I. Tim 4:1-5
I. Tim 4:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀mí sọ pàtó pé nígbà tí ó bá yá, àwọn ẹlòmíràn yóo yapa kúrò ninu ẹ̀sìn igbagbọ, wọn yóo tẹ̀lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀tàn ati ẹ̀kọ́ tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù wá. Ẹnu àwọn àgàbàgebè eniyan ni ẹ̀kọ́ burúkú wọnyi yóo ti wá, àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ èké; àwọn tí Satani ń darí ẹ̀rí-ọkàn wọn. Irú wọn ni wọ́n ń sọ pé kí eniyan má ṣe gbeyawo. Wọ́n ní kí eniyan má ṣe jẹ àwọn oríṣìí oúnjẹ kan, bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọrun ni ó dá a pé kí àwọn onigbagbọ ati àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ máa jẹ ẹ́ pẹlu ọpẹ́. Nítorí ohun gbogbo tí Ọlọrun dá ni ó dára. Kò sí ohun tí a gbọdọ̀ kọ̀ bí a bá gbà á pẹlu ọpẹ́, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati adura ti sọ ọ́ di mímọ́.
I. Tim 4:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN Ẹmí ntẹnumọ ọ pe, ni igba ikẹhin awọn miran yio kuro ninu igbagbọ́, nwọn o mã fiyesi awọn ẹmí ti ntan-ni-jẹ, ati ẹkọ́ awọn ẹmí èṣu; Nipa agabagebe awọn ti nṣeke, awọn ti ọkàn awọn tikarawọn dabi eyiti a fi irin gbigbona jó. Awọn ti nda-ni-lẹkun ati gbeyawo, ti nwọn si npaṣẹ lati ka ẽwọ onjẹ ti Ọlọrun ti da fun itẹwọgba pẹlu ọpẹ awọn onigbagbọ ati awọn ti o mọ otitọ. Nitori gbogbo ohun ti Ọlọrun dá li o dara, kò si ọkan ti o yẹ ki a kọ̀, bi a ba fi ọpẹ́ gbà a. Nitori a fi ọ̀rọ Ọlọrun ati adura yà a si mimọ́.

I. Tim 4:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó. Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́. Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á. Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.