiyi, Oluwa, Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́, wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ́ Israeli: kiki bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati ma rìn ninu ofin mi, bi iwọ ti rìn niwaju mi. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ, ti iwọ ti sọ fun Dafidi, iranṣẹ rẹ, Ni otitọ ni Ọlọrun yio ha ma ba enia gbe li aiye? Kiyesi i, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti emi kọ́! Sibẹ, iwọ ṣe afiyesi adura iranṣẹ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati adura ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ: Ki oju rẹ ki o le ṣí si ile yi lọsan ati loru, ani si ibi ti iwọ ti wipe, iwọ o fi orukọ rẹ sibẹ; lati tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ ngbà si ibi yi. Nitorina gbọ́ ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati ti Israeli enia rẹ ti nwọn o ma gbà si ibi yi: iwọ gbọ́ lati ibugbe rẹ wá, ani lati ọrun wá, nigbati iwọ ba gbọ́, ki o si dariji. Bi ọkunrin kan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, ti ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi; Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni sisan a fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ pada sori on tikararẹ̀; ati ni didare fun olododo, lati fifun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀. Bi a ba si fọ́ awọn enia rẹ Israeli bajẹ niwaju ọta, nitori ti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ti nwọn ba si pada ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ niwaju rẹ ni ile yi; Nigbana ni ki o gbọ́ lati ọrun wá, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun wọn ati fun awọn baba wọn. Nigbati a ba se ọrun mọ́ ti kò si sí òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ; ṣugbọn bi nwọn ba gbadura si ibi yi, ti nwọn ba jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nitoriti iwọ pọn wọn loju. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ ji, ati ti Israeli enia rẹ, nigbati iwọ ba ti kọ́ wọn li ọ̀na rere na, ninu eyiti nwọn o ma rìn: ki o si rọ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun awọn enia rẹ ni ini. Bi ìyan ba mu ni ilẹ, bi àjakalẹ-arun ba wà, bi irẹ̀danu ba wà, tabi eṣú ti njẹrun, bi awọn ọta wọn ba yọ wọn li ẹnu ni ilẹ ilu wọn; oniruru ipọnju tabi oniruru àrun. Adura ki adura, tabi ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ ti a ba ti ọdọ ẹnikẹni gbà, tabi ọdọ gbogbo Israeli enia rẹ, nigbati olukuluku ba mọ̀ ipọnju rẹ̀, ati ibanujẹ rẹ̀, ti o ba si tẹ́ ọwọ rẹ̀ mejeji siha ile yi: Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ibugbe rẹ wá, ki o si dariji, ki o si san a fun olukuluku gẹgẹ bi gbogbo ọ̀na rẹ̀, bi iwọ ti mọ̀ ọkàn rẹ̀; (nitori iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn awọn ọmọ enia:) Ki nwọn ki o le bẹ̀ru rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ, li ọjọ gbogbo ti nwọn o wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa. Pẹlupẹlu niti alejo, ti kì iṣe inu Israeli, enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ òkere jade wá nitori orukọ nla rẹ, ati ọwọ agbara rẹ ati ninà apa rẹ; bi nwọn ba wá ti nwọn ba si gbadura siha ile yi: Ki iwọ ki o gbọ́ lati ọrun, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejo na kepe ọ si; ki gbogbo enia aiye ki o le mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o si le ma bẹ̀ru rẹ̀, bi Israeli enia rẹ, ki nwọn ki o le mọ̀ pe orukọ rẹ li a npè mọ ile yi ti emi kọ́. Bi awọn enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọta wọn li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, ti nwọn ba si gbadura si ọ, siha ilu yi, ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ: Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wa, ki o si mu ọ̀ran wọn duro. Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ (nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀,) bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le awọn ọta lọwọ, ti nwọn ba si kó wọn ni igbekun lọ si ilẹ ti o jìna rére, tabi ti o wà nitosi. Ṣugbọn, bi nwọn ba rò inu ara wọn wò, ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbekun lọ, ti nwọn ba si yipada, ti nwọn ba si gbadura si ọ li oko ẹrú wọn, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣìṣe, awa si ti ṣe buburu; Bi nwọn ba si fi gbogbo aiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ li oko ẹrú wọn, si ibi ti a gbe kó wọn lọ, ti nwọn ba si gbadura siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ati siha ilu na ti iwọ ti yàn, ati siha ile na ti emi ti kọ́ fun orukọ rẹ: Ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn lati ọrun wá, ani lati ibugbe rẹ wá, ki o si mu ọ̀ran wọn duro, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn enia rẹ jì ti nwọn ti da si ọ. Nisisiyi Ọlọrun mi, jẹ ki oju rẹ ki o ṣí, ki o si tẹtisilẹ si adura si ihinyi. Njẹ nisisiyi, dide, Oluwa Ọlọrun si ibi isimi rẹ, iwọ ati apoti agbara rẹ; jẹ ki a fi igbala wọ̀ awọn alufa rẹ, Oluwa Ọlọrun, ki o si jẹ ki awọn enia ayanfẹ rẹ ki o ma yọ̀ ninu ire. Oluwa Ọlọrun, máṣe yi oju ẹni ororo rẹ pada: ranti ãnu fun Dafidi, iranṣẹ rẹ.

