I. Tim 4:1-16

I. Tim 4:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

ṢUGBỌN Ẹmí ntẹnumọ ọ pe, ni igba ikẹhin awọn miran yio kuro ninu igbagbọ́, nwọn o mã fiyesi awọn ẹmí ti ntan-ni-jẹ, ati ẹkọ́ awọn ẹmí èṣu; Nipa agabagebe awọn ti nṣeke, awọn ti ọkàn awọn tikarawọn dabi eyiti a fi irin gbigbona jó. Awọn ti nda-ni-lẹkun ati gbeyawo, ti nwọn si npaṣẹ lati ka ẽwọ onjẹ ti Ọlọrun ti da fun itẹwọgba pẹlu ọpẹ awọn onigbagbọ ati awọn ti o mọ otitọ. Nitori gbogbo ohun ti Ọlọrun dá li o dara, kò si ọkan ti o yẹ ki a kọ̀, bi a ba fi ọpẹ́ gbà a. Nitori a fi ọ̀rọ Ọlọrun ati adura yà a si mimọ́. Bi iwọ ba nrán awọn ará leti nkan wọnyi, iwọ o jẹ iranṣẹ rere ti Kristi Jesu, ti a nfi ọrọ igbagbọ́ ati ẹ̀kọ rere bọ́, eyiti iwọ ti ntẹle. Ṣugbọn kọ̀ ọrọ asan ati itan awọn agba obinrin, si mã tọ́ ara rẹ si ìwa-bi-Ọlọrun. Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀. Otitọ ni ọrọ na, o si yẹ fun itẹwọgbà gbogbo. Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́. Nkan wọnyi ni ki o mã palaṣẹ ki o si mã kọ́ni. Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́. Titi emi o fi de, mã tọju iwe kikà ati igbaniyanju ati ikọ́ni. Máṣe ainani ẹ̀bun ti mbẹ lara rẹ, eyiti a fi fun ọ nipa isọtẹlẹ pẹlu ifọwọle awọn àgba. Mã fiyesi nkan wọnyi; fi ara rẹ fun wọn patapata; ki ilọsiwaju rẹ ki o le hàn gbangba fun gbogbo enia. Mã ṣe itọju ara rẹ ati ẹkọ́ rẹ; mã duro laiyẹsẹ ninu nkan wọnyi: nitori ni ṣiṣe eyi, iwọ ó gbà ara rẹ ati awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ rẹ là.

I. Tim 4:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀mí sọ pàtó pé nígbà tí ó bá yá, àwọn ẹlòmíràn yóo yapa kúrò ninu ẹ̀sìn igbagbọ, wọn yóo tẹ̀lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀tàn ati ẹ̀kọ́ tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù wá. Ẹnu àwọn àgàbàgebè eniyan ni ẹ̀kọ́ burúkú wọnyi yóo ti wá, àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ èké; àwọn tí Satani ń darí ẹ̀rí-ọkàn wọn. Irú wọn ni wọ́n ń sọ pé kí eniyan má ṣe gbeyawo. Wọ́n ní kí eniyan má ṣe jẹ àwọn oríṣìí oúnjẹ kan, bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọrun ni ó dá a pé kí àwọn onigbagbọ ati àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ máa jẹ ẹ́ pẹlu ọpẹ́. Nítorí ohun gbogbo tí Ọlọrun dá ni ó dára. Kò sí ohun tí a gbọdọ̀ kọ̀ bí a bá gbà á pẹlu ọpẹ́, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati adura ti sọ ọ́ di mímọ́. Bí o bá ń fi irú ọ̀rọ̀ báyìí siwaju àwọn arakunrin, ìwọ yóo jẹ́ òjíṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a tọ́ dàgbà ninu ọ̀rọ̀ igbagbọ ati ẹ̀kọ́ rere tí ò ń tẹ̀lé. Má jẹ́ kí á bá ọ ní ìdí ìtàn àgbọ́sọ tí kò wúlò ati àwọn ìtànkítàn tí àwọn ìyá arúgbó fẹ́ràn. Ṣe ara rẹ yẹ fún ìgbé-ayé eniyan Ọlọrun. Eniyan a máa rí anfaani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfaani ti ẹ̀mí kò lópin; nítorí ó ní anfaani ní ayé yìí, ó tún fún eniyan ní anfaani ti ayé tí ń bọ̀. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, ó sì yẹ kí eniyan gbà á tọkàntọkàn. Ìdí tí a fi ń ṣe làálàá nìyí, tí a sì ń jìjàkadì, nítorí a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo eniyan, pàápàá jùlọ ti àwọn onigbagbọ. Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa pa láṣẹ, kí o sì máa kọ́ àwọn eniyan. Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kẹ́gàn rẹ, nítorí pé o jẹ́ ọ̀dọ́. Ṣugbọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn onigbagbọ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, ati ninu ìṣe rẹ, ninu ìfẹ́, ninu igbagbọ ati ninu ìwà pípé. Kí n tó dé, tẹra mọ́ kíka ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ati gbígba àwọn eniyan níyànjú, ati iṣẹ́ olùkọ́ni. Má ṣe àìnáání ẹ̀bùn tí Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí àwọn àgbà ìjọ gbé ọwọ́ lé ọ lórí. Máa lépa àwọn nǹkan wọnyi. Àwọn ni kí o jẹ́ kí ó gba gbogbo àkókò rẹ, kí ìtẹ̀síwájú rẹ lè hàn sí gbogbo eniyan. Máa ṣọ́ ara rẹ ati ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró ṣinṣin ninu wọn. Tí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo gba ara rẹ là ati àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.

I. Tim 4:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó. Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́. Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á. Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́. Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé. Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run. Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo. Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́, Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbani-níyànjú àti ìkọ́ni. Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà. Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn. Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.