II. Kro 20:21-22
II. Kro 20:21-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ba awọn enia na gbero, o yàn awọn akọrin si Oluwa, ti yio ma yìn ẹwa ìwa-mimọ́ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati ma wipe, Ẹ yìn Oluwa: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn.
II. Kro 20:21-22 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Jehoṣafati bá àwọn eniyan rẹ̀ jíròrò tán, ó yan àwọn tí wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA; tí wọn yóo wọ aṣọ mímọ́, tí wọn yóo sì máa yìn ín bí wọn yóo ti máa lọ níwájú ogun, wọn yóo máa kọrin pé, “Ẹ yin OLUWA! Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ dúró laelae.” Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn, OLUWA gbẹ̀yìn yọ sí àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu ati ti Òkè Seiri tí wọ́n wá bá àwọn eniyan Juda jà, ó sì tú wọn ká.
II. Kro 20:21-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jehoṣafati yàn wọ́n láti kọrin sí OLúWA àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí iwájú ogun ńlá náà, wí pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, nítorí àánú rẹ̀ dúró títí láéláé.” Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, OLúWA rán ogun ẹ̀yìn sí àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu àti òkè Seiri tí ó ń gbógun ti Juda, wọ́n sì kọlù wọ́n.