II. Kro 5:11-14
II. Kro 5:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati awọn alufa ti ibi mimọ́ jade wá; (nitori gbogbo awọn alufa ti a ri li a yà si mimọ́, nwọn kò si kiyesi ipa wọn nigbana: Awon ọmọ Lefi pẹlu ti iṣe akọrin, gbogbo wọn ti Asafu, ti Hemani, ti Jedutuni, pẹlu awọn ọmọ wọn ati awọn arakunrin wọn, nwọn wọ ọ̀gbọ funfun, nwọn ni kimbali, ati ohun-elo orin, ati duru, nwọn si duro ni igun ila-õrun pẹpẹ na, ati pẹlu wọn, ìwọn ọgọfa alufa ti nwọn nfún ipè:) O si ṣe bi ẹnipe ẹnikan, nigbati a gbọ́ ohùn awọn afunpè ati awọn akọrin, bi ohùn kan lati ma yìn, ati lati ma dupẹ fun Oluwa; nigbati nwọn si gbé ohùn wọn soke pẹlu ipè ati kimbali, ati ohun-elo orin, lati ma yìn Oluwa pe, O ṣeun; ãnu rẹ̀ si duro lailai: nigbana ni ile na kún fun awọsanmọ, ani ile Oluwa; Tobẹ̃ ti awọn alufa kò le duro lati ṣiṣẹ ìsin nitori awọsanmọ na: nitori ogo Oluwa kún ile Ọlọrun.
II. Kro 5:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwọn alufaa jáde wá láti ibi mímọ́, (nítorí gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà níbẹ̀ ti ya ara wọn sí mímọ́ láìbèèrè ìpín tí olukuluku wà. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin, àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé: “OLUWA ṣeun, ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.” Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí ògo OLUWA tí ó kún ilé Ọlọrun.
II. Kro 5:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti ibi mímọ́. Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ Akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà-oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tuntun wọ́n ń lo kimbali, dùùrù àti ohun èlò orin olókùn. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfáà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn. Àwọn afùnpè àti àwọn akọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan ṣoṣo, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun OLúWA. Wọ́n fi ìpè, kimbali àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sókè láti fi yin OLúWA, wọ́n ń kọrin pé: “Ó dára; ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.” Nígbà náà ni ìkùùkuu ojú ọ̀run kún inú tẹmpili OLúWA, Tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò le è ṣiṣẹ́ ìsìn wọn nítorí ìkùùkuu náà, nítorí ògo OLúWA kún inú tẹmpili Ọlọ́run.