I. Tes 4:9-10
I. Tes 4:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn niti ifẹ awọn ará, ẹ kò tun fẹ ki ẹnikẹni kọwe si nyin: nitori a ti kọ́ ẹnyin tikaranyin lati ọdọ Ọlọrun wá lati mã fẹ ara nyin. Nitõtọ ẹnyin si nṣe e si gbogbo awọn ará ti o wà ni gbogbo Makedonia: ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, pe ki ẹnyin ki o mã pọ̀ siwaju si i
I. Tes 4:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, nítorí Ọlọrun ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti fẹ́ràn ọmọnikeji yín. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ sì ń ṣe sí gbogbo àwọn onigbagbọ ní gbogbo Masedonia. Ẹ̀yin ará, mò ń rọ̀ yín, ẹ túbọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ ati jù bẹ́ẹ̀ lọ.
I. Tes 4:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín. Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀.