I. Sam 4:1-22
I. Sam 4:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Samueli si wá si gbogbo Israeli: Israeli si jade lọ pade awọn Filistini lati jagun, nwọn do si eti Ebeneseri: awọn Filistini si do ni Afeki. Awọn Filistini si tẹ itẹgun lati pade Israeli: nigbati nwọn pade ija, awọn Filistini si le Israeli: nwọn si pa iwọn ẹgbaji ọkunrin ni itẹgun ni papa. Awọn enia si de budo, awọn agbà Israeli si wipe, Nitori kini Oluwa ṣe le wa loni niwaju awọn Filistini? Ẹ jẹ ki a mu apoti majẹmu Oluwa ti mbẹ ni Ṣilo sọdọ wa, pe, nigbati o ba de arin wa, ki o le gba wa kuro lọwọ awọn ọta wa. Bẹli awọn enia si ranṣẹ si Ṣilo, pe ki nwọn gbe lati ibẹ wá apoti majẹmu Oluwa awọn ọmọ-ogun ẹniti o joko larin awọn kerubu: ati awọn ọmọ Eli mejeji, Hofni ati Finehasi, wà nibẹ pẹlu apoti majẹmu Ọlọrun. Nigbati apoti majẹmu Oluwa de budo, gbogbo Israeli si ho yè, tobẹ̃ ti ilẹ mì. Nigbati awọn Filistini si gbọ́ ohùn ariwo na, nwọn si wipe, Ohùn ariwo nla kili eyi ni budo awọn Heberu? O si wa ye wọn pe, apoti majẹmu Oluwa li o de budo. Ẹ̀ru si ba awọn Filistini, nwọn si wipe, Ọlọrun wọ budo. Nwọn si wipe, Awa gbe! nitoripe iru nkan bayi kò si ri. A gbe! tani yio gbà wa lọwọ Ọlọrun alagbara wọnyi? awọn wọnyi li Ọlọrun ti o fi gbogbo ipọnju pọn Egipti loju li aginju. Ẹ jẹ alagbara, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹnyin Filistini, ki ẹnyin máṣe ẹrú fun awọn Heberu, bi nwọn ti nṣe ẹrú nyin ri: Ẹ ṣe bi ọkunrin, ki ẹ si ja. Awọn Filistini si ja, nwọn si lé Israeli, nwọn si sa olukuluku sinu ago rẹ̀: ipani si pọ̀ gidigidi, awọn ẹlẹsẹ ti o ṣubu ninu ogun Israeli jẹ ẹgbãmẹdogun. Nwọn si gbà apoti ẹri Ọlọrun: ọmọ Eli mejeji si kú, Hofni ati Finehasi. Ọkunrin ara Benjamini kan sa lati ogun wá o si wá si Ṣilo lọjọ kanna, ti on ti aṣọ rẹ̀ fifaya, ati erupẹ lori rẹ̀. Nigbati o si de, si wõ, Eli joko lori apoti kan lẹba ọ̀na o nṣọna: nitori aiyà rẹ̀ kò balẹ nitori apoti Ọlọrun. Ọkunrin na si wọ ilu lati rohin, gbogbo ilu fi igbe ta. Eli si gbọ́ ohùn igbe na, o sì wipe, Ohùn igbe kili eyi? ọkunrin na si yara wá o si rò fun Eli. Eli si di ẹni ejidilọgọrun ọdun; oju rẹ̀ di baibai, kò si le riran. Ọkunrin na si wi fun Eli pe, Emi li ẹniti o ti ogun wá, loni ni mo sa ti ogun na wá; o si bi i pe, Eti ri, ọmọ mi? Ẹniti o mu ihin wá si dahun o si wipe, Israeli sa niwaju awọn Filistini, iṣubu na si pọ ninu awọn enia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji, Hofni ati Finehasi si kú, nwọn si gbà apoti Ọlọrun. O sì ṣe, nigbati o darukọ apoti Ọlọrun, o ṣubu ṣehin kuro lori apoti lẹba bode, ọrun rẹ̀ si ṣẹ, o si kú: nitori o di arugbo tan, o si tobi. O si ṣe idajọ Israeli li ogoji ọdun. Aya ọmọ rẹ̀, obinrin Finehasi, loyun, o si sunmọ ọjọ ibi rẹ̀; nigbati o si gbọ́ ihìn pe a ti gbà apoti Ọlọrun, ati pe, baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ kú, o kunlẹ, o si bimọ, nitori obí tẹ̀ ẹ. Lakoko ikú rẹ̀ awọn obinrin ti o duro tì i si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; nitoriti iwọ bi ọmọkunrin kan. Ko dahun, kò si kà a si. On si pe ọmọ na ni Ikabodu, wipe, Kò si ogo fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun, ati nitori ti baba ọkọ rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀. O si wipe, Ogo kò si fun Israeli mọ: nitoriti a ti gbà apoti Ọlọrun.
I. Sam 4:1-22 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli náà bá kó ogun jáde láti bá wọn jà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pàgọ́ sí Ebeneseri, àwọn ọmọ ogun Filistini sì pa tiwọn sí Afeki. Àwọn ọmọ ogun Filistini ni wọ́n kọ́ kọlu àwọn ọmọ ogun Israẹli, nígbà tí àwọn mejeeji gbógun pàdé ara wọn, tí wọ́n sì jà fitafita; àwọn ọmọ ogun Filistini ṣẹgun Israẹli, wọ́n sì pa nǹkan bíi ẹgbaaji (4,000) ninu wọn. Nígbà tí wọ́n pada dé ibùdó, àwọn àgbààgbà Israẹli bèèrè pé, “Kí ló dé tí OLUWA fi jẹ́ kí àwọn ará Filistia ṣẹgun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí á lọ gbé àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní Ṣilo wá sọ́dọ̀ wa, kí ó lè máa bá wa lọ, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí Ṣilo láti gbé àpótí ẹ̀rí OLUWA tí ó gúnwà láàrin àwọn Kerubu. Àwọn ọmọ Eli mejeeji, Hofini ati Finehasi, sì tẹ̀lé àpótí ẹ̀rí náà. Nígbà tí wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí dé ibùdó, gbogbo Israẹli hó ìhó ayọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì tìtì. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ híhó tí wọn ń hó, wọ́n ní, “Irú ariwo ńlá wo ni àwọn Heberu ń pa ní ibùdó wọn yìí?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àpótí ẹ̀rí OLUWA ni ó dé sí ibùdó àwọn Heberu, ẹ̀rù ba àwọn ará Filistia. Wọ́n ní, “Oriṣa kan ti dé sí ibùdó wọn! A gbé! Irú èyí kò ṣẹlẹ̀ rí. A gbé! Ta ni lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn oriṣa tí ó lágbára wọnyi? Àwọn ni wọ́n pa àwọn ará Ijipti ní ìpakúpa ninu aṣálẹ̀. Ẹ ṣe ọkàn yín gírí, ẹ̀yin ọmọ ogun Filistini! Ẹ ṣe bí akọni, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óo di ẹrú àwọn ará Heberu gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti jẹ́ ẹrú wa, nítorí náà, ẹ ṣe bí akọni, kí ẹ sì jà.” Àwọn ọmọ ogun Filistini jà fitafita, wọ́n ṣẹgun Israẹli, olukuluku àwọn ọmọ Israẹli sì sá pada lọ sí ilé rẹ̀, ọpọlọpọ ló kú ninu wọn. Ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaarun (30,000) ni ọmọ ogun Filistini pa ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli tí ń fi ẹsẹ̀ rìn. Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli mejeeji. Ọkunrin kan láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ti ojú ogun sáré pada lọ sí Ṣilo, ó sì dé ibẹ̀ lọ́jọ́ náà. Ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sórí láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Ọkàn Eli dàrú gidigidi nítorí àpótí ẹ̀rí náà, ó sì jókòó lórí àga rẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń wo òréré. Ọkunrin tí ó ti ojú ogun wá bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn fún àwọn ará ìlú, ẹ̀rù ba olukuluku, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké. Nígbà tí Eli gbọ́ igbe wọn, ó bèèrè pé, “Kí ni wọ́n ń kígbe báyìí fún?” Ọkunrin náà bá yára wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Eli. Eli ti di ẹni ọdún mejidinlọgọrun-un ní àkókò yìí, ojú rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ má ríran mọ́ rárá. Ọkunrin náà wí fún un pé, “Ojú ogun ni mo ti sá wá lónìí.” Eli bá bi í pé, “Kí ló dé, ọmọ mi?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn ará Filistia. Wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wa, wọ́n pa Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ rẹ mejeeji pẹlu. Wọ́n sì gbé àpótí Ọlọrun lọ.” Nígbà tí ọkunrin náà fẹnu kan àpótí Ọlọ́run, Eli ṣubú sẹ́yìn lórí àpótí tí ó jókòó lé ní ẹnu ọ̀nà, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí pé ó ti di arúgbó, ó sì sanra. Ogoji ọdún ni Eli fi ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli. Iyawo Finehasi, ọmọ Eli, wà ninu oyún ní àkókò náà, ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ sì ti súnmọ́ etílé. Nígbà tí ó gbọ́ pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ, ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú, lẹsẹkẹsẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, tí ó sì bímọ. Bí ó ti ń kú lọ, àwọn obinrin tí wọn ń gbẹ̀bí rẹ̀ wí fún un pé, “Ṣe ọkàn gírí, ọkunrin ni ọmọ tí o bí.” Ṣugbọn kò tilẹ̀ kọ ibi ara sí ohun tí wọ́n sọ, kò sì dá wọn lóhùn. Ó bá sọ ọmọ náà ní Ikabodu, ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀.” Nítorí pé wọ́n ti gba àpótí Ọlọrun ati pé baba ọkọ rẹ̀ ati ọkọ rẹ̀ ti kú. Ó ní, “Ògo Ọlọrun ti fi Israẹli sílẹ̀, nítorí pé wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun lọ.”
I. Sam 4:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ Samuẹli tọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá. Nísinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli jáde láti lọ bá àwọn Filistini jà. Àwọn ọmọ Israẹli sì pàgọ́ sí Ebeneseri àti àwọn Filistini ní Afeki. Àwọn Filistini mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Israẹli, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Filistini ṣẹ́gun Israẹli wọ́n pa ẹgbàajì ọkùnrin nínú ogun náà (4,000). Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbàgbà Israẹli sì béèrè pé, “Èéṣe ti OLúWA fi mú kí àwọn Filistini ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA láti Ṣilo wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣilo, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wá, ẹni tí ń wà láàrín àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Eli méjèèjì Hofini àti Finehasi wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Nígbà tí àpótí ẹ̀rí OLúWA wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì. Ní ìgbà tí àwọn Filistini gbọ́ ariwo náà wọ́n béèrè pé, “Kí ni gbogbo ariwo yìí ní ibùdó Heberu?” Nígbà tí wọ́n mọ̀ wí pé àpótí ẹ̀rí OLúWA ti wá sí ibùdó, Àwọn Filistini sì bẹ̀rù pé, Ọlọ́run kékeré ti wọ ibùdó, wọ́n wí pé, “A wọ wàhálà, irú èyí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí. Àwa gbé! Ta ni yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run alágbára yìí? Àwọn ni Ọlọ́run tí ó fi ìpọ́njú pa àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo àjàkálẹ̀-ààrùn ní aginjù. Ẹ jẹ́ alágbára Filistini, ẹ ṣe bí ọkùnrin, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin yóò di ẹrú àwọn Heberu, bí wọ́n ti jẹ́ sí i yín: Ẹ jẹ́ alágbára ọkùnrin, kí ẹ sì jagun!” Nígbà náà àwọn Filistini jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Israẹli olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn; Àwọn ará Israẹli tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́dógún àwọn ọmọ-ogun orí ilẹ̀ (30,000). Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí OLúWA, àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì sì kú, Hofini àti Finehasi. Lọ́jọ́ kan náà tí ará Benjamini kan sá wá láti ojú ogun tí ó sì lọ sí Ṣilo, aṣọ rẹ̀ sì fàya pẹ̀lú eruku lórí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé, Eli sì jókòó sórí àga rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó ń wò, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí àpótí ẹ̀rí OLúWA. Nígbà tí ọkùnrin náà wọ ìlú tí ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Eli gbọ́ ìró ohùn ẹkún náà ó sì béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ ariwo yìí?” Ọkùnrin náà sì sáré tọ Eli wá Eli sì di ẹni méjì-dínlọ́gọ́run ọdún, tí ojú rẹ̀ di bàìbàì, kò sì ríran mọ́. Ọkùnrin náà sọ fún Eli, “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ibi ogun náà ni: mo sá láti ibi ogun náà wá lónìí.” Eli sì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ọmọ mi?” Ọkùnrin tí ó mú ìròyìn náà wá dáhùn pé, “Israẹli sá níwájú àwọn Filistini, ìṣubú àwọn ọmọ-ogun náà sì pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, wọ́n kú, wọ́n sì ti gba àpótí ẹ̀rí OLúWA lọ.” Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí OLúWA, Eli sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Israẹli fún ogójì ọdún. Aya ọmọ rẹ̀, ìyàwó Finehasi, ó lóyún ó súnmọ́ àkókò àti bí. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn náà wí pé wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí OLúWA lọ àti wí pé baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó rọbí ó sì bímọ, ó sì borí ìrora ìrọbí náà. Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù; nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin.” Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i. Ó sì pe ọmọ náà ní Ikabodu, wí pé, “Kò sí ògo fún Israẹli mọ́” nítorí tí wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àti ikú baba ọkọ rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀. Ó si wí pé, “Ògo kò sí fún Israẹli mọ́, nítorí ti a ti gbá àpótí Ọlọ́run.”