I. Tim 2:8-10
I. Tim 2:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina mo fẹ ki awọn ọkunrin mã gbadura nibi gbogbo, ki nwọn mã gbé ọwọ́ mimọ́ soke, li aibinu ati li aijiyan. Bẹ̃ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsin ṣe ara wọn li ọṣọ́, pẹlu itiju ati ìwa airekọja; kì iṣe pẹlu irun didì ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye, Bikoṣe pẹlu iṣẹ́ rere (eyi ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹwọ ìwa-bi-Ọlọrun).
I. Tim 2:8-10 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà mo fẹ́ kí gbogbo eniyan máa gbadura ninu gbogbo ìsìn, kí wọn máa gbé ọwọ́ adura sókè pẹlu ọkàn kan, láìsí èrò ibinu tabi ọkàn àríyànjiyàn. Bákan náà, kí àwọn obinrin wọ aṣọ bí ó ti yẹ, aṣọ tí kò ní ti eniyan lójú, kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́ níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kí wọn má ṣe di irun wọn ní aláràbarà fún àṣehàn. Kí wọn má ṣe kó ohun ọ̀ṣọ́ bíi wúrà ati ìlẹ̀kẹ̀ tabi aṣọ olówó ńlá sára. Ṣugbọn kí ọ̀ṣọ́ wọn jẹ́ ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, bí ó ti yẹ fún àwọn obinrin olùfọkànsìn.
I. Tim 2:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye, bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.