II. Kro 6:1-42 Yoruba Bible (YCE)

Solomoni ọba ní, “OLUWA, o ti sọ pé o óo máa gbé inú òkùnkùn biribiri. Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti kọ́ ilé kan tí ó lógo fún ọ, ibi tí o óo máa gbé títí lae.” Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli wà níbẹ̀, ọba bá yíjú pada sí wọn, ó sì gbadura fún wọn. Lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ohun gbogbo tí ó wí fún Dafidi, baba mi, ṣẹ fúnrarẹ̀, nítorí ó wí pé, ‘Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn eniyan jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, n kò tíì yan ìlú kankan ninu ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé sí fún ìjọ́sìn ní orúkọ mi, bẹ́ẹ̀ ni n kò yan ẹnìkan kan láti jẹ́ olórí àwọn eniyan mi. Ṣugbọn nisinsinyii, mo yan Jerusalẹmu fún ibi ìjọ́sìn ní orúkọ mi, mo sì ti yan Dafidi láti jẹ́ olórí Israẹli, eniyan mi.’ ” Ó wu Dafidi, baba mi, láti kọ́ ilé kan fún ìjọ́sìn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ṣugbọn OLUWA sọ fún baba mi pé nǹkan dáradára ni pé ó wù ú lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún òun Ọlọrun, ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé náà, ọmọ bíbí inú rẹ̀ ni yóo kọ́ ilé fún òun. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Mo ti wà ní ipò baba mi, mo ti gorí ìtẹ́ ọba Israẹli, bí OLUWA ti ṣèlérí, mo sì ti kọ́ tẹmpili fún OLUWA Ọlọrun Israẹli. Mo ti gbé àpótí ẹ̀rí sibẹ, inú rẹ̀ sì ni majẹmu tí OLUWA bá àwọn eniyan Israẹli dá wà.” Lẹ́yìn náà, Solomoni dúró níwájú pẹpẹ lójú gbogbo eniyan, ó gbé ọwọ́ mejeeji sókè, ó sì gbadura sí Ọlọrun. Solomoni ti ṣe pẹpẹ bàbà kan, ó gbé e sí àgbàlá ilé náà. Gígùn ati ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta (1.3 mita). Solomoni gun orí pẹpẹ yìí, níbi tí gbogbo eniyan ti lè rí i. Ó kúnlẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Ọlọrun; ó bá gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run tabi ní ayé, ìwọ tí ò ń pa majẹmu mọ́, tí o sì ń fi ìfẹ́ ńlá han àwọn iranṣẹ rẹ, tí wọn ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé ìlànà rẹ. O ti mú ìlérí rẹ ṣẹ fún baba mi, Dafidi, iranṣẹ rẹ. O fi ẹnu rẹ ṣèlérí, o sì ti fi ọwọ́ ara rẹ mú ìlérí náà ṣẹ lónìí. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, jẹ́ kí ìlérí tí o ṣe fún Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, ìran rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọn bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣe. Nisinsinyii, jọ̀wọ́ Ọlọrun Israẹli, mú ọ̀rọ̀ rẹ tí o sọ fún Dafidi, iranṣẹ rẹ ṣẹ. “Ṣugbọn ṣé ìwọ Ọlọrun yóo máa bá eniyan gbé lórí ilẹ̀ ayé? Bí ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́, mélòó mélòó ni ilé tí mo kọ́ yìí? Sibẹsibẹ, jọ̀wọ́ fetí sí adura ati ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ. OLUWA Ọlọrun mi, gbọ́ igbe èmi iranṣẹ rẹ, ati adura tí mò ń gbà níwájú rẹ. Máa bojútó ilé yìí tọ̀sán-tòru. O ti sọ pé ibẹ̀ ni àwọn eniyan yóo ti máa jọ́sìn ní orúkọ rẹ. Jọ̀wọ́ máa gbọ́ adura tí èmi iranṣẹ rẹ bá gbà nígbà tí mo bá kọjú sí ilé yìí. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ, ati ti Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ibí yìí láti gbadura. