I. Tes 5:12-15
I. Tes 5:12-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin; Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin. Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, ki ẹ mã kìlọ fun awọn ti iṣe alaigbọran, ẹ mã tù awọn alailọkàn ninu, ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ẹ mã mu sũru fun gbogbo enia. Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia.
I. Tes 5:12-15 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa bu ọlá fún àwọn tí ń ṣe làálàá láàrin yín, tí wọn ń darí yín nípa ti Oluwa, tí wọn ń gbà yín níyànjú. Ẹ máa fi ìfẹ́ yẹ́ wọn sí gidigidi nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ máa wà ní alaafia láàrin ara yín. Ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa gba àwọn tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ níyànjú; bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn tí ó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn; ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́; ẹ máa mú sùúrù pẹlu gbogbo eniyan. Kí ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni kò fi burúkú gbẹ̀san burúkú lára ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn nígbà gbogbo kí ẹ máa lépa nǹkan rere láàrin ara yín ati láàrin gbogbo eniyan.
I. Tes 5:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrín yín tí wọn ń kìlọ̀ fún yín nínú Olúwa. Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ sì máa wà ní àlàáfíà láàrín ara yín. Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrín yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.