I. Tes 3:1-13

I. Tes 3:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORINA nigbati ara wa kò gba a mọ́, awa rò pe o dara ki a fi awa nikan sẹhin ni Ateni; Awa si rán Timotiu, arakunrin wa, ati iranṣẹ Ọlọrun ninu ihinrere Kristi, lati fi ẹsẹ nyin mulẹ, ati lati tù nyin ninu niti igbagbọ́ nyin: Ki a máṣe mu ẹnikẹni yẹsẹ nipa wahalà wọnyi: nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ pe a ti yàn wa sinu rẹ̀. Nitori nitõtọ nigbati awa wà lọdọ nyin, a ti nsọ fun nyin tẹlẹ pe, awa ó ri wahalà; gẹgẹ bi o si ti ṣẹ, ti ẹnyin si mọ̀. Nitori eyi, nigbati ara mi kò gba a mọ́, mo si ranṣẹ ki emi ki o le mọ igbagbọ́ nyin ki oludanwò nì má bã ti dan nyin wo lọnakọna, ki lãlã wa si jẹ asan. Ṣugbọn nisisiyi ti Timotiu ti ti ọdọ nyin wá sọdọ wa, ti o si ti mu ihinrere ti igbagbọ́ ati ifẹ nyin wá fun wa, ati pe ẹnyin nṣe iranti wa ni rere nigbagbogbo, ẹnyin si nfẹ gidigidi lati ri wa, bi awa pẹlu si ti nfẹ lati ri nyin: Nitori eyi, ará, awa ni itunu lori nyin ninu gbogbo wahalà ati ipọnju wa nitori igbagbọ́ nyin: Nitori awa yè nisisiyi, bi ẹnyin ba duro ṣinṣin ninu Oluwa. Nitori ọpẹ́ kili awa le tún ma dá lọwọ Ọlọrun nitori nyin, fun gbogbo ayọ̀ ti awa nyọ̀ nitori nyin niwaju Ọlọrun wa; Li ọsán ati li oru li awa ngbadura gidigidi pe, ki awa ki o le ri oju nyin, ki a si ṣe aṣepé eyiti o kù ninu igbagbọ́ nyin? Njẹ ki Ọlọrun ati Baba wa tikararẹ, ati Jesu Kristi Oluwa wa, ṣe amọ̀na wa sọdọ nyin. Ki Oluwa si mã mu nyin bisi i, ki ẹ si mã pọ̀ ninu ifẹ si ọmọnikeji nyin, ati si gbogbo enia, gẹgẹ bi awa ti nṣe si nyin: Ki o ba le fi ọkàn nyin balẹ li ailabukù ninu ìwa mimọ́ niwaju Ọlọrun ati Baba wa, nigba atiwá Jesu Kristi Oluwa wa pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀.

I. Tes 3:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí náà, nígbà tí ara wa kò gbà á mọ́, a pinnu pé kí ó kúkú ku àwa nìkan ní Atẹni; ni a bá rán Timoti si yín, ẹni tí ó jẹ́ arakunrin wa ati alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun ninu iṣẹ́ ìyìn rere ti Kristi, kí ó lè máa gbà yín níyànjú, kí igbagbọ yín lè dúró gbọnin-gbọnin. Kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ ní àkókò inúnibíni yìí. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé onigbagbọ níláti rí irú ìrírí yìí. Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀ pé a níláti jìyà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, bí ẹ̀yin náà ti mọ̀. Nítorí náà, èmi náà kò lè fi ara dà á mọ́, ni mo bá ranṣẹ láti wá wádìí nípa ìdúró yín, kí ó má baà jẹ́ pé olùdánwò ti dán yín wò, kí akitiyan wa má baà já sí òfo. Ṣugbọn nisinsinyii, Timoti ti ti ọ̀dọ̀ yín dé, ó ti fún wa ní ìròyìn rere nípa igbagbọ ati ìfẹ́ yín. Ó ní ẹ̀ ń ranti wa sí rere nígbà gbogbo, ati pé bí ọkàn yin ti ń fà wá, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ti àwa náà ń fà yín. Ará, ìròyìn yìí fún wa ní ìwúrí nípa yín, nítorí igbagbọ yín, a lè gba gbogbo ìṣòro ati inúnibíni tí à ń rí. Nítorí pé bí ẹ bá dúró gbọningbọnin ninu Oluwa nisinsinyii, a jẹ́ pé wíwà láàyè wa kò jẹ́ lásán. Nítorí pé ọpẹ́ mélòó ni a lè dá lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, lórí gbogbo ayọ̀ tí à ń yọ̀ nítorí yín níwájú Ọlọrun wa? À ń gbadura kíkankíkan tọ̀sán-tòru pé kí á lè fi ojú kàn yín, kí á lè ṣe àtúnṣe níbi tí igbagbọ yín bá kù kí ó tó. Ǹjẹ́ nisinsinyii, kí Ọlọrun Baba wa fúnrarẹ̀ ati Oluwa wa Jesu kí ó tọ́ ẹsẹ̀ wa sí ọ̀nà dé ọ̀dọ̀ yín. Kí Oluwa mú kí ìfẹ́ yín sí ara yín ati sí gbogbo eniyan kí ó pọ̀ sí i, kí ó sì túbọ̀ jinlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí tiwa ti rí si yín. Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.

I. Tes 3:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Ateni. Awa sì rán Timotiu, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Ọlọ́run nínú ìhìnrere Kristi, láti fi ẹsẹ yín múlẹ̀, àti láti tù yín nínú ní ti ìgbàgbọ́ yín. Láìsí àní àní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwọn tí ó gbàgbọ́, kí a má ba dààmú. Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò dé. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́. Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba á mọ́, mo sì ránṣẹ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ìgbàgbọ́ yín, kí olùdánwò nì má ba à dán an yín wò lọ́nàkọnà, kí làálàá wa sì jásí asán. Nísinsin yìí, Timotiu ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín ṣì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ ṣì ń rántí ìbágbé wa láàrín yín pẹ̀lú ayọ̀. Timotiu tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsin yìí pé, ẹ̀yin dúró gbọningbọnin fún Olúwa. Nítorí àwa yè nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa. Kò ṣe é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín. Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí. À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jesu Kristi láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í. A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà. Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.