II. Kro 15:3-6
II. Kro 15:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ ọjọ pupọ ni Israeli ti wà laisìn Ọlọrun otitọ, ati laini alufa ti nkọni, ati laini ofin. Ṣugbọn nwọn yipada si Oluwa. Ọlọrun Israeli, ninu wahala wọn, nwọn si ṣe awari rẹ̀, nwọn si ri i. Ati li ọjọ wọnni alafia kò si fun ẹniti o njade, tabi fun ẹniti nwọle, ṣugbọn ibanujẹ pupọ li o wà lori gbogbo awọn olugbe ilẹ wọnni. Orilẹ-ède si kọlù orilẹ-ède, ati ilu si ilu: nitori ti Ọlọrun fi oniruru ipọnju bà wọn ninu jẹ.
II. Kro 15:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Ọjọ́ pẹ́, tí Israẹli ti wà láìní Ọlọrun òtítọ́, wọn kò ní alufaa tí ń kọ́ ni, wọn kò sì ní òfin. Ṣugbọn nígbà tí ìyọnu dé, wọ́n yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Wọ́n wá OLUWA, wọ́n sì rí i. Ní àkókò náà, kò sí ìbàlẹ̀ ọkàn fún àwọn tí wọn ń jáde ati àwọn tí wọ́n ń wọlé, nítorí ìdààmú ńlá dé bá àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. Orílẹ̀-èdè kan ń pa ekeji run, ìlú kan sì ń pa ekeji rẹ́, nítorí Ọlọrun mú oniruuru ìpọ́njú bá wọn.
II. Kro 15:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Israẹli ti wà láì sin Ọlọ́run òtítọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láìní òfin. Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si OLúWA Ọlọ́run Israẹli, wọ́n sì wa kiri. Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlú kan sí òmíràn nítorí Ọlọ́run ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú.