I. Tim 3:1-16

I. Tim 3:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ. Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ. Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo; Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo; (Ṣugbọn bi enia kò ba mọ̀ bi ã ti ṣe ikawọ ile ara rẹ̀, on o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?) Ki o má jẹ ẹni titun, kí o má bã gbéraga, ki o si ṣubu sinu ẹbi Èṣu. O si yẹ kí o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn ti mbẹ lode: kí o má ba bọ sinu ẹ̀gan ati sinu idẹkun Èṣu. Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn diakoni lati ni ìwa àgba, ki nwọn má jẹ ẹlẹnu meji, kì nwọn má fi ara wọn fun waini pupọ̀, ki nwọn má jẹ olojukokoro. Ki nwọn mã di ohun ijinlẹ igbagbọ́ mu li ọkàn funfun. Ki a si kọ́ wá idi awọn wọnyi daju pẹlu; nigbana ni ki a jẹ ki nwọn jẹ oyè diakoni, bi nwọn ba jẹ alailẹgan. Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn obinrin lati ni iwa àgba, kì nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin bikoṣe alairekọja, olõtọ li ohun gbogbo. Ki awọn diakoni jẹ ọkọ obinrin kan, ki nwọn ki o káwọ awọn ọmọ wọn ati ile ara wọn daradara. Nitori awọn ti o lò oyè diakoni daradara rà ipo rere fun ara wọn, ati igboiya pupọ ni igbagbọ́ ti mbẹ ninu Kristi Jesu. Iwe nkan wọnyi ni mo kọ si ọ, mo si nreti ati tọ̀ ọ wá ni lọ̃lọ̃. Ṣugbọn bi mo ba pẹ, ki iwọ ki o le mọ̀ bi o ti yẹ fun awọn enia lati mã huwa ninu ile Ọlọrun, ti iṣe ijọ Ọlọrun alãye, ọwọ̀n ati ipilẹ otitọ. Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.

I. Tim 3:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí: bí ẹnikẹ́ni bá dàníyàn láti jẹ́ olùdarí, iṣẹ́ rere ni ó fẹ́ ṣe. Nítorí náà, olùdarí níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn; kò gbọdọ̀ ní ju iyawo kan lọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ọlọ́gbọ́n eniyan, ọmọlúwàbí, ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa ṣe eniyan lálejò, tí ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ni. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, tabi ẹni tí máa ń lu eniyan. Ṣugbọn kí ó jẹ́ onífaradà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ alásọ̀, tabi ẹni tí ó ní ọ̀kánjúwà owó. Ó gbọdọ̀ káwọ́ ilé rẹ̀ dáradára, kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Nítorí ẹni tí kò káwọ́ ilé ara rẹ̀, báwo ni ó ṣe lè mójútó ìjọ Ọlọrun? Kí ó má jẹ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onigbagbọ, kí ó má baà gbéraga, kí ó wá bọ́ sọ́wọ́ Satani. Ṣugbọn kí ó jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀rí rere lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe onigbagbọ, kí ó má baà bọ̀ sinu ẹ̀gàn, kí tàkúté Satani má baà mú un. Bákan náà ni kí àwọn diakoni jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́. Kí wọn má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu meji. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó ń mutí para. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ oníwọ̀ra eniyan. Wọ́n níláti di ohun ìjìnlẹ̀ igbagbọ mú pẹlu ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́. A sì níláti kọ́kọ́ dán wọn wò ná; bí wọ́n bá jẹ́ aláìlẹ́gàn, kí á wá fi wọ́n sí ipò diakoni. Bákan náà ni àwọn obinrin níláti jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́; kí wọn má jẹ́ abanijẹ́. Kí wọn jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, kí wọn jẹ́ ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu ohun gbogbo. Diakoni kò gbọdọ̀ ní ju aya kan lọ; ó sì gbọdọ̀ káwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára ati gbogbo ìdílé rẹ̀. Nítorí àwọn tí wọn bá ṣe iṣẹ́ diakoni dáradára ti ṣí ọ̀nà ipò gíga fún ara wọn. Wọ́n lè sọ̀rọ̀ pẹlu ọpọlọpọ ìgboyà nípa igbagbọ tí ó wà ninu Kristi Jesu. Mo ní ìrètí láti wá sọ́dọ̀ rẹ láìpẹ́, ṣugbọn mò ń kọ ìwé yìí, nítorí bí mo bá pẹ́ kí n tó wá, kí o lè mọ̀ bí ó ti yẹ láti darí ètò ilé Ọlọrun, èyí tíí ṣe ìjọ Ọlọrun alààyè, òpó ati ààbò òtítọ́. Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ: Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara, tí a dá láre ninu ẹ̀mí, tí àwọn angẹli fi ojú rí, tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ, tí a gbàgbọ́ ninu ayé, tí a gbé lọ sinu ògo.

I. Tim 3:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò alábojútó, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́, Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí oníjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó. Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo; Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó ha ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run? Kí ó má jẹ́ ẹni tuntun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má ba à gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi èṣù. Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má ba à bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ̀kùn èṣù. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò. Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun. Kí a kọ́kọ́ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwà àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòtítọ́ ní ohun gbogbo. Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára. Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Kristi Jesu. Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń retí àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́. Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: ẹni tí a fihàn nínú ara, tí a dá láre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn angẹli rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo.