I. Sam 30:1-31

I. Sam 30:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si bọ̀ si Siklagi ni ijọ kẹta, awọn ara Amaleki si ti kọlu iha ariwa, ati Siklagi, nwọn si ti kun u; Nwọn si ko awọn obinrin ti mbẹ ninu rẹ̀ ni igbekun, nwọn kò si pa ẹnikan, ọmọde tabi agbà, ṣugbọn nwọn ko nwọn lọ, nwọn si ba ọ̀na ti nwọn lọ. Dafidi ati awọn ọmọkunrin si wọ ilu, si wõ, a ti kun u; ati obinrin wọn, ati ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn li a kó ni igbèkun lọ. Dafidi ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun titi agbara kò si si fun wọn mọ lati sọkun. A si kó awọn aya Dafidi mejeji nigbèkun lọ, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili aya, Nabali ara Karmeli. Dafidi si banujẹ gidigidi, nitoripe awọn enia na si nsọ̀rọ lati sọ ọ li okuta, nitoriti inu gbogbo awọn enia na si bajẹ, olukuluku ọkunrin nitori ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati nitori ọmọ rẹ̀ obinrin: ṣugbọn Dafidi mu ara rẹ̀ li ọkàn le ninu Oluwa Ọlọrun rẹ̀. Dafidi si wi fun Abiatari alufa, ọmọ Ahimeleki pe, Emi bẹ̀ ọ, mu efodu fun mi wá nihinyi. Abiatari si mu efodu na wá fun Dafidi. Dafidi si bere lọdọ Oluwa wipe, Ki emi ki o lepa ogun yi bi? emi le ba wọn? O si da a lohùn pe, Lepa: nitoripe ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà. Bẹni Dafidi ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si lọ, nwọn si wá si ibi odo Besori, apakan si duro. Ṣugbọn Dafidi ati irinwo ọmọkunrin lepa wọn: igba enia ti ãrẹ̀ mu, ti nwọn kò le kọja odò Besori si duro lẹhin. Nwọn si ri ara Egipti kan li oko, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá, nwọn si fun u li onjẹ, o si jẹ; nwọn si fun u li omi mu; Nwọn si bùn u li akara eso ọpọtọ ati ṣiri ajara gbigbẹ meji: nigbati o si jẹ ẹ tan, ẹmi rẹ̀ si sọji: nitoripe ko jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò si mu omi ni ijọ mẹta li ọsan, ati li oru. Dafidi si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ iṣe? ati nibo ni iwọ ti wá? On si wipe, ọmọ ara Egipti li emi iṣe, ọmọ-ọdọ ọkunrin kan ara Amaleki; oluwa mi si fi mi silẹ, nitoripe lati ijọ mẹta li emi ti ṣe aisan. Awa si gbe ogun lọ siha gusu ti ara Keriti, ati si apa ti iṣe ti Juda, ati si iha gusu ti Kelebu; awa si kun Siklagi. Dafidi si bi i lere pe, Iwọ le mu mi sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun yi lọ bi? On si wipe, Fi Ọlọrun bura fun mi, pe, iwọ kì yio pa mi, bẹ̃ni iwọ kì yio si fi mi le oluwa mi lọwọ; emi o si mu ọ sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun na lọ. O si mu u sọkalẹ, si wõ, nwọn si tànka ilẹ, nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn si njo, nitori ikogun pupọ ti nwọn ko lati ilẹ awọn Filistini wá, ati lati ilẹ Juda. Dafidi si pa wọn lati afẹmọjumọ titi o fi di aṣalẹ ijọ keji: kò si si ẹnikan ti o là ninu wọn, bikoṣe irinwo ọmọkunrin ti nwọn gun ibakasiẹ ti nwọn si sa. Dafidi si gba gbogbo nkan ti awọn ara Amaleki ti ko: Dafidi si gbà awọn obinrin rẹ̀ mejeji. Kò si si nkan ti o kù fun wọn, kekere tabi nla, ọmọkunrin tabi ọmọbinrin, tabi ikogun, tabi gbogbo nkan ti nwọn ti ko: Dafidi si gbà gbogbo wọn. Dafidi si ko gbogbo agutan, ati malu, nwọn si dà wọn ṣaju nkan miran ti nwọn gbà, nwọn si wipe, Eyiyi ni ikogun ti Dafidi. Dafidi si ba igba ọkunrin ti o ti rẹ̀ jù ati tọ̀ Dafidi lẹhin, ti on ti fi silẹ li odò Besori: nwọn si lọ ipade Dafidi, ati lati pade awọn enia ti o pẹlu rẹ̀: Dafidi si pade awọn enia na, o si ki wọn. Gbogbo awọn enia buburu ati awọn ọmọ Beliali ninu awọn ti o ba Dafidi lọ si dahun, nwọn si wipe, Bi nwọn kò ti ba wa lọ, a kì yio fi nkan kan fun wọn ninu ikogun ti awa rí gbà bikoṣe obinrin olukuluku wọn, ati ọmọ wọn; ki nwọn ki o si mu wọn, ki nwọn si ma lọ. Dafidi si wipe, Ẹ má ṣe bẹ̃, enyin ará mi: Oluwa li o fi nkan yi fun wa, on li o si pa wa mọ, on li o si fi ẹgbẹ-ogun ti o dide si wa le wa lọwọ. Tani yio gbọ́ ti nyin ninu ọ̀ran yi? ṣugbọn bi ipin ẹniti o sọkalẹ lọ si ìja ti ri, bẹ̃ni ipin ẹniti o duro ti ẹrù; nwọn o si pin i bakanna. Lati ọjọ na lọ, o si pa a li aṣẹ, o si sọ ọ li ofin fun Israeli titi di oni yi. Dafidi si bọ̀ si Siklagi, o si rán ninu ikogun na si awọn agbà Juda, ati si awọn ọrẹ́ rẹ̀, o si wipe, Wõ, eyi li ẹ̀bun fun nyin, lati inu ikogun awọn ọta Oluwa wá. O si rán a si awọn ti o wà ni Beteli ati si awọn ti o wà ni gusu Ramoti, ati si awọn ti o wà ni Jattiri. Ati si awọn ti o wà ni Aroeri, ati si awọn ti o wà ni Sifmoti, ati si awọn ti o wà ni Eṣtemoa. Ati si awọn ti o wà ni Rakali, ati si awọn ti o wà ni ilu awọn Jerameeli, ati si awọn ti o wà ni ilu awọn ara Keni, Ati si awọn ti o wà ni Homa, ati si awọn ti o wà ni Koraṣani, ati si awọn ti o wà ni Ataki. Ati si awọn ti o wà ni Hebroni, ati si gbogbo ilu wọnni ti Dafidi tikararẹ̀ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ima rin kiri.

I. Sam 30:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ pada dé Sikilagi ní ọjọ́ kẹta, wọ́n rí i pé àwọn ará Amaleki ti gbógun ti Nẹgẹbu ati Sikilagi, wọ́n ṣẹgun Sikilagi, wọ́n sì sun ìlú náà níná; wọ́n kó gbogbo obinrin ati àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ lẹ́rú, àtọmọdé, àtàgbà, wọn kò sì pa ẹnikẹ́ni. Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé, wọ́n rí i pé wọ́n ti dáná sun ìlú náà, wọ́n sì ti kó àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin lẹ́rú. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sọkún títí tí ó fi rẹ̀ wọ́n. Wọ́n kó àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili opó Nabali lẹ́rú pẹlu. Dafidi sì wà ninu ìbànújẹ́, nítorí pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń gbèrò láti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ṣugbọn Dafidi túbọ̀ ní igbẹkẹle ninu OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Dafidi sọ fún Abiatari alufaa, ọmọ Ahimeleki, pé kí ó mú efodu wá. Abiatari sì mú un wá. Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?” OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.” Dafidi ati àwọn ẹgbẹta (600) ọmọlẹ́yìn rẹ̀, bá lọ, nígbà tí wọ́n dé odò Besori, apá kan ninu wọn dúró ní etí odò náà. Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò. Àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi rí ọmọkunrin ará Ijipti kan ninu oko, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dafidi, wọ́n fún un ní oúnjẹ ati omi, èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ati ìdì àjàrà meji. Nígbà tí ó jẹun tán, ó ní agbára nítorí pé kò tíì jẹun, kò sì mu omi fún ọjọ́ mẹta sẹ́yìn. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?” Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá. A ti jagun ní Nẹgẹbu ní agbègbè Kereti ati ní agbègbè Juda ati ní agbègbè Nẹgẹbu ti Kalebu, a sì sun Sikilagi níná.” Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?” Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.” Ó mú Dafidi lọ bá wọn. Àwọn ọmọ ogun náà fọ́n káàkiri, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ọpọlọpọ ìkógun tí wọ́n rí kó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati Juda. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Kò sì sí ẹni tí ó là ninu wọn, àfi irinwo ọdọmọkunrin tí wọ́n gun ràkúnmí sá lọ. Dafidi sì gba àwọn eniyan rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki náà kó, ati àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji. Kò sí ohun kan tí ó nù, Dafidi gba gbogbo àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki kó. Ó gba gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn pẹlu. Àwọn eniyan náà sì ń dá àwọn ẹran ọ̀sìn náà jọ níwájú Dafidi, wọ́n ń sọ pé, “Ìkógun Dafidi nìyí.” Dafidi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú pupọ, tí wọn kò lè kọjá odò, ṣugbọn tí wọ́n dúró lẹ́yìn odò Besori; àwọn náà wá pàdé Dafidi ati àwọn tí wọ́n bá a lọ. Dafidi sì kí wọn dáradára. Àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan burúkú ati òǹrorò láàrin àwọn tí wọ́n bá Dafidi lọ ní, “Nítorí pé wọn kò bá wa lọ, a kò ní fún wọn ninu ìkógun wa tí a gbà pada, àfi aya ati àwọn ọmọ wọn nìkan ni wọ́n lè gbà.” Ṣugbọn Dafidi dáhùn pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ ẹ̀ gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí gbogbo ohun tí OLUWA fifún wa. Òun ni ó pa wá mọ́ tí ó sì fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ ogun tí wọ́n dojú ìjà kọ wá. Kò sí ẹni tí yóo fara mọ́ àbá yín yìí. Gbogbo wa ni a óo jọ pín ìkógun náà dọ́gba-dọ́gba, ati àwọn tí ó lọ ati àwọn tí ó dúró ti ẹrù.” Láti ọjọ́ náà ni ó ti sọ ọ́ di òfin ati ìlànà ní Israẹli, títí di òní olónìí. Nígbà tí Dafidi pada dé Sikilagi, ó fi ẹ̀bùn ranṣẹ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí Juda; ó mú ninu ìkógun náà, ó ní, “Ẹ̀bùn yín nìyí lára ìkógun tí a kó láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá OLUWA.” Ó fi ranṣẹ sí àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli, ati àwọn tí wọ́n wà ní Ramoti ti Nẹgẹbu, ati Jatiri; ati àwọn tí wọ́n wà ní Aroeri, Sifimoti, ati ní Eṣitemoa; ní Rakali, ní àwọn ìlú Jerameeli, àwọn ìlú Keni, ní Homa, Boraṣani, ati ní Ataki, ní Heburoni ati ní gbogbo ìlú tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti rìn kiri.

I. Sam 30:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì ṣe nígbà ti Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì bọ̀ sí Siklagi ní ọjọ́ kẹta, àwọn ará Amaleki sì ti kọlu ìhà gúúsù, àti Siklagi, wọ́n sì ti kùn ún ní iná. Wọ́n sì kó àwọn obìnrin tí ń bẹ nínú rẹ̀ ní ìgbèkùn, wọn kò sì pa ẹnìkan, ọmọdé tàbí àgbà, ṣùgbọ́n wọ́n kó wọn lọ, wọ́n sì bá ọ̀nà tiwọn lọ. Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin sì wọ ìlú Siklagi, sì wò ó, a ti kùn ún ni iná; àti obìnrin wọn, àti ọmọkùnrin wọn àti ọmọbìnrin wọn ni a kó ni ìgbèkùn lọ. Dafidi àti àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún títí agbára kò fi sí fún wọn mọ́ láti sọkún. A sì kó àwọn aya Dafidi méjèèjì nígbèkùn lọ, Ahinoamu ará Jesreeli àti Abigaili aya Nabali ará Karmeli. Dafidi sì banújẹ́ gidigidi, nítorí pé àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ láti sọ ọ́ lókùúta, nítorí ti inú gbogbo àwọn ènìyàn náà sì bàjẹ́, olúkúlùkù ọkùnrin nítorí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti nítorí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣùgbọ́n Dafidi mú ara rẹ̀ lọ́kàn le nínú OLúWA Ọlọ́run rẹ̀. Dafidi sì wí fún Abiatari àlùfáà, ọmọ Ahimeleki pé, èmí bẹ̀ ọ́, mú efodu fún mi wá níhìn-ín yìí. Abiatari sì mú efodu náà wá fún Dafidi. Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ OLúWA wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?” Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa: nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.” Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi Àfonífojì Besori, apá kan sì dúró. Ṣùgbọ́n Dafidi àti irínwó ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, tiwọn kò lè kọjá odò Besori sì dúró lẹ́yìn. Wọ́n sì rí ará Ejibiti kan ní oko, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ, ó sì jẹ; wọ́n sì fún un ní omi mu. Wọ́n sì fún un ní àkàrà, èso ọ̀pọ̀tọ́ àti síírí àjàrà gbígbẹ́ méjì: nígbà tí ó sì jẹ ẹ́ tán, ẹ̀mí rẹ̀ sì sọjí: nítorí pé kò jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi ní ọjọ́ mẹ́ta ní ọ̀sán, àti ní òru. Dafidi sì bi í léèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ? Àti níbo ni ìwọ ti wá?” Òun sì wí pé, “Ọmọ ará Ejibiti ni èmi, ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ará Amaleki. Olúwa mi fi mí sílẹ̀, nítorí pé láti ọjọ́ mẹ́ta ni èmi ti ṣe àìsàn. Àwa sì gbé ogun lọ sí ìhà gúúsù tí ará Kereti, àti sí ìhà ti Juda, àti sí ìhà gúúsù ti Kalebu; àwa sì kun Siklagi ní iná.” Dafidi sì bi í léèrè pé, “Ìwọ lè mú mí sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun yìí lọ bí?” Òun sì wí pé, “Fi Ọlọ́run búra fún mi pé, ìwọ kì yóò pa mí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò sì fi mi lé olúwa mi lọ́wọ́; èmi yóò sì mú ọ sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun náà lọ.” Ó sì mú un sọ̀kalẹ̀, sì wò ó, wọ́n sì tàn ká ilẹ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ìkógun púpọ̀ tí wọ́n kó láti ilẹ̀ àwọn Filistini wá, àti láti ilẹ̀ Juda. Dafidi sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ọjọ́ kejì: kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irínwó ọmọkùnrin tí wọ́n gun ìbákasẹ tí wọ́n sì sá. Dafidi sì gbà gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki ti kó: Dafidi sì gba àwọn obìnrin rẹ̀ méjèèjì. Kò sì ṣí nǹkan tí ó kù fún wọn, kékeré tàbí ńlá, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin, tàbí ìkógun, tàbí gbogbo nǹkan tí wọ́n ti kó: Dafidi sì gba gbogbo wọn. Dafidi sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáájú àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, “Èyí yìí ni ìkógun ti Dafidi.” Dafidi sì wá sọ́dọ̀ igba ọkùnrin tí àárẹ̀ ti mú jú, tiwọn kò lè tọ́ Dafidi lẹ́yìn mọ́, ti òun ti fi sílẹ̀, ni àfonífojì Besori: wọ́n sì lọ pàdé Dafidi, àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀: Dafidi sì pàdé àwọn ènìyàn náà, ó sì kí wọn. Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Beliali nínú àwọn tí o bá Dafidi lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.” Dafidi sì wí pé, “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi: OLúWA ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́ ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́. Ta ni yóò gbọ́ tiyín nínú ọ̀ràn yìí? Ṣùgbọ́n bi ìpín ẹni tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ si ìjà ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ti ó dúró ti ẹrù; wọn ó sì pín in bákan náà.” Láti ọjọ́ náà lọ, ó sì pàṣẹ, ó sì sọ ọ di òfin fún Israẹli títí di òní yìí. Dafidi sì padà sí Siklagi, ó sì rán nínú ìkógun náà si àwọn àgbàgbà Juda, àti sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ni ẹ̀bùn fún un yín, láti inú ìkógun àwọn ọ̀tá OLúWA wa.” Ó sì rán an sí àwọn tí ó wà ni Beteli àti sí àwọn tí ó wà ní gúúsù tí Ramoti, àti sí àwọn tí ó wà ní Jattiri. Àti sí àwọn tí ó wà ní Aroeri, àti sí àwọn tí ó wà ní Sifimoti, àti sí àwọn tí ó wà ni Eṣitemoa. Àti si àwọn tí ó wà ni Rakeli, àti sí àwọn tí ó wà ní ìlú àwọn Jerahmeeli, àti sí àwọn tí ó wà ni ìlú àwọn ará Keni, àti sí àwọn tí ó wà ni Horma, àti sí àwọn ti ó wà ní Bori-Aṣani, àti sí àwọn tí ó wà ni Ataki. Àti àwọn tí ó wà ni Hebroni, àti sí gbogbo àwọn ìlú ti Dafidi tìkára rẹ̀ àti tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa ń rìn ká.