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa láti ibùgbé rẹ ní ọ̀run, kí o sì dáríjì wá. “Bí ẹnìkan bá ṣẹ aládùúgbò rẹ̀, tí a sì mú un wá kí ó wá búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé yìí, OLUWA, gbọ́ láti ọ̀run, kí o ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá ṣẹ̀ níyà bí ó ti tọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí o dá ẹni tí kò ṣẹ̀ láre gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀. “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn eniyan rẹ lójú ogun nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ ọ́, ṣugbọn bí wọ́n bá ronupiwada, tí wọ́n ranti orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ ninu ilé yìí, jọ̀wọ́ gbọ́ láti ọ̀run, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada sórí ilẹ̀ tí o ti fún àwọn ati àwọn baba wọn. “Nígbà tí òjò bá kọ̀ tí kò rọ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ ṣẹ̀, bí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé o ti jẹ wọ́n níyà, jọ̀wọ́, gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dáríjì àwọn eniyan Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ. Tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa tọ̀, kí o sì jẹ́ kí òjò rọ̀ sí ilẹ̀ tí o fún àwọn eniyan rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. “Nígbàkúùgbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tabi ọ̀gbẹlẹ̀, tabi ìrẹ̀dànù ohun ọ̀gbìn, tabi eṣú, tabi kòkòrò tíí máa jẹ ohun ọ̀gbìn; tabi tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti èyíkéyìí ninu àwọn ìlú wọn, irú ìyọnu tabi àìsàn yòówù tí ó lè jẹ́, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan, tabi ti gbogbo Israẹli, eniyan rẹ, lẹ́yìn tí olukuluku ti mọ ìṣòro ati ìbànújẹ́ rẹ̀, bí wọ́n bá gbé ọwọ́ adura wọn sókè sí ìhà ilé yìí, jọ̀wọ́, gbọ́ láti ilé rẹ ní ọ̀run, dáríjì wọ́n, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ni o mọ ọkàn ọmọ eniyan. Kí àwọn eniyan rẹ lè máa bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa. “Bákan náà, nígbà tí àwọn àjèjì, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, bá ti ọ̀nà jíjìn wá, láti gbadura sí ìhà ilé yìí, nítorí orúkọ ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ńlá, ati agbára rẹ, gbọ́ láti ibùgbé rẹ lọ́run; kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà bá ń tọrọ lọ́dọ̀ rẹ, kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, kí wọ́n lè mọ̀ pé ilé ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, ni ilé tí mo kọ́ yìí. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ sójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn, láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà, tí wọ́n bá kọjú sí ìhà ìlú tí o ti yàn yìí ati sí ìhà ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ yìí, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì jà fún wọn. “Bí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í ṣẹ̀), tí inú bá bí ọ sí wọn, tí o sì mú kí àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ọ̀nà jíjìn tabi nítòsí, sibẹ, tí wọ́n bá ranti, tí wọ́n sì ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ tí wọ́n sọ pé, ‘àwọn ti ṣẹ̀, àwọn ti hu ìwà tí kò tọ́, àwọn sì ti ṣe burúkú,’ tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ninu ìgbèkùn níbi tí a kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n gbadura sí ìhà ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wọn, ati sí ìlú tí o ti yàn, ati sí ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, jà fún àwọn eniyan rẹ, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ jì wọ́n. “Nisinsinyii, Ọlọrun mi, bojúwò wá kí o sì tẹ́tí sí adura tí wọ́n bá gbà níhìn-ín. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun, dìde, lọ sí ibùjókòó rẹ, ìwọ ati àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Gbé ìgbàlà rẹ wọ àwọn alufaa rẹ bí ẹ̀wù, kí o sì jẹ́ kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ yọ̀ ninu ire rẹ. Áà! OLUWA Ọlọrun, má ṣe kọ ẹni tí a fi òróró yàn, ranti ìfẹ́ rẹ tí kìí yẹ̀ sí Dafidi, iranṣẹ rẹ.”

II. Kro 6:1-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Solomoni wí pé, “OLúWA ti sọ wí pé òun yóò máa gbé nínú òkùnkùn tí ó ṣú biribiri; ṣùgbọ́n èmi ti kọ́ tẹmpili dáradára fún ọ ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láé.” Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Israẹli dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn. Nígbà náà ni ó sì wí pé: “Ògo ni fún OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé, ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ti yan Jerusalẹmu, kí orúkọ mi le è wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dafidi láti jẹ ọba lórí Israẹli ènìyàn mi.’ “Baba mi Dafidi ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili fún orúkọ OLúWA, àní Ọlọ́run Israẹli. Ṣùgbọ́n OLúWA sọ fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹmpili yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹmpili náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ: òun ni yóò kọ́ tẹmpili fún orúkọ mi.’ “OLúWA sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dafidi baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹmpili fún orúkọ OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti OLúWA bá àwọn Israẹli ènìyàn mi dá wà.” Nígbà naà ni Solomoni dúró níwájú pẹpẹ OLúWA, ní iwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. Solomoni ṣe àga idẹ kan tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gíga, a gbé e sí àárín àgbàlá ti òde. Ó sì dúró ní orí rẹ̀, àti pé ó kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí òkè ọ̀run. Ó wí pé: “OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ ní ọ̀run àti ní ayé: ìwọ tí o pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi tọkàntọkàn wọn rìn ní ọ̀nà rẹ. Ìwọ tí o pa ìlérí tí o ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi mọ́; nítorí ìwọ ti fi ẹnu rẹ ṣe ìlérí àti pé ìwọ ti fi ọwọ́ rẹ mú un ṣẹ; bí ó ti rí lónìí yìí. “Nísinsin yìí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, pa ìlérí tí ó ti ṣe mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi nígbà tí o wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ kù láti ní ọkùnrin láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n bá kíyèsi ara nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe láti rìn níwájú mi gẹ́gẹ́ bí òfin mi gẹ́gẹ́ bí o sì ti ṣe.’ Nísinsin yìí, OLúWA Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi kí ó wá sí ìmúṣẹ. “Ṣùgbọ́n ṣé Ọlọ́run nítòótọ́ yóò máa bá àwọn ènìyàn gbé lórí ilẹ̀ ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run gíga kò le gbà ọ́. Báwo ni ó ṣe kéré tó, ilé OLúWA tí mo ti kọ́! Síbẹ̀ ṣe àfiyèsí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún àánú, OLúWA Ọlọ́run mi, gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ. Kí ojú rẹ kí ó lè ṣí sí ilé OLúWA ní ọ̀sán àti lóru, ní ibí yìí tí ìwọ ti wí pé ìwọ yóò fi orúkọ rẹ síbẹ̀. Kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà lórí ibí yìí. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti àwọn ènìyàn Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà lórí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run, ibùgbé rẹ, nígbà tí ìwọ bá sì gbọ́, dáríjì. “Nígbà tí ọkùnrin kan bá dẹ́ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì mú búra, tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí, Nígbà naà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dáhùn. Ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, san padà fún ẹni tí ó jẹ̀bi nípa mímú padà wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe. Ṣe ìdáláre fún olódodo, bẹ́ẹ̀ sì ni, fi fún un gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀. “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli bá ní ìjákulẹ̀ níwájú àwọn ọ̀tá nítorí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ àti nígbà tí wọ́n bá sì yípadà, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ nínú ilé OLúWA yìí, Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn Israẹli jì wọ́n kí o sì mú wọn padà wá sílé tí o ti fi fún wọn àti àwọn baba wọn. “Nígbà tí a bá ti ọ̀run tí kò sì sí òjò nítorí àwọn ènìyàn rẹ ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, Nígbà tí wọ́n bá sì gbàdúrà sí ibí yìí tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ nínú èyí tí wọn ó máa rìn, kí o sì rọ òjò sórí ilẹ̀ tí o ti fi fún àwọn ènìyàn rẹ fún ìní. “Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí ẹlẹ́ǹgà, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá wọn bá yọ wọ́n lẹ́nu nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú wọn, ohunkóhun, ìpọ́njú tàbí ààrùn lè wá. Nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni àwọn ènìyàn rẹ Israẹli olúkúlùkù mọ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀ àti ìbànújẹ́, tí ó sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé OLúWA yìí. Nígbà náà gbọ́ láti ọ̀run ibùgbé rẹ dáríjì, kí o sì pín fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i gbogbo ohun tí ó ṣe, nígbà tí ìwọ ti mọ ọkàn rẹ̀ (nítorí ìwọ nìkan ni ó mọ ọkàn ènìyàn) Bẹ́ẹ̀ ni kí wọn kí ó lè bẹ̀rù rẹ kí wọn kí ó sì rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń gbé nínú ilé tí o ti fi fún àwọn baba wa. “Ní ti àwọn àlejò tí wọn kò sí lára àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ṣùgbọ́n tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn nítorí orúkọ ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá wá tí ó sì gbàdúrà pẹ̀lú kíkojú si ilé OLúWA yìí. Nígbà náà, gbọ́ láti ọ̀run àní láti ibi ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe ohun tí àwọn àlejò béèrè lọ́wọ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni kí gbogbo àwọn ènìyàn ayé kí wọn lè mọ orúkọ rẹ kí wọn sì bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì lè mọ̀ wí pé ilé yìí tí èmi ti kọ, orúkọ rẹ ni ó ń jẹ́. “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá lọ sójú ogun lórí àwọn ọ̀tá wọn, nígbàkígbà tí o bá rán wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ si ìhà ìlú yìí tí ìwọ ti yàn àti ilé OLúWA tí èmi ti kọ́ fún orúkọ rẹ. Nígbà náà gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró. “Nígbà tí wọ́n bá sì dẹ́ṣẹ̀ sí ọ—nítorí kò sí ènìyàn kan tí kì í dẹ́ṣẹ̀—bí o bá sì bínú sí wọn tí o bá sì fi wọ́n fún àwọn ọ̀tá, tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré tàbí nítòsí, Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n bá sì yí ọkàn wọn padà ní ilẹ̀ tí wọ́n ti mú wọn ní ìgbèkùn, tí wọ́n sì ronúpìwàdà tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọn ó sì wí pé, ‘Àwa ti dẹ́ṣẹ̀, àwa sì ti ṣe ohun tí kò dára, a sì ti ṣe búburú’. Tí wọn bá sì yípadà sí ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí ní ilẹ̀ ìgbèkùn wọn níbi tí wọ́n ti mú wọn, tí wọ́n sì gbàdúrà wọn, kojú si ìlú tí ìwọ ti yàn àti lórí ilé OLúWA tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ; Nígbà náà, láti ọ̀run, ibi ibùgbé rẹ, gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọn, tí wọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ. “Nísinsin yìí, Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ojú rẹ kí ó ṣí kí o sì tẹ́ etí rẹ sílẹ̀ fún àdúrà sí ibí yìí. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí dìde, OLúWA Ọlọ́run mi, sí ibi ìsinmi rẹ, ìwọ àti àpótí ẹ̀rí agbára rẹ. Jẹ́ kí àwọn àlùfáà, OLúWA Ọlọ́run mi, kí o wọ̀ wọ́n láṣọ pẹ̀lú ìgbàlà, jẹ́ kí àwọn àyànfẹ́ kí inú wọn kí ó dùn nínú ilé rẹ. OLúWA Ọlọ́run mi, má ṣe kọ̀ ẹni ààmì òróró rẹ. Rántí ìfẹ́ ńlá tí ó ṣe ìlérí fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ.”