II. Kro 20:1-3
II. Kro 20:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
O SI ṣe, lẹhin eyi li awọn ọmọ Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni, ati ninu awọn ọmọ Edomu pẹlu wọn, gbé ogun tọ Jehoṣafati wá. Nigbana li awọn kan wá, nwọn si wi fun Jehoṣafati pe, Ọ̀pọlọpọ enia mbo wá ba ọ lati apakeji okun lati Siria, si kiyesi i, nwọn wà ni Hasason-Tamari ti iṣe Engedi. Jehoṣafati si bẹ̀ru, o si fi ara rẹ̀ si ati wá Oluwa, o si kede àwẹ ja gbogbo Juda.
II. Kro 20:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí, àwọn ará Moabu, ati àwọn ará Amoni, ati díẹ̀ ninu àwọn ará Meuni kó ara wọn jọ láti bá Jehoṣafati jagun. Àwọn kan wá sọ fún Jehoṣafati pé ogun ńlá kan ń bọ̀ wá jà á láti Edomu ní òdìkejì òkun. Wọ́n sọ pé àwọn ọ̀tá náà ti dé Hasasoni Tamari, (tí a tún ń pè ní Engedi). Ẹ̀rù ba Jehoṣafati gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ojú OLUWA, ó kéde jákèjádò ilẹ̀ Juda pé kí wọ́n gbààwẹ̀.
II. Kro 20:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Mehuni wá láti gbé ogun ti Jehoṣafati. Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jehoṣafati, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá bá ọ láti apá kejì Òkun láti Siria. Ó ti wà ní Hasason Tamari náà” (èyí tí í ṣe, En-Gedi). Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ OLúWA, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda.