I. Tim 1:3-5
I. Tim 1:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi mo ti gba ọ niyanju lati joko ni Efesu, nigbati mo nlọ si Makedonia, ki iwọ ki o le paṣẹ fun awọn kan, ki nwọn ki o máṣe kọ́ni li ẹkọ́ miran, Ki nwọn má si ṣe fiyesi awọn itan lasan, ati ti ìran ti kò li opin, eyiti imã mú ijiyan wa dipo iṣẹ iriju Ọlọrun ti mbẹ ninu igbagbọ́; bẹni mo ṣe nisisiyi. Ṣugbọn opin aṣẹ na ni ifẹ lati ọkàn mimọ́ ati ẹri-ọkan rere ati igbagbọ́ aiṣẹtan wa.
I. Tim 1:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí mò ń lọ sí Masedonia, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o dúró ní Efesu, kí o pàṣẹ fún àwọn kan kí wọn má ṣe kọ́ eniyan ní ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà, kí wọn má jókòó ti àwọn ìtàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ati ìtàn ìrandíran tí kò lópin, tí ó máa ń mú àríyànjiyàn wá, dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọrun tí a mọ̀ nípa igbagbọ. Ìdí tí mo fi pa àṣẹ yìí ni láti ta ìfẹ́ àtọkànwá jí ninu rẹ, pẹlu ẹ̀rí ọkàn rere ati igbagbọ tí kò lẹ́tàn.
I. Tim 1:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí mo ṣe rọ̀ yìn nígbà tí mò ń lọ sí Makedonia, ẹ dúró ní Efesu, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́ kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn asán, àti ìtàn ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́. Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn.