I. Tim 1:8-11
I. Tim 1:8-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awa mọ̀ pe ofin dara, bi enia ba lò o bi ã ti ilo ofin; Bi a ti mọ̀ eyi pe, a kò ṣe ofin fun olododo, bikoṣe fun awọn alailofin ati awọn alaigbọran, fun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ati awọn ẹlẹṣẹ, fun awọn alaimọ́ ati awọn ẹlẹgan, fun awọn apa-baba ati awọn apa-iya, fun awọn apania, Fun awọn àgbere, fun awọn ti nfi ọkunrin ba ara wọn jẹ́, fun awọn ají-enia tà, fun awọn eke, fun awọn abura eke, ati bi ohun miran ba si wà ti o lodi si ẹkọ́ ti o yè koro, Gẹgẹ bi ihinrere ti ogo Ọlọrun olubukún, ti a fi si itọju mi.
I. Tim 1:8-11 Yoruba Bible (YCE)
A mọ̀ pé òfin jẹ́ ohun tí ó dára bí a bá lò ó bí ó ti tọ́. A mọ èyí pé a kò ṣe òfin fún àwọn eniyan rere, bí kò ṣe fún àwọn oníwàkiwà ati àwọn alágídí, àwọn aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn oníbàjẹ́ ati àwọn aláìbìkítà fún ohun mímọ́, àwọn tí wọn máa ń lu baba ati ìyá wọn, àwọn àgbèrè, àwọn ọkunrin tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀, àwọn gbọ́mọgbọ́mọ, àwọn onírọ́, àwọn tí ó ń búra èké, ati àwọn tí ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó dára, gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí a fi lé mi lọ́wọ́, ìyìn rere Ọlọrun Ológo, tí ìyìn yẹ fún.
I. Tim 1:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára. Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn, fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro. Gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.