II. Kro 20:31-37
II. Kro 20:31-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jehoṣafati si jọba lori Juda: o si wà li ẹni ọdun marundilogoji, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹdọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Asuba, ọmọbinrin Ṣilhi. O si rìn li ọ̀na Asa, baba rẹ̀, kò si yà kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyi ti o tọ́ li oju Oluwa. Sibẹ kò mu ibi giga wọnni kuro: pẹlupẹlu awọn enia na kò si fi ọkàn wọn fun Ọlọrun awọn baba wọn rara. Ati iyokù iṣe Jehoṣafati, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyẹsi i, a kọ wọn sinu iwe Jehu, ọmọ Hanani, a si ti fi i sinu iwe awọn ọba Israeli. Ati lẹhin eyi ni Jehoṣafati, ọba Juda, dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, ọba Israeli, ẹniti o ṣe buburu gidigidi: O si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ ọ lati kan ọkọ̀ lati lọ si Tarṣiṣi: nwọn si kàn ọkọ̀ ni Esion-Geberi. Nigbana ni Elieseri ọmọ Dodafah ti Mareṣa sọtẹlẹ si Jehoṣafati wipe, Nitori ti iwọ ti dá ara rẹ pọ̀ mọ Ahasiah, Oluwa ti ba iṣẹ rẹ jẹ. Awọn ọkọ̀ na si fọ́, nwọn kò si le lọ si Tarṣiṣi.
II. Kro 20:31-37 Yoruba Bible (YCE)
Jehoṣafati jọba lórí Juda, ẹni ọdún marundinlogoji ni nígbà tí ó gorí oyè. Gbogbo ọdún tí ó lò lórí oyè jẹ́ ọdún mẹẹdọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba, ọmọ Ṣilihi. Ó ṣe dáradára gẹ́gẹ́ bí Asa, baba rẹ̀, ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run; àwọn eniyan kò tíì máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọrun àwọn baba ńlá wọn. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn Jehu ọmọ Hanani, tí ó jẹ́ apá kan ìtàn àwọn ọba Israẹli. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Jehoṣafati, ọba Juda lọ darapọ̀ mọ́ Ahasaya, ọba Israẹli, tí ó jẹ́ eniyan burúkú. Wọ́n jọ kan àwọn ọkọ̀ ojú omi tí yóo lọ sí ìlú Taṣiṣi. Wọ́n kan àwọn ọkọ̀ náà ní Esiongeberi. Elieseri ọmọ Dodafahu, ará Mareṣa fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Jehoṣafati wí. Ó ní, “Nítorí pé o darapọ̀ mọ́ Ahasaya, OLUWA yóo ba ohun tí o ti ṣe tẹ́lẹ̀ jẹ́.” Gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi náà rì, wọn kò sì lè lọ sí Taṣiṣi mọ́.
II. Kro 20:31-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni Jehoṣafati jẹ ọba lórí Juda. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùn-dínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Asuba ọmọbìnrin Silihi. Ó sì rin ọ̀nà baba rẹ̀ Asa kò sì yà kúrò nínú rẹ̀, ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú OLúWA. Ní ibi gíga, pẹ̀lúpẹ̀lú, kò mu wọn kúrò, gbogbo àwọn ènìyàn náà kò sì fi ọkàn wọn fún Ọlọ́run àwọn baba wọn. Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoṣafati, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ sí inú ìwé ìtàn ti Jehu ọmọ Hanani, tí a kọ sí inú ìwé àwọn ọba Israẹli. Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati ọba Juda da ara rẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú Ahasiah, ọba Israẹli, ẹni tí ó jẹ̀bi ìwà búburú. Ó sì gbà pẹ̀lú rẹ̀ láti kan ọkọ̀ láti lọ sí Tarṣiṣi, lẹ́yìn èyí wọ́n kan ọkọ̀ ní Esioni-Geberi. Elieseri ọmọ Dodafahu ti Meraṣa sọtẹ́lẹ̀ sí Jehoṣafati, wí pe, “Nítorí tí ìwọ ti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Ahasiah, OLúWA yóò pa ohun ti ìwọ ti ṣe run.” Àwọn ọkọ̀ náà sì fọ́, wọn kò sì le lọ sí ibi ìtajà.