I. Tim 5:1-25

I. Tim 5:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

MÁṢE ba alàgba wi, ṣugbọn ki o mã gba a niyanju bi baba; awọn ọdọmọkunrin bi arakunrin; Awọn àgba obinrin bi iya; awọn ọdọmọbirin bi arabinrin ninu ìwa mimọ́. Bọ̀wọ fun awọn opó ti iṣe opó nitõtọ. Ṣugbọn bi opó kan ba li ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, jẹ ki nwọn tète kọ́ ati ṣe itọju ile awọn tikarawọn, ki nwọn ki o si san õre awọn obi wọn pada: nitoripe eyi li o ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun. Njẹ ẹniti iṣe opó nitõtọ, ti o ṣe on nikan, a mã gbẹkẹle Ọlọrun, a si mã duro ninu ẹ̀bẹ ati ninu adura lọsán ati loru. Ṣugbọn ẹniti o ba fi ara rẹ̀ fun aiye jijẹ, o kú nigbati o wà lãye. Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o si mã palaṣẹ, ki nwọn ki o le wà lailẹgan. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò bá pèse fun awọn tirẹ, papa fun awọn ará ile rẹ̀, o ti sẹ́ igbagbọ́, o buru ju alaigbagbọ́ lọ. Máṣe kọ orukọ ẹniti o ba din ni ọgọta ọdún silẹ bi opó, ti o ti jẹ obinrin ọkọ kan, Ẹniti a jẹri rẹ̀ fun iṣẹ rere; bi o ba ti ntọ́ ọmọ ri, bi o ba ti ngba alejò, bi o bá ti nwẹ ẹsẹ awọn enia mimọ́, bi o ba ti nràn awọn olupọnju lọwọ, bi o ba ti nlepa iṣẹ rere gbogbo. Ṣugbọn kọ̀ awọn opo ti kò dagba: nitoripe nigbati nwọn ba ti ṣe ifẹkufẹ lodi si Kristi, nwọn a fẹ gbeyawo; Nwọn a di ẹlẹbi, nitoriti nwọn ti kọ̀ igbagbọ́ wọn iṣaju silẹ. Ati pẹlu nwọn nkọ́ lati ṣe ọlẹ, lati mã kiri lati ile de ile; ki iṣe ọlẹ nikan, ṣugbọn onisọkusọ ati olofòfo pẹlu, nwọn a ma sọ ohun ti kò yẹ. Nitorina mo fẹ ki awọn opo ti kò dagba mã gbeyawo, ki nwọn mã bímọ, ki nwọn ki o mã ṣe alabojuto ile, ki nwọn ki o máṣe fi àye silẹ rara fun ọtá na lati sọ̀rọ ẹ̀gan. Nitori awọn miran ti yipada kuro si ẹhin Satani. Bi obinrin kan ti o gbagbọ́ ba ni awọn opó, ki o mã ràn wọn lọwọ, ki a má si di ẹrù le ijọ, ki nwọn ki o le mã ràn awọn ti iṣe opó nitõtọ lọwọ. Awọn alàgba ti o ṣe akoso daradara ni ki a kà yẹ si ọlá ilọpo meji, pẹlupẹlu awọn ti o ṣe lãlã ni ọ̀rọ ati ni kikọni. Nitoriti iwe-mimọ́ wipe, Iwọ kò gbọdọ dì malu ti ntẹ̀ ọkà li ẹnu. Ati pe, ọ̀ya alagbaṣe tọ si i. Máṣe gbà ẹ̀sun si alàgba kan, bikoṣe lati ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta. Ba awọn ti o ṣẹ̀ wi niwaju gbogbo enia, ki awọn iyokù pẹlu ki o le bẹ̀ru. Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ati awọn angẹli ayanfẹ, ki iwọ ki o mã ṣakiyesi nkan wọnyi, laiṣe ojuṣãju, lai fi ègbè ṣe ohunkohun. Máṣe fi ikanju gbe ọwọ́ le ẹnikẹni, bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ alabapin ninu ẹ̀ṣẹ̀ awọn ẹlomiran: pa ara rẹ mọ́ ni ìwa funfun. Máṣe mã mu omi nikan, ṣugbọn mã lo waini diẹ nitori inu rẹ, ati nitori ailera rẹ igbakugba. Ẹ̀ṣẹ awọn ẹlomiran a mã han gbangba, a mã lọ ṣãju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mã tẹle wọn. Bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni iṣẹ rere wà ti nwọn hàn gbangba; awọn iru miran kò si le farasin.

I. Tim 5:1-25 Yoruba Bible (YCE)

Má máa fi ohùn líle bá àwọn àgbàlagbà wí, ṣugbọn máa gbà wọ́n níyànjú bíi baba rẹ. Máa ṣe sí àwọn ọdọmọkunrin bí ẹ̀gbọ́n ati àbúrò rẹ. Mú àwọn àgbà obinrin bí ìyá; mú àwọn ọ̀dọ́ obinrin bí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ pẹlu ìwà mímọ́ ní ọ̀nà gbogbo. Bu ọlá fún àwọn opó tí wọ́n jẹ́ alailẹnikan. Ṣugbọn bí opó kan bá ní àwọn ọmọ tabi àwọn ọmọ-ọmọ, wọ́n gbọdọ̀ kọ́ láti ṣe ìtọ́jú ìdílé wọn, kí wọ́n san pada ninu ohun tí àwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Èyí ni ohun tí ó dára lójú Ọlọrun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá jẹ́ opó nítòótọ́, tí kò ní ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, Ọlọrun nìkan ni ó ń wò, tí ó ń bẹ̀, tí ó ń gbadura sí tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn opó tí ó bá ń gbádùn ara rẹ̀ káàkiri ti kú sáyé. Àwọn ohun tí o óo máa pa láṣẹ nìyí, kí wọ́n lè jẹ́ aláìlẹ́gàn. Bí ẹnìkan kò bá pèsè fún àwọn ẹbí rẹ̀, pataki jùlọ fún àwọn ìdílé rẹ̀, olúwarẹ̀ ti lòdì sí ẹ̀sìn igbagbọ wa, ó sì burú ju alaigbagbọ lọ. Má kọ orúkọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ bí opó àfi ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọta ọdún, tí ó sì jẹ́ aya ọkọ kan, tí a jẹ́rìí sí iṣẹ́ rere rẹ̀, tí ó tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára, tí ó máa ń ṣe eniyan lálejò, tí kò sí iṣẹ́ tí ó kéré jù tí kò lè ṣe fún àwọn onigbagbọ, tí ó ti ran àwọn tí ó wà ninu ìyọnu lọ́wọ́. Ní kúkúrú, kí ó jẹ́ ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo. Ṣọ́ra nípa kíkọ orúkọ àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ sílẹ̀, nítorí nígbà tí ara wọn bá gbóná, wọn yóo kọ ètò ti Kristi sílẹ̀, wọn yóo fẹ́ tún lọ́kọ. Wọn yóo wá gba ẹ̀bi nítorí wọ́n ti kọ ẹ̀jẹ́ wọn àkọ́kọ́ sílẹ̀. Ati pé nígbà tí wọn bá ń tọ ojúlé kiri, wọ́n ń kọ́ láti ṣe ìmẹ́lẹ́. Kì í sì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nìkan, wọn a máa di olófòófó ati alátojúbọ̀ ọ̀ràn-ọlọ́ràn, wọn a sì máa sọ ohun tí kò yẹ. Nítorí náà mo fẹ́ kí àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tún lọ́kọ, kí wọ́n bímọ, kí wọ́n ní ilé tiwọn. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn kò ní fi ààyè sílẹ̀ fún ọ̀tá láti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́. Nítorí àwọn mìíràn ti yipada, wọ́n ti ń tẹ̀lé Satani. Bí onigbagbọ obinrin kan bá ní àwọn opó ninu ẹbí rẹ̀, òun ni ó níláti ṣe ìtọ́jú wọn. Kò níláti di ẹrù wọn lé ìjọ Ọlọrun lórí, kí ìjọ lè mójútó àwọn tí wọ́n jẹ́ opó gidi. Ó yẹ kí àwọn àgbà tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ aṣiwaju dáradára gba ìdálọ́lá ọ̀nà meji, pataki jùlọ àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ oníwàásù ati olùkọ́ni. Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Má ṣe dí mààlúù tí ó ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ati pé, “Owó oṣù òṣìṣẹ́ tọ́ sí i.” Bí ẹnìkan bá fi ẹ̀sùn kan àgbàlagbà, má ṣe kà á sí àfi tí ẹlẹ́rìí meji tabi mẹta bá wà. Bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wí ní gbangba, kí ẹ̀rù lè ba àwọn yòókù. Mo sọ fún ọ, níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, ati àwọn angẹli tí Kristi ti yàn, pé kí o pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́; má ṣe ojuṣaaju. Má fi ìwàǹwára gbé ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni lórí láti fi jẹ oyè ninu ìjọ, má sì di alábàápín ninu ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ mọ́. Má máa mu omi nìkan, ṣugbọn máa lo waini díẹ̀, nítorí inú tí ń yọ ọ́ lẹ́nu ati nítorí àìsàn tí ó máa ń ṣe ọ́ nígbà gbogbo. Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn sí gbogbo eniyan, àwọn adájọ́ ti mọ̀ wọ́n kí wọ́n tó mú wọn dé kọ́ọ̀tù. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa pẹ́ kí ó tó hàn sóde. Bákan náà ni, iṣẹ́ rere a máa hàn sí gbogbo eniyan. Bí wọn kò bá tilẹ̀ tíì hàn, wọn kò ṣe é bò mọ́lẹ̀ títí.

