I. Sam 28:3-25
I. Sam 28:3-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Samueli sì ti kú, gbogbo Israeli si sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ni Rama ni ilu rẹ̀. Saulu si ti mu awọn abokusọ̀rọ-ọkunrin, ati awọn abokusọ̀rọ-obinrin kuro ni ilẹ na. Awọn Filistini si ko ara wọn jọ, nwọn wá, nwọn si do si Ṣunemu: Saulu si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si tẹdo ni Gilboa. Nigbati Saulu si ri ogun awọn Filistini na, on si bẹ̀ru, aiya rẹ̀ si warìri gidigidi. Nigbati Saulu si bere lọdọ Oluwa, Oluwa kò da a lohùn nipa alá, nipa Urimu tabi nipa awọn woli. Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ ba mi wá obinrin kan ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ, emi o si tọ ọ lọ, emi o si bere lọdọ rẹ̀. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Wõ, obinrin kan ni Endori ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ. Saulu si pa ara dà, o si mu aṣọ miran wọ̀, o si lọ, awọn ọmọkunrin meji si pẹlu rẹ̀, nwọn si wá si ọdọ obinrin na li oru: on si wipe, emi bẹ̀ ọ, fi ẹmi abokusọ̀rọ da nkan fun mi, ki o si mu ẹniti emi o darukọ rẹ̀ fun ọ wá oke fun mi. Obinrin na si da a lohùn pe, Wõ, iwọ sa mọ̀ ohun ti Saulu ṣe, bi on ti ke awọn abokusọ̀rọ obinrin, ati awọn abokusọ̀rọ ọkunrin kuro ni ilẹ na; njẹ eha ṣe ti iwọ dẹkùn fun ẹmi mi, lati mu ki nwọn pa mi? Saulu si bura fun u nipa Oluwa, pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ìya kan ki yio jẹ ọ nitori nkan yi. Obinrin na si bi i pe, Tali emi o mu wá soke fun ọ? on si wipe, Mu Samueli goke fun mi wá. Nigbati obinrin na si ri Samueli, o kigbe lohùn rara: obinrin na si ba Saulu sọrọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi tan mi jẹ? nitoripe Saulu ni iwọ iṣe. Ọba si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru; kini iwọ ri? obinrin na si wi fun Saulu pe, Emi ri ọlọrun kan nṣẹ́ ti ilẹ wá. O si bi i pe, Ẽ ti ri? o si wipe, Ọkunrin arugbo kan li o nṣẹ́ bọ̀; o si fi agbada bora. Saulu si mọ̀ pe, Samueli ni; o si tẹriba, o si wolẹ. Samueli si wi fun Saulu pe, Eṣe ti iwọ fi yọ mi lẹnu lati mu mi wá oke? Saulu si dahun o si wipe, Ipọnju nla ba mi; nitoriti awọn Filistini mba mi jagun, Ọlọrun si kọ̀ mi silẹ, kò si da mi lohùn mọ, nipa ọwọ́ awọn woli, tabi nipa alá; nitorina li emi si ṣe pè ọ, ki iwọ ki ole fi ohun ti emi o ṣe hàn mi. Samueli si wipe, O ti ṣe bi mi lere nigbati o jẹ pe, Oluwa ti kọ̀ ọ silẹ, o si wa di ọta rẹ? Oluwa si ṣe fun ara rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Oluwa si yà ijọba na kuro li ọwọ́ rẹ, o si fi fun aladugbo rẹ, ani Dafidi. Nitoripe iwọ kò gbọ́ ohùn Oluwa, iwọ kò si ṣe iṣẹ ibinu rẹ̀ si Amaleki, nitorina li Oluwa si ṣe nkan yi si ọ loni yi: Oluwa yio si fi Israeli pẹlu iwọ le awọn Filistini lọwọ: li ọla ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio pẹlu mi: Oluwa yio si fi ogun Israeli le awọn Filistini lọwọ́. Lojukanna ni Saulu ṣubu lulẹ gbọrọ bi o ti gùn, ẹ̀ru si bà a gidigidi, nitori ọ̀rọ Samueli; agbara kò si si fun u: nitoripe kò jẹun li ọjọ na t'ọsan t'oru. Obinrin na si tọ Saulu wá, o si ri i pe o wà ninu ibanujẹ pupọ, o si wi fun u pe, Wõ, iranṣẹbinrin rẹ ti gbọ́ ohùn rẹ, emi si ti fi ẹmi mi si ọwọ́ mi, emi si ti gbọ́ ọ̀rọ ti iwọ sọ fun mi. Njẹ, nisisiyi, emi bẹ ọ, gbọ́ ohùn iranṣẹbinrin rẹ, emi o si fi onjẹ diẹ siwaju rẹ; si jẹun, iwọ o si li agbara, nigbati iwọ ba nlọ li ọ̀na. Ṣugbọn on kọ̀, o si wipe, Emi kì yio jẹun. Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ̀, pẹlu obinrin na si rọ̀ ọ; on si gbọ́ ohùn wọn. O si dide kuro ni ilẹ, o si joko lori akete. Obinrin na si ni ẹgbọrọ malu kan ti o sanra ni ile; o si yara, o pa a o si mu iyẹfun, o si pò o, o si fi ṣe akara aiwu. On si mu u wá siwaju Saulu, ati siwaju awọn iranṣẹ rẹ̀; nwọn si jẹun. Nwọn si dide, nwọn lọ li oru na.

I. Sam 28:3-25 Yoruba Bible (YCE)
Samuẹli ti kú, àwọn Israẹli ti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti sin ín sí Rama ìlú rẹ̀. Saulu ti lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní ilẹ̀ Israẹli. Àwọn ará Filistia sì kó ara wọn jọ, wọ́n pa ibùdó sí Ṣunemu. Saulu náà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, wọ́n pa ibùdó sí Giliboa. Nígbà tí Saulu rí àwọn ọmọ ogun Filistini, àyà rẹ̀ já, ẹ̀rù sì bà á lọpọlọpọ. Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii. Saulu bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obinrin kan tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀, kí n lè lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ rẹ̀.” Wọn sì sọ fún un pé, “Obinrin kan wà ní Endori tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀.” Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.” Obinrin náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń dẹ tàkúté fún mi láti pa mí? O ṣá mọ ohun tí Saulu ọba ṣe, tí ó lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní Israẹli.” Saulu bá búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, ibi kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ nítorí èyí.” Obinrin náà dáhùn pé, “Ta ni kí n pè fún ọ?” Saulu dáhùn pe, “Pe Samuẹli fún mi.” Nígbà tí obinrin náà rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí? Àṣé Saulu ọba ni ọ́.” Saulu bá sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, sọ ohun tí o rí fún mi.” Obinrin náà dáhùn pé, “Mo rí ẹbọra kan, tí ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.” Saulu bèèrè pé, “Báwo ló rí?” Obinrin náà dáhùn pé, “Ọkunrin arúgbó kan ló ń bọ̀, ó sì fi aṣọ bora.” Saulu mọ̀ pé Samuẹli ni, ó sì tẹríba. Samuẹli bi Saulu pé, “Kí ló dé tí o fi ń yọ mí lẹ́nu? Kí ló dé tí o fi gbé mi dìde?” Saulu dáhùn pé, “Mo wà ninu ìpọ́njú ńlá nítorí pé àwọn ará Filistia ń bá mi jagun, Ọlọrun sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí pé kò fún mi ní ìtọ́sọ́nà, yálà láti ẹnu wolii kan ni, tabi lójú àlá. Nítorí náà ni mo ṣe pè ọ́, pé kí o lè sọ ohun tí n óo ṣe fún mi.” Samuẹli dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bi mí, nígbà tí OLUWA ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó sì ti di ọ̀tá rẹ? OLUWA ti ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó sọ láti ẹnu mi. Ó ti gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ, ó sì ti fún Dafidi, aládùúgbò rẹ. O ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, nítorí pé, o kò pa gbogbo àwọn ará Amaleki ati àwọn nǹkan ìní wọn run. Ìdí nìyí tí OLUWA fi ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ọ lónìí. OLUWA yóo fa ìwọ ati Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Ní ọ̀la ni ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ yóo kú; OLUWA yóo sì fa àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́.” Lẹ́sẹ̀kan náà, Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja, nítorí pé ohun ti Samuẹli sọ dẹ́rùbà á gidigidi, àárẹ̀ sì mú un nítorí pé, kò jẹun ní gbogbo ọ̀sán ati òru náà. Nígbà tí obinrin náà rí i pé ó wà ninu ọpọlọpọ ìbànújẹ́, ó sọ fún un pé, “Oluwa mi, mo fi ẹ̀mí mi wéwu láti ṣe ohun tí o bèèrè. Ǹjẹ́, nisinsinyii, jọ̀wọ́ ṣe ohun tí mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ fún mi. Jẹ́ kí n tọ́jú oúnjẹ fún ọ, kí o jẹ ẹ́, kí o lè lókun nígbà tí o bá ń lọ.” Saulu kọ̀, kò fẹ́ jẹun. Ṣugbon àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati obinrin náà bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹun. Ó gbà, ó dìde nílẹ̀, ó sì jókòó lórí ibùsùn. Obinrin náà yára pa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí ó ń sìn, ó sì ṣe burẹdi díẹ̀ láì fi ìwúkàrà sí i. Ó gbé e kalẹ̀ níwájú wọn; Saulu ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ jẹ ẹ́, wọ́n sì jáde lọ ní òru náà.
I. Sam 28:3-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Samuẹli sì ti kú, gbogbo Israẹli sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rama ní ìlú rẹ̀. Saulu sì ti mú àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà. Àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣunemu: Saulu sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gilboa. Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi. Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ OLúWA, OLúWA kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì. Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.” Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.” Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.” Saulu sì búra fún un nípa OLúWA pé, “Bí OLúWA ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.” Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?” Òun sì wí pé, “Mú Samuẹli gòkè wá fún mi.” Nígbà tí obìnrin náà sì rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Saulu sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Saulu ni ìwọ jẹ́.” Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?” Obìnrin náà sì wí fún Saulu pé, “Èmi rí ọlọ́run kan tí ń ti ilẹ̀ wá.” Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.” Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.” Saulu sì mọ̀ pé, Samuẹli ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀. Samuẹli sì i wí fún Saulu pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?” Saulu sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Filistini ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.” Samuẹli sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, OLúWA ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀. OLúWA sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: OLúWA sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dafidi. Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn OLúWA ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Amaleki nítorí náà ni OLúWA sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí. OLúWA yóò sì fi Israẹli pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Filistini lọ́wọ́: ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: OLúWA yóò sì fi ogun Israẹli lé àwọn Filistini lọ́wọ́.” Lójúkan náà ni Saulu ṣubú lulẹ̀ gbalaja níbí ó ṣe gùn tó, ẹ̀rù sì bà á gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ Samuẹli; agbára kò sí fún un; nítorí pé kò jẹun ní ọjọ́ náà tọ̀sán tòru. Obìnrin náà sì tọ Saulu wá, ó sì rí i pé ó wà nínú ìbànújẹ́ púpọ̀, ó sì wí fún un pé, “Wò ó, ìránṣẹ́bìnrin rẹ́ ti gbọ́ ohun rẹ̀, èmi sì ti fi ẹ̀mí mi sí ọwọ́ mi, èmi sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ti ìwọ sọ fún mi. Ǹjẹ́, nísinsin yìí èmi bẹ̀ ọ́, gbọ́ ohùn ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi yóò sì fi oúnjẹ díẹ̀ síwájú rẹ̀; sì jẹun, ìwọ yóò sì lágbára, nígbà tí ìwọ bá ń lọ lọ́nà.” Ṣùgbọ́n ó kọ̀, ó sì wí pé, “Èmi kì yóò jẹun.” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rọ̀ ọ́. Ó sì dìde kúrò ni ilẹ̀, ó sì jókòó lórí àkéte. Obìnrin náà sì ni ẹgbọrọ màlúù kan ti ó sanra ni ilé, ó sì yára, ó pa á, ó sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà àìwú. Ó sì mú un wá síwájú Saulu, àti síwájú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀; wọ́n sì jẹun. Wọ́n sì dìde, wọ́n lọ ní òru náà.