II. Kro 2:1-6
II. Kro 2:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
SOLOMONI si pinnu rẹ̀ lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, ati ile kan fun ijọba rẹ̀. Solomoni si yàn ẹgbã marundilogoji ọkunrin lati ru ẹrù, ati ọkẹ mẹrin lati ké igi li ori òke, ati egbejidilogun lati bojuto wọn. Solomoni si ranṣẹ si Huramu, ọba Tire, wipe, Gẹgẹ bi iwọ ti ba Dafidi, baba mi lò, ti iwọ fi igi kedari ṣọwọ si i lati kọ́ ile kan fun u lati ma gbe inu rẹ̀, bẹni ki o ba mi lò. Kiyesi i, emi nkọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun mi, lati yà a si mimọ́ fun u, ati lati sun turari niwaju rẹ̀, ati fun àkara-ifihan igbakugba, ati fun ẹbọsisun li ọwurọ ati li alẹ, li ọjọjọ isimi ati li oṣoṣù titun, ati li apejọ Oluwa Ọlọrun wa; eyi ni aṣẹ fun Israeli titi lai. Ile ti emi nkọ́ yio si tobi; nitori titobi ni Ọlọrun wa jù gbogbo awọn ọlọrun lọ. Ṣugbọn tani to lati kọ́ ile fun u, nitori ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà a? tali emi ti emi iba kọ́le fun u, bikòṣe kiki ati sun ẹbọ niwaju rẹ̀?
II. Kro 2:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Solomoni ọba pinnu láti kọ́ tẹmpili níbi tí àwọn eniyan yóo ti máa sin OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀. Ó kó ọ̀kẹ́ mẹta ati ẹgbaarun (70,000) àwọn òṣìṣẹ́ jọ láti máa ru àwọn nǹkan tí yóo fi kọ́lé, ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) àwọn òṣìṣẹ́ tí yóo máa fọ́ òkúta, ati ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) eniyan láti máa bojútó àwọn òṣìṣẹ́. Solomoni ranṣẹ sí Huramu, ọba Tire pé, “Máa ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Dafidi, baba mi, tí o kó igi kedari ranṣẹ sí i láti kọ́ ààfin rẹ̀. Mo fẹ́ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun mi. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ tí a ó ti máa sun turari olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀. A ó máa mú ẹbọ àkàrà ojoojumọ lọ sibẹ, a ó sì máa rú ẹbọ sísun níbẹ̀ láàárọ̀ ati lálẹ́; ati ní ọjọọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣooṣù, ati ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli títí lae. Ilé tí mo fẹ́ kọ́ yóo tóbi pupọ, nítorí pé Ọlọrun wa tóbi ju gbogbo oriṣa lọ. Kò sí ẹni tí ó lè kọ́ ilé fún un, nítorí pé ọ̀run, àní ọ̀run tí ó ga jùlọ, kò le è gbà á. Kí ni mo jẹ́ tí n óo fi kọ́ ilé fún un, bíkòṣe pé kí n kọ́ ibi tí a óo ti máa sun turari níwájú rẹ̀?
II. Kro 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Solomoni pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ OLúWA àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀ Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin àwọn (70,000) ọkùnrin láti ru ẹrù àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rin àwọn (80,000) ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìn-dínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn. Solomoni rán iṣẹ́ yìí sí Hiramu ọba Tire: “Rán àwọn igi kedari sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dafidi. Nígbà tí ó fi igi kedari ránṣẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé. Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ OLúWA Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún ṣíṣe ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn ti OLúWA Ọlọ́run wa. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli láéláé. “Ilé OLúWA tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run mìíràn lọ. Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún OLúWA, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run tó ga jùlọ, kò le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún OLúWA, bí kò ṣe kìkì àti sun ẹbọ sun ẹbọ níwájú rẹ̀?