I. Tim 2:1-15

I. Tim 2:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORINA mo gbà nyin niyanju ṣaju ohun gbogbo, pe ki a mã bẹ̀bẹ, ki a mã gbadura, ki a mã ṣìpẹ, ati ki a mã dupẹ nitori gbogbo enia; Fun awọn ọba, ati gbogbo awọn ti o wà ni ipo giga; ki a le mã lo aiye wa ni idakẹjẹ ati pẹlẹ ninu gbogbo ìwa-bi-Ọlọrun ati ìwa agbà. Nitori eyi dara o si ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun Olugbala wa; Ẹniti o nfẹ ki gbogbo enia ni igbala ki nwọn si wá sinu ìmọ otitọ. Nitori Ọlọrun kan ni mbẹ, Onilaja kan pẹlu larin Ọlọrun ati enia, on papa enia, ani Kristi Jesu; Ẹniti o fi ara rẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo enia, ẹrí li akokò rẹ̀; Nitori eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, (otitọ li emi nsọ, emi kò ṣeke;) olukọ awọn Keferi ni igbagbọ́ ati otitọ. Nitorina mo fẹ ki awọn ọkunrin mã gbadura nibi gbogbo, ki nwọn mã gbé ọwọ́ mimọ́ soke, li aibinu ati li aijiyan. Bẹ̃ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsin ṣe ara wọn li ọṣọ́, pẹlu itiju ati ìwa airekọja; kì iṣe pẹlu irun didì ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye, Bikoṣe pẹlu iṣẹ́ rere (eyi ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹwọ ìwa-bi-Ọlọrun). Jẹ ki obinrin ki o mã fi idakẹjẹ ati itẹriba gbogbo kọ́ ẹkọ́. Ṣugbọn emi kò fi aṣẹ fun obinrin lati mã kọ́ni, tabi lati paṣẹ lori ọkunrin, bikoṣepe ki o dakẹjẹ. Nitori Adamu li a kọ́ dá, lẹhin na, Efa. A kò si tàn Adamu jẹ, ṣugbọn obinrin na, nigbati a tàn a, o ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ. Ṣugbọn a o gbà a là nipa ìbimọ rẹ̀, bi nwọn ba duro ninu igbagbọ́ ati ifẹ, ati ìwa mimọ́ pẹlu ìwa airekọja.

I. Tim 2:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, lákọ̀ọ́kọ́, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o máa tọrọ ninu adura, kí o máa bẹ̀bẹ̀, kí o sì máa dúpẹ́ fún gbogbo eniyan, fún àwọn ọba, ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ipò gíga, pé kí á máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí á máa gbé ìgbé-ayé bí olùfọkànsìn ati bí ọmọlúwàbí. Irú adura báyìí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọrun Olùgbàlà wa, ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo eniyan rí ìgbàlà, tí ó sì fẹ́ kí wọn ní ìmọ̀ òtítọ́. Nítorí Ọlọrun kan ni ó wà, alárinà kan ni ó sì wà láàrin Ọlọrun ati eniyan; olúwarẹ̀ ni Kristi Jesu, tí òun náà jẹ́ eniyan, tí ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo eniyan. Èyí ni ẹ̀rí pé, Ọlọrun ṣe ètò pé kí gbogbo eniyan lè ní ìgbàlà nígbà tí àkókò rẹ̀ tó. Òtítọ́ ni mò ń sọ, n kò purọ́, pé ohun tí a yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli sí ni pé kí n jẹ́ olùkọ́ni fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ igbagbọ ati òtítọ́ Ọlọrun. Nítorí náà mo fẹ́ kí gbogbo eniyan máa gbadura ninu gbogbo ìsìn, kí wọn máa gbé ọwọ́ adura sókè pẹlu ọkàn kan, láìsí èrò ibinu tabi ọkàn àríyànjiyàn. Bákan náà, kí àwọn obinrin wọ aṣọ bí ó ti yẹ, aṣọ tí kò ní ti eniyan lójú, kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́ níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kí wọn má ṣe di irun wọn ní aláràbarà fún àṣehàn. Kí wọn má ṣe kó ohun ọ̀ṣọ́ bíi wúrà ati ìlẹ̀kẹ̀ tabi aṣọ olówó ńlá sára. Ṣugbọn kí ọ̀ṣọ́ wọn jẹ́ ọpọlọpọ iṣẹ́ rere, bí ó ti yẹ fún àwọn obinrin olùfọkànsìn. Obinrin níláti máa fi ìfarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pẹlu ìtẹríba. N kò gbà fún obinrin láti jẹ́ olùkọ́ni tabi láti ní àṣẹ lórí ọkunrin. Kí obinrin máa panumọ́ ni. Nítorí Adamu ni a kọ́kọ́ dá, kí á tó dá Efa. Kì í sì í ṣe Adamu ni a tàn jẹ, obinrin ni a tàn jẹ tí ó fi di ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn a óo gba obinrin là nípa ọmọ-bíbí, bí àwọn obinrin bá dúró láì yẹsẹ̀ ninu igbagbọ ati ìfẹ́ ati ìwà mímọ́ pẹlu ìwà ìkóra-ẹni-níjàánu.

I. Tim 2:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn. Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́. Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa; Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́. Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà. Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ. Nítorí èyí tí a yàn mi ṣe oníwàásù, aposteli òtítọ́ ni èmi ń sọ, èmi kò ṣèké olùkọ́ àwọn aláìkọlà nínú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́. Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye, bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run. Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorí Adamu ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Efa. Adamu kọ́ ni a tànjẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n a ó gbà àwọn obìnrin là nípa ìbímọ wọn, bí wọ́n bá dúró nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìwà mímọ́ pẹ̀lú ìwà àìrékọjá.