II. Kro 15:9-18

II. Kro 15:9-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si kó gbogbo Juda ati Benjamini jọ, ati awọn alejo ti o pẹlu wọn lati inu Efraimu ati Manasse, ati lati inu Simeoni wá: nitori ti nwọn ya li ọ̀pọlọpọ sọdọ rẹ̀ lati inu Israeli wá, nigbati nwọn ri pe, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn kó ara wọn jọ si Jerusalemu, li oṣù kẹta, li ọdun kẹdogun ijọba Asa. Nwọn si fi ninu ikógun ti nwọn kó wá, rubọ si Oluwa li ọjọ na, ẹ̃dẹgbãrin akọ-malu ati ẹ̃dẹgbãrin agutan. Nwọn si tun dá majẹmu lati wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, tinutinu wọn ati tọkàntọkàn wọn. Pe, ẹnikẹni ti kò ba wá Oluwa Ọlọrun Israeli, pipa li a o pa a, lati ẹni-kekere de ẹni-nla, ati ọkunrin ati obinrin. Nwọn si fi ohùn rara bura fun Oluwa, ati pẹlu ariwo, ati pẹlu ipè ati pẹlu fère. Gbogbo Juda si yọ̀ si ibura na: nitoriti nwọn fi tinu-tinu wọn bura, nwọn si fi gbogbo ifẹ inu wọn wá a; nwọn si ri i: Oluwa si fun wọn ni isimi yikakiri. Pẹlupẹlu Maaka, iya Asa, li ọba mu u kuro lati má ṣe ayaba, nitoriti o yá ere fun oriṣa rẹ̀: Asa si ké ere rẹ̀ lulẹ, o si tẹ̀ ẹ mọlẹ, o si sun u nibi odò Kidroni. Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro ni Israeli: kiki ọkàn Asa wà ni pipé li ọjọ rẹ̀ gbogbo. O si mu ohun mimọ́ wọnni ti baba rẹ̀, ati ohun mimọ́ wọnni ti on tikararẹ̀ wá sinu ile Ọlọrun, fadakà, wura, ati ohun-elo wọnni.

II. Kro 15:9-18 Yoruba Bible (YCE)

Ó kó gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Bẹnjamini jọ, ati àwọn tí wọ́n wá láti Efuraimu, Manase ati Simeoni, tí wọ́n jẹ́ àlejò láàrin wọn. Nítorí pé ọpọlọpọ eniyan láti ilẹ̀ Israẹli ni wọ́n ti sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọ́n rí i pé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀. Wọ́n péjọ ní Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹẹdogun ìjọba Asa. Wọ́n mú ẹẹdẹgbẹrin (700) mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan ninu ìkógun tí wọ́n kó, wọ́n fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun baba wọn. Wọ́n dá majẹmu pé àwọn yóo máa sin OLUWA Ọlọrun baba àwọn tọkàntọkàn àwọn; ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, ìbáà ṣe àgbà tabi ọmọde, ọkunrin tabi obinrin, pípa ni àwọn yóo pa á. Wọ́n fi igbe búra ní orúkọ OLUWA pẹlu ariwo ati fèrè. Inú gbogbo Juda sì dùn sí ẹ̀jẹ́ náà, nítorí pé tọkàntọkàn ni wọ́n fi jẹ́ ẹ. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń sin Ọlọrun. Ọlọrun gba ìsìn wọn, ó sì fún wọn ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà. Asa ọba, yọ Maaka ìyá rẹ̀ àgbà pàápàá kúrò ní ipò ìyá ọba, nítorí pé ó gbẹ́ ère ìríra kan fún oriṣa Aṣera. Asa wó ère náà lulẹ̀, ó gé e wẹ́lẹwẹ̀lẹ, ó sì dáná sun ún ní odò Kidironi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Asa kò wó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ palẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, sibẹsibẹ kò ní ẹ̀bi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó kó àwọn nǹkan tí Abija, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ fún Ọlọrun lọ sinu tẹmpili pẹlu gbogbo nǹkan tí òun pàápàá ti yà sí mímọ́: fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò.

II. Kro 15:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà naà, ó pe gbogbo Juda àti Benjamini jọ àti àwọn ènìyàn láti Efraimu, Manase àti Simeoni tí ó ti ṣe àtìpó ní àárín wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Israẹli nígbà tí wọ́n rí i wí pé OLúWA Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n péjọ sí Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹ́ẹ̀dógún ti ìjọba Asa. Ní àkókò yìí, wọ́n rú ẹbọ sí OLúWA ọgọ́rùn-ún méje akọ màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkógun tí wọ́n ti kó padà. Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá OLúWA Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn. Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá OLúWA Ọlọ́run Israẹli, pípa ni á ó pa á láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin. Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún OLúWA àti pẹ̀lú ìhó ńlá àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè. Gbogbo Juda yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, OLúWA sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri. Ọba Asa sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní Àfonífojì Kidironi. Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Israẹli; síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Asa wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo. Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà.