II. Kro 15:1-2
II. Kro 15:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Asaraya ọmọ Odedi. Ó lọ pàdé Asa, ó wí fún un pé, “Gbọ́ mi, ìwọ Asa, ati gbogbo ẹ̀yin ọmọ Juda ati ti Bẹnjamini, OLUWA wà pẹlu yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin náà bá wà pẹlu rẹ̀. Bí ẹ bá wá a, ẹ óo rí i. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun náà yóo kọ̀ yín sílẹ̀.
II. Kro 15:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Asariah ọmọ Odedi. Ó jáde lọ bá Asa, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Asa, àti gbogbo Juda àti Benjamini. OLúWA wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
II. Kro 15:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
ẸMI Ọlọrun si wá si ara Asariah, ọmọ Odedi: O si jade lọ ipade Asa, o si wi fun u pe, Ẹ gbọ́ temi, Asa, ati gbogbo Juda ati Benjamini! Oluwa pẹlu nyin, nitori ti ẹnyin ti wà pẹlu rẹ̀; bi ẹnyin ba si ṣafẹri rẹ̀, ẹnyin o ri i; ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀ ọ, on o si kọ̀ nyin.