II. Kro 20:1-30

II. Kro 20:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

O SI ṣe, lẹhin eyi li awọn ọmọ Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni, ati ninu awọn ọmọ Edomu pẹlu wọn, gbé ogun tọ Jehoṣafati wá. Nigbana li awọn kan wá, nwọn si wi fun Jehoṣafati pe, Ọ̀pọlọpọ enia mbo wá ba ọ lati apakeji okun lati Siria, si kiyesi i, nwọn wà ni Hasason-Tamari ti iṣe Engedi. Jehoṣafati si bẹ̀ru, o si fi ara rẹ̀ si ati wá Oluwa, o si kede àwẹ ja gbogbo Juda. Juda si kó ara wọn jọ, lati wá iranlọwọ lọwọ Oluwa: pẹlupẹlu nwọn wá lati inu gbogbo ilu Juda lati wá Oluwa, Jehoṣafati si duro ninu apejọ enia Juda ati Jerusalemu, ni ile Oluwa, niwaju àgbala titun. O si wipe, Oluwa, Ọlọrun awọn baba wa, iwọ kọ́ ha ni Ọlọrun li ọrun? Iwọ kọ́ ha nṣakoso lori gbogbo ijọba awọn orilẹ-ède? lọwọ rẹ ki agbara ati ipá ha wà, ti ẹnikan kò si, ti o le kò ọ loju? Iwọ ha kọ́ Ọlọrun wa, ti o ti le awọn ara ilẹ yi jade niwaju Israeli enia rẹ, ti o si fi fun iru-ọmọ Abrahamu, ọrẹ rẹ lailai? Nwọn si ngbe inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ibi-mimọ́ fun ọ ninu rẹ̀ fun orukọ rẹ, pe, Bi ibi ba de si wa, bi idà, ijiya tabi àjakalẹ-àrun, tabi ìyan, bi awa ba duro niwaju ile yi, ati niwaju rẹ, (nitori orukọ rẹ wà ni ile yi): bi a ba ke pè ọ ninu wàhala wa, nigbana ni iwọ o gbọ́, iwọ o si ṣe iranlọwọ. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, ati awọn ara òke Seiri, ti iwọ kò jẹ ki Israeli gbogun si nigbati nwọn jade ti ilẹ Egipti wá, ṣugbọn nwọn yipada kuro lọdọ wọn, nwọn kò si run wọn; Si kiyesi i, bi nwọn ti san a pada fun wa; lati wá le wa jade kuro ninu ini rẹ, ti iwọ ti fi fun wa lati ni. Ọlọrun wa! Iwọ kì o ha da wọn lẹjọ? nitori awa kò li agbara niwaju ọ̀pọlọpọ nla yi, ti mbọ̀ wá ba wa; awa kò si mọ̀ eyi ti awa o ṣe: ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ. Gbogbo Juda si duro niwaju Oluwa, pẹlu awọn ọmọ wẹrẹ wọn, obinrin wọn, ati ọmọ wọn. Ṣugbọn lori Jahasieli, ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah, ọmọ Lefi kan ninu awọn ọmọ Asafu, ni ẹmi Oluwa wá li ãrin apejọ enia na. O si wipe, Ẹ tẹti silẹ, gbogbo Judah, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu, ati iwọ Jehoṣafati ọba; Bayi li Oluwa wi fun nyin, Ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya nitori ọ̀pọlọpọ enia yi; nitori ogun na kì iṣe ti nyin bikòṣe ti Ọlọrun. Lọla sọ̀kalẹ tọ̀ wọn: kiyesi i, nwọn o gbà ibi igòke Sisi wá; ẹnyin o si ri wọn ni ipẹkun odò na, niwaju aginju Jerueli. Ẹnyin kò ni ijà li ọ̀ran yi; ẹ tẹgun, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala Oluwa lọdọ nyin, iwọ Juda ati Jerusalemu: ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya: lọla, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa yio si pẹlu nyin. Jehoṣafati tẹ ori rẹ̀ ba silẹ: ati gbogbo Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu wolẹ niwaju Oluwa lati sìn Oluwa. Awọn ọmọ Lefi, ninu awọn ọmọ Kohati ati ninu awọn ọmọ Kori si dide duro, lati fi ohùn rara kọrin iyìn soke si Oluwa Ọlọrun Israeli. Nwọn si dide ni kutukutu owurọ, nwọn si jade lọ si aginju Tekoa: bi nwọn si ti jade lọ, Jehoṣafati duro, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ará Juda, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu. Ẹ gbà Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́, bẹ̃li a o fi ẹsẹ nyin mulẹ; ẹ gbà