I. Tes 3:11-13
I. Tes 3:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ ki Ọlọrun ati Baba wa tikararẹ, ati Jesu Kristi Oluwa wa, ṣe amọ̀na wa sọdọ nyin. Ki Oluwa si mã mu nyin bisi i, ki ẹ si mã pọ̀ ninu ifẹ si ọmọnikeji nyin, ati si gbogbo enia, gẹgẹ bi awa ti nṣe si nyin: Ki o ba le fi ọkàn nyin balẹ li ailabukù ninu ìwa mimọ́ niwaju Ọlọrun ati Baba wa, nigba atiwá Jesu Kristi Oluwa wa pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀.
I. Tes 3:11-13 Yoruba Bible (YCE)
Ǹjẹ́ nisinsinyii, kí Ọlọrun Baba wa fúnrarẹ̀ ati Oluwa wa Jesu kí ó tọ́ ẹsẹ̀ wa sí ọ̀nà dé ọ̀dọ̀ yín. Kí Oluwa mú kí ìfẹ́ yín sí ara yín ati sí gbogbo eniyan kí ó pọ̀ sí i, kí ó sì túbọ̀ jinlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí tiwa ti rí si yín. Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
I. Tes 3:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jesu Kristi láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í. A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà. Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.