I. Tim 6:6-10
I. Tim 6:6-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni. Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ. Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ ìwọnyi yio tẹ́ wa lọrùn. Ṣugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ́ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã rì enia sinu iparun ati ègbé. Nitori ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ́, nwọn si fi ibinujẹ pupọ̀ gún ara wọn li ọ̀kọ̀.
I. Tim 6:6-10 Yoruba Bible (YCE)
Òtítọ́ ni pé èrè ńlá wà ninu jíjẹ́ olùfọkànsìn, tí eniyan bá ní ìtẹ́lọ́rùn. Nítorí a kò mú ohunkohun wá sinu ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè mú ohunkohun kúrò ninu rẹ̀. Bí a bá ti ní oúnjẹ ati aṣọ, kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu wọn. Àwọn tí wọn ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa ṣubú sinu ìdánwò, tàkúté a sì mú wọn. Wọn a máa lépa ọpọlọpọ nǹkan tí kò mú ọgbọ́n wá ati àwọn nǹkan tí ó lè pa eniyan lára, irú nǹkan tí ó ti mú kí àwọn mìíràn jìn sinu ọ̀fìn ikú ati ìparun. Ìfẹ́ owó ni ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan burúkú. Èyí ni àwọn mìíràn ń lépa tí wọ́n fi ṣìnà kúrò ninu igbagbọ, tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn fa ọpọlọpọ ìbànújẹ́ fún ara wọn.
I. Tim 6:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.