awọn woli rẹ̀ gbọ́, bẹ̃li ẹnyin o ṣe rere. O si ba awọn enia na gbero, o yàn awọn akọrin si Oluwa, ti yio ma yìn ẹwa ìwa-mimọ́ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati ma wipe, Ẹ yìn Oluwa: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn. Awọn ọmọ Ammoni ati Moabu si dide si awọn ti ngbe òke Seiri, lati pa, ati lati run wọn tũtu: nigbati nwọn si pa awọn ti ngbe òke Seiri run tan, ẹnikini nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji. Nigbati Juda si de iha ile-iṣọ li aginju, nwọn wò awọn ọ̀pọlọpọ enia, si kiyesi i, okú ti o ṣubu lulẹ ni nwọn, ẹnikan kò sá asalà. Nigbati Jehoṣafati ati awọn enia rẹ̀ de lati kó ikogun wọn, nwọn ri lara wọn ọ̀pọlọpọ ọrọ̀, ati okú, ati ohun-elo iyebiye, nwọn si kójọ fun ara wọn, jù eyiti nwọn le kó lọ: nwọn si kó ikogun wọn jọ ni ijọ mẹta, nitoriti o sa papọ̀ju. Ati li ọjọ kẹrin nwọn kó ara wọn jọ li afonifoji Ibukún, nitori nibẹ ni nwọn fi ibukún fun Oluwa, nitorina ni a ṣe npe orukọ ibẹ na ni, Afonifoji Ibukún, titi di oni. Nigbana ni nwọn yipada, gbogbo awọn ọkunrin Juda ati Jerusalemu, ati Jehoṣafati niwaju wọn lati pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀; nitori ti Oluwa ti mu wọn yọ̀ lori awọn ọta wọn. Nwọn si wá si Jerusalemu pẹlu ohun-elo orin, ati duru ati ipè si ile Oluwa. Ibẹ̀ru Ọlọrun si wà lara gbogbo ijọba ilẹ wọnni, nigbati nwọn gbọ́ pe Oluwa ti ba awọn ọta Israeli jà. Bẹ̃ni ijọba Jehoṣafati wà li alafia: nitoriti Ọlọrun rẹ̀ fun u ni isimi yikakiri.

II. Kro 20:1-30 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Moabu, ati àwọn ará Amoni, ati díẹ̀ ninu àwọn ará Meuni kó ara wọn jọ láti bá Jehoṣafati jagun. Àwọn kan wá sọ fún Jehoṣafati pé ogun ńlá kan ń bọ̀ wá jà á láti Edomu ní òdìkejì òkun. Wọ́n sọ pé àwọn ọ̀tá náà ti dé Hasasoni Tamari, (tí a tún ń pè ní Engedi). Ẹ̀rù ba Jehoṣafati gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ojú OLUWA, ó kéde jákèjádò ilẹ̀ Juda pé kí wọ́n gbààwẹ̀. Àwọn eniyan péjọ láti gbogbo ìlú Juda, wọ́n wá bèèrè ìrànlọ́wọ́ OLUWA. Jehoṣafati bá dìde dúró láàrin àwọn tí wọ́n ti Juda ati Jerusalẹmu wá sinu tẹmpili, níbi tí wọ́n péjọ sí níwájú gbọ̀ngàn tuntun, ó ní, “OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọrun ọ̀run. Ìwọ ni o ni àkóso ìjọba gbogbo orílẹ̀-èdè. Agbára ati ipá wà ní ìkáwọ́ rẹ, kò sì sí ẹni tí ó tó dojú kọ ọ́. Ṣebí ìwọ, Ọlọrun wa, ni o lé gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀ kúrò fún àwa ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, tí o sì fi ilẹ̀ náà fún arọmọdọmọ Abrahamu, ọ̀rẹ́ rẹ, títí lae? Wọ́n ti ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì ti kọ́ ibi mímọ́ sibẹ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, nítorí pé tí ibi bá dé bá wa, tabi ìdájọ́, tabi àjàkálẹ̀ àrùn, tabi ìyàn, a óo dúró níwájú ilé yìí ati níwájú rẹ, nítorí orúkọ rẹ wà ninu ilé yìí. A óo ké pè ọ́ ninu ìyọnu wa, o óo gbọ́ tiwa, o óo sì gbà wá. “Nisinsinyii, wo àwọn ọmọ ogun Amoni, ati ti Moabu ati ti Òkè Seiri, àwọn tí o kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli bá jà nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti, o kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n run. Wò ó! Wọ́n ń fi burúkú san ire fún wa, wọ́n ń bọ̀ wá lé wa kúrò lórí ilẹ̀ rẹ, tí o fún wa bí ìní. Ọlọrun wa, dá wọn lẹ́jọ́. Nítorí pé agbára wa kò tó láti dojú kọ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun wọn tí wọn ń kó bọ̀ wá bá wa jà. A kò mọ ohun tí a lè ṣe, ìwọ ni a gbójú sókè tí à ń wò.” Gbogbo àwọn ọkunrin Juda dúró níwájú OLUWA pẹlu àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Jahasieli, ọmọ Sakaraya, ọmọ Bẹnaya, ọmọ Jeieli, ọmọ Matanaya; ọmọ Lefi ni, láti inú ìran Asafu. Ó bá dìde dúró láàrin àwùjọ àwọn eniyan. Ó ní, “Ẹ fetí sí mi, gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati ti Jerusalẹmu ati ọba Jehoṣafati, OLUWA ní kí ẹ má fòyà, kí ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì nítorí ogun ńlá yìí; nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ó ja ogun ńlá yìí, Ọlọrun ni. Ní ọ̀la, ẹ kógun lọ bá wọn; wọn yóo gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Sisi wá, ẹ óo rí wọn ní òpin àfonífojì ní apá ìlà oòrùn aṣálẹ̀ Jerueli. Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.” Jehoṣafati dojúbolẹ̀, gbogbo àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu náà bá dojúbolẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Ni àwọn ọmọ Lefi láti inú ìdílé Kohati ati ti Kora bá dìde, wọ́n gbóhùn sókè, wọ́n sì yin OLUWA Ọlọrun Israẹli. Ní kutukutu òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn eniyan náà lọ sí aṣálẹ̀ Tekoa. Bí wọ́n ti ń lọ, Jehoṣafati dúró, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, ẹ gba ohun tí àwọn wolii rẹ̀ wí gbọ́ pẹlu, ẹ óo sì ní ìṣẹ́gun.” Nígbà tí Jehoṣafati bá àwọn eniyan rẹ̀ jíròrò tán, ó yan àwọn tí wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA; tí wọn yóo wọ aṣọ mímọ́, tí wọn yóo sì máa yìn ín bí wọn yóo ti máa lọ níwájú ogun, wọn yóo máa kọrin pé, “Ẹ yin OLUWA! Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ dúró laelae.” Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọrin ìyìn, OLUWA gbẹ̀yìn yọ sí àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu ati ti Òkè Seiri tí wọ́n wá bá àwọn eniyan Juda jà, ó sì tú wọn ká. Àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu gbógun ti àwọn ará Òkè Seiri wọ́n sì pa wọ́n run patapata. Lẹ́yìn náà, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn run. Nígbà tí ogun Juda dé ilé ìṣọ́ tí ó wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n wo àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n sì rí i pé wọ́n ti kú sílẹ̀ lọ bẹẹrẹ; kò sí ẹni tí ó sá àsálà ninu wọn. Nígbà tí Jehoṣafati ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti kó ìkógun, wọ́n rí ọpọlọpọ mààlúù, ati ẹrù aṣọ ati nǹkan ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye. Wọ́n kó wọn títí ó fi sú wọn. Odidi ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi kó ìkógun nítorí pé ó ti pọ̀ jù. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ ní àfonífojì Beraka. Ibẹ̀ ni wọ́n ti yin OLUWA. Nítorí náà ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pe ibẹ̀ ní Beraka títí di òní olónìí. Jehoṣafati kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun, nítorí pé OLUWA ti fún un ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, wọ́n wọ inú tẹmpili lọ, pẹlu ìró hapu, ati ti dùùrù ati ti fèrè. Ẹ̀rù OLUWA ba ìjọba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLUWA bá àwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Israẹli jagun. Nítorí náà Jehoṣafati jọba ní alaafia, nítorí pé Ọlọrun fún un ní ìsinmi ní gbogbo àyíká rẹ̀.