I. Tim 5:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bí i baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin. Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́. Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó ti í ṣe opó nítòótọ́. Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkára wọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láààyè. Nǹkan wọ̀nyí ni kí wọn máa paláṣẹ, kí wọn lè wà láìlẹ́gàn Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ. Kọ orúkọ ẹni tí kò bá dín ni ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, lẹ́yìn ti ó ti jẹ́ aya ọkọ kan. Ẹni ti a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo. Ṣùgbọ́n ma ṣe kọ orúkọ àwọn opó tí kò dàgbà; nítorí pé nígbà tiwọn bá ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Kristi, wọn á tún fẹ́ láti gbéyàwó. Wọn á di ẹlẹ́bi, nítorí tí wọn ti kọ ìgbàgbọ́ wọn ìṣáájú sílẹ̀. Àti pẹ̀lú wọn ń kọ́ láti ṣe ọ̀lẹ, láti máa kiri láti ilédélé, kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan, ṣùgbọ́n onísọkúsọ àti olófòófó pẹ̀lú, wọn a máa sọ ohun tí kò yẹ. Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí kò dàgbà máa gbéyàwó, kí wọn máa bímọ, kí wọn máa ṣe alábojútó ilé, kí wọn má ṣe fi ààyè sílẹ̀ rárá fún ọ̀tá náà láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn. Nítorí àwọn mìíràn ti yípadà kúrò sí ẹ̀yìn Satani. Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́. Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni. Nítorí tí Ìwé mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.” Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì-mẹ́ta. Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù. Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, àti àwọn angẹli àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúsàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun. Má ṣe fi ìkánjú gbe ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe jẹ́ alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn: pa ara rẹ mọ́ ní ìwà mímọ́. Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúgbà. Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa hàn gbangba, a máa lọ ṣáájú sí ìdájọ́; tí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú a sì máa tẹ̀lé wọn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni iṣẹ́ rere wa máa ń hàn gbangba; bí wọn kò tilẹ̀ tí ì hàn, wọn kò lè fi ara sin títí.