I. Tim 6:1-10

I. Tim 6:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)

KI gbogbo awọn ti iṣe ẹrú labẹ ìrú mã ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọla gbogbo, ki a má bã sọrọ-odi si orukọ Ọlọrun ati ẹkọ́ rẹ̀. Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ́, ki nwọn máṣe gàn wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mã sìn wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ́ ati olufẹ. Nkan wọnyi ni ki o mã kọ́ni ki o si mã fi gba-ni-niyanju. Bi ẹnikẹni ba nkọ́ni li ẹkọ miran, ti kò si gba ọ̀rọ ti o ye kõro, ani ọ̀rọ Jesu Kristi Oluwa wa, ati ẹkọ́ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun. O gberaga, kò mọ nkan kan, bikoṣe ifẹ iyan-jija ati ìja-ọ̀rọ ninu eyiti ilara, ìya, ọrọ buburu ati iro buburu ti iwá, Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni. Ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun pẹlu itẹlọrùn ère nla ni. Nitori a kò mu ohun kan wá si aiye, bẹni a kò si le mu ohunkohun jade lọ. Bi a ba si li onjẹ ati aṣọ ìwọnyi yio tẹ́ wa lọrùn. Ṣugbọn awọn ti nfẹ di ọlọrọ̀ a mã bọ́ sinu idanwò ati idẹkun, ati sinu wère ifẹkufẹ pipọ ti ipa-ni-lara, iru eyiti imã rì enia sinu iparun ati ègbé. Nitori ifẹ owo ni gbòngbo ohun buburu gbogbo: eyiti awọn miran nlepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ́, nwọn si fi ibinujẹ pupọ̀ gún ara wọn li ọ̀kọ̀.

I. Tim 6:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àjàgà ẹrú níláti rí i pé wọ́n ń bu ọlá fún àwọn ọ̀gá wọn ní ọ̀nà gbogbo, kí àwọn eniyan má baà sọ̀rọ̀ ìṣáátá sí orúkọ Ọlọrun ati ẹ̀kọ́ onigbagbọ. Àwọn ẹrú tí wọ́n ní ọ̀gá onigbagbọ kò gbọdọ̀ sọ ara wọn di ẹgbẹ́ ọ̀gá wọn, wọn ìbáà jẹ́ ará ninu Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti sìn wọ́n tara-tara, nítorí àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ fún jẹ́ arakunrin ninu igbagbọ ati ìfẹ́. Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa fi kọ́ àwọn eniyan, kí o sì máa fi gbà wọ́n níyànjú. Bí ẹnìkan bá ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ mìíràn, tí kò mọ ẹ̀kọ́ tí ó yè, ẹ̀kọ́ ti Oluwa wa Jesu Kristi, ati ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí ó pé, ìgbéraga ti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di aṣiwèrè, kò sì mọ nǹkankan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ óo fẹ́ràn láti máa ṣe òfintótó ọ̀ràn, ati iyàn jíjà, àwọn ohun tí ó ń mú owú-jíjẹ, ìjà, ìsọkúsọ, ìfura burúkú, ati àríyànjiyàn wá. Nǹkan wọnyi wọ́pọ̀ láàrin àwọn tí orí wọn ti kú, tí wọ́n ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n rò pé nítorí èrè ni eniyan fi ń ṣe ẹ̀sìn. Òtítọ́ ni pé èrè ńlá wà ninu jíjẹ́ olùfọkànsìn, tí eniyan bá ní ìtẹ́lọ́rùn. Nítorí a kò mú ohunkohun wá sinu ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè mú ohunkohun kúrò ninu rẹ̀. Bí a bá ti ní oúnjẹ ati aṣọ, kí á ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu wọn. Àwọn tí wọn ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa ṣubú sinu ìdánwò, tàkúté a sì mú wọn. Wọn a máa lépa ọpọlọpọ nǹkan tí kò mú ọgbọ́n wá ati àwọn nǹkan tí ó lè pa eniyan lára, irú nǹkan tí ó ti mú kí àwọn mìíràn jìn sinu ọ̀fìn ikú ati ìparun. Ìfẹ́ owó ni ìpìlẹ̀ gbogbo nǹkan burúkú. Èyí ni àwọn mìíràn ń lépa tí wọ́n fi ṣìnà kúrò ninu igbagbọ, tí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn fa ọpọlọpọ ìbànújẹ́ fún ara wọn.

I. Tim 6:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú. Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jesu Kristi Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu, Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkan kan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀ búburú wá, àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.