II. Kro 20:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Mehuni wá láti gbé ogun ti Jehoṣafati. Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jehoṣafati, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá bá ọ láti apá kejì Òkun láti Siria. Ó ti wà ní Hasason Tamari náà” (èyí tí í ṣe, En-Gedi). Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ OLúWA, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda. Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ OLúWA; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a. Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé OLúWA níwájú àgbàlá tuntun. O sì wí pé: “OLúWA, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú. Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé? Wọ́n ti ń gbé nínú rẹ̀ wọ́n sì ti kọ́ sínú rẹ ibi mímọ́ fún orúkọ rẹ wí pé, ‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sọkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’ “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọkùnrin nìyí láti Ammoni, Moabu àti òkè Seiri, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Israẹli láyè láti gbóguntì nígbà tí wọn wá láti Ejibiti; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run. Sì kíyèsi i, bí wọ́n ti san án padà fún wa; láti wá lé wa jáde kúrò nínú ìní rẹ, tí ìwọ ti fi fún wa láti ní. Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.” Gbogbo àwọn ọkùnrin Juda, pẹ̀lú àwọn aya wọn àti ọmọ wọn àti àwọn kéékèèkéé, dúró níbẹ̀ níwájú OLúWA. Nígbà náà, ẹ̀mí OLúWA sì bà lé Jahasieli ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah ọmọ Lefi àti ọmọ Asafu, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe dìde dúró láàrín àpéjọ ènìyàn. Ó sì wí pé, “Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ọba Jehoṣafati àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní Juda àti Jerusalẹmu! Èyí ní ohun tí OLúWA sọ wí pé kí a ṣe: ‘Ẹ má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà nítorí ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí. Nítorí ogun náà kì í ṣe tiyín, ṣùgbọ́n ti Ọlọ́run ni. Ní ọ̀la, ẹ sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ, wọn yóò gòkè pẹ̀lú, ẹ̀yin yóò sì rí wọn ní ìpẹ̀kun odò náà, níwájú aginjù Jerueli. Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní ààyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà OLúWA tí yóò fi fún yín, ìwọ Juda àti Jerusalẹmu. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojúkọ wọ́n ní ọ̀la, OLúWA yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ” Jehoṣafati tẹ orí rẹ̀ ba sílẹ̀ pẹ̀lú ojú rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu wólẹ̀ níwájú láti sin OLúWA. Nígbà náà díẹ̀ lára àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ọmọ Kohati àti àwọn ọmọ Kora sì dìde dúró wọ́n sì sin OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, pẹ̀lú ohùn ariwo ńlá. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù wọ́n jáde lọ sí aginjù Tekoa. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń jáde lọ, Jehoṣafati dìde dúró ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ mi, Juda àti ènìyàn Jerusalẹmu! Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú OLúWA Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì borí, ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn wòlíì rẹ̀ ẹ̀yìn yóò sì ṣe rere.” Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jehoṣafati yàn wọ́n láti kọrin sí OLúWA àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí iwájú ogun ńlá náà, wí pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, nítorí àánú rẹ̀ dúró títí láéláé.” Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, OLúWA rán ogun ẹ̀yìn sí àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu àti òkè Seiri tí ó ń gbógun ti Juda, wọ́n sì kọlù wọ́n. Àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Seiri láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin láti òkè Seiri, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run. Nígbà tí àwọn ènìyàn Juda jáde sí ìhà ilé ìṣọ́ ní aginjù, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí ààyè sá. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀. Ní ọjọ́ kẹrin, wọn kó ara jọ pọ̀ ní Àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún OLúWA. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì ìbùkún títí di òní. Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jehoṣafati, gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jerusalẹmu, nítorí OLúWA ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sì wọ Jerusalẹmu, wọ́n sì lọ sí ilé OLúWA pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn àti dùùrù àti ìpè. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá si orí gbogbo ìjọba ilẹ̀ náà nígbà tí wọ́n gbọ́ bí OLúWA ti bá àwọn ọ̀tá Israẹli jà. Bẹ́ẹ̀ ni ìjọba Jehoṣafati sì wà ní àlàáfíà, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ ti fún un ni ìsinmi ní gbogbo àyíká.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa