I. Tes 5:16-24
I. Tes 5:16-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo. Ẹ mã gbadura li aisimi. Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin. Ẹ máṣe pa iná Ẹmí. Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ. Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin. Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi. Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi. Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e.
I. Tes 5:16-24 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa gbadura láì sinmi. Ẹ máa dúpẹ́ ninu ohun gbogbo nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun nípa Kristi Jesu fun yín. Ẹ má máa da omi tútù sí àwọn tí ó ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ lọ́kàn. Ẹ má máa fi ojú tẹmbẹlu ẹ̀bùn wolii. Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin. Ẹ máa takété sí ohunkohun tí ó bá burú. Kí Ọlọrun alaafia kí ó yà yín sí mímọ́ patapata; kí ó pa gbogbo ẹ̀mí yín mọ́ ati ọkàn, ati ara yín. Kí èyíkéyìí má ní àbùkù nígbà tí Oluwa wa Jesu Kristi bá farahàn. Ẹni tí ó pè yín yóo ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé olóòótọ́ ni.
I. Tes 5:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́. Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń sọtẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú. Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi. Kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ọlọ́run àlàáfíà, sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́ pátápátá ní àìlábùkù, títí di ìgbà wíwá Jesu Kristi Olúwa wa. Olóòtítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.