I. Sam 24:1-22

I. Sam 24:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe nigbati Saulu pada kuro lẹhin awọn Filistini, a si sọ fun u pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni aginju Engedi. Saulu si mu ẹgbẹdogun akọni ọkunrin ti a yàn ninu gbogbo Israeli, o si lọ lati wá Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ lori okuta awọn ewurẹ igbẹ. O si de ibi awọn agbo agutan ti o wà li ọ̀na, ihò kan si wà nibẹ, Saulu si wọ inu rẹ̀ lọ lati bo ẹsẹ rẹ̀: Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si mbẹ lẹba iho na. Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu. O si ṣe lẹhin eyi, aiya já Dafidi nitoriti on ke eti aṣọ Saulu. On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni. Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ. Dafidi si dide lẹhin na, o si jade kuro ninu iho na, o si kọ si Saulu pe, Oluwa mi, ọba. Saulu si wo ẹhìn rẹ̀, Dafidi si doju rẹ̀ bo ilẹ, o si tẹriba fun u. Dafidi si wi fun Saulu pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi ngbọ́ ọ̀rọ awọn enia pe, Wõ, Dafidi nwá ẹmi rẹ? Wõ, oju rẹ ri loni, bi Oluwa ti fi iwọ le mi li ọwọ́ loni ni iho nì: awọn kan ni ki emi ki o pa ọ: ṣugbọn emi dá ọ si; emi si wipe, emi ki yio nawọ́ mi si oluwa mi, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa li on iṣe. Pẹlupẹlu, baba mi, wõ, ani wo eti aṣọ rẹ li ọwọ́ mi; nitori emi ke eti aṣọ rẹ, emi ko si pa ọ, si wò, ki o si mọ̀ pe, kò si ibi tabi ẹ̀ṣẹ li ọwọ́ mi, emi kò si ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ ndọdẹ ẹmi mi lati gba a. Ki Oluwa ki o ṣe idajọ larin emi ati iwọ, ati ki Oluwa ki o gbẹsan mi lara rẹ; ṣugbọn ọwọ́ mi ki yio si lara rẹ. Gẹgẹ bi owe igba atijọ ti wi, Ìwabuburu a ma ti ọdọ awọn enia buburu jade wá; ṣugbọn ọwọ́ mi kì yio si lara rẹ. Nitori tani ọba Israeli fi jade? tani iwọ nlepa? okú aja, tabi eṣinṣin? Ki Oluwa ki o ṣe onidajọ, ki o si dajọ larin emi ati iwọ, ki o si wò ki o gbejà mi, ki o si gbà mi kuro li ọwọ́ rẹ. O si ṣe, nigbati Dafidi si dakẹ ọ̀rọ wọnyi isọ fun Saulu, Saulu si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Saulu si gbe ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. O si wi fun Dafidi pe, Iwọ ṣe olododo jù mi lọ: nitoripe iwọ ti fi ire san fun mi, emi fi ibi san fun ọ. Iwọ si fi ore ti iwọ ti ṣe fun mi hàn loni: nigbati o jẹ pe, Oluwa ti fi emi le ọ li ọwọ́, iwọ kò si pa mi. Nitoripe bi enia ba ri ọta rẹ̀, o le jẹ ki o lọ li alafia bi? Oluwa yio si fi ire san eyi ti iwọ ṣe fun mi loni. Wõ, emi mọ̀ nisisiyi pe, nitotọ iwọ o jẹ ọba, ilẹ-ọba Israeli yio si fi idi mulẹ si ọ lọwọ. Si bura fun mi nisisiyi li orukọ Oluwa, pe, iwọ kì yio ke iru mi kuro lẹhin mi, ati pe, iwọ ki yio pa orukọ mi run kuro ni idile baba mi. Dafidi si bura fun Saulu. Saulu si lọ si ile rẹ̀; ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ si iho na.

I. Sam 24:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Saulu bá àwọn ará Filistia jagun tán, wọ́n sọ fún un pé Dafidi wà ní aṣálẹ̀ Engedi. Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ọmọ ogun lára àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n lọ láti wá Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ní orí àwọn àpáta ewúrẹ́ ìgbẹ́. Nígbà tí Saulu dé ibi tí àwọn agbo aguntan kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó rí ihò àpáta ńlá kan lẹ́bàá ibẹ̀, ó sì wọ inú rẹ̀ lọ láti sinmi. Ihò náà jẹ́ ibi tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ farapamọ́ sí. Àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Dafidi sọ fún un pé, “Òní gan-an ni ọjọ́ tí OLUWA ti sọ fún ọ nípa rẹ̀, pé òun yóo fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, kí o lè ṣe é bí ó ti wù ọ́.” Dafidi bá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Saulu wà, ó sì gé etí aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọkàn Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí dá a lẹ́bi nítorí pé ó gé etí aṣọ Saulu. Ó sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Kí OLUWA pa mí mọ́ kúrò ninu ṣíṣe ibi sí oluwa mi, ẹni tí OLUWA ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọba. N kò gbọdọ̀ fọwọ́ mi kàn án, nítorí ẹni àmì òróró OLUWA ni.” Nípa báyìí Dafidi dá àwọn eniyan rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọ́n pa Saulu. Saulu jáde ninu ihò náà, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Dafidi jáde, ó pè é, ó ní, “Olúwa mi ọba,” bí Saulu ti wo ẹ̀yìn ni Dafidi dojúbolẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un. Ó sọ fún un pé, “Kí ló dé tí o fi ń gbọ́ ti àwọn tí wọ́n ń sọ pé mo fẹ́ pa ọ́? Nisinsinyii, o rí i dájú pé OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ ninu ihò àpáta. Àwọn kan ninu àwọn ọkunrin mi rọ̀ mí pé kí n pa ọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Mo sọ fún wọn pé, n kò ní fọwọ́ mi kàn ọ́, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́. Wò ó! Baba mi, wo etí aṣọ rẹ tí mo mú lọ́wọ́ yìí, ǹ bá pa ọ́ bí mo bá fẹ́, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, mo gé etí aṣọ rẹ. Ó yẹ kí èyí fihàn ọ́ pé n kò ní ìfẹ́ láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ, tabi láti pa ọ́. Ṣugbọn ìwọ ń lé mi kiri láti pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ọ́ níbi. Kí OLUWA dájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ. Kí ó sì jẹ ọ́ níyà fún ìwà burúkú tí ò ń hù sí mi, nítorí pé n kò ní ṣe ọ́ ní ibi kan. Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, àwọn eniyan burúkú a máa hùwà burúkú, ṣugbọn n kò ní ṣe ọ́ ní ibi kan. Ta ni ìwọ odidi ọba Israẹli ń gbìyànjú láti pa? Ta ni ò ń lépa? Ṣé òkú ajá lásán! Eṣinṣin lásánlàsàn! Kí OLUWA dájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ, kí ó gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò, kí ó gbèjà mi, kí ó sì gbà mí, lọ́wọ́ rẹ.” Nígbà tí Dafidi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Saulu dáhùn pé, “Ṣé ohùn rẹ ni mò ń gbọ́, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Ó wí fún Dafidi pé, “Eniyan rere ni ọ́, èmi ni eniyan burúkú, nítorí pé oore ni ò ń ṣe mí, ṣugbọn èmi ń ṣe ọ́ ní ibi. Lónìí, o ti fi bí o ti jẹ́ eniyan rere sí mi tó hàn mí, nítorí pé o kò pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA fi mí lé ọ lọ́wọ́. Ǹjẹ́ bí eniyan bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní alaafia? Kí OLUWA bukun ọ nítorí ohun tí o ṣe fún mi lónìí. Nisinsinyii, mo mọ̀ dájú pé o óo jọba ilẹ̀ Israẹli, ìjọba Israẹli yóo sì tẹ̀síwájú nígbà tìrẹ. Nítorí náà, búra fún mi pé o kò ní pa ìdílé mi run lẹ́yìn mi, ati pé o kò ní pa orúkọ mi rẹ́ ní ìdílé baba mi.” Dafidi bá búra fún Saulu. Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ pada sílé, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì pada sí ibi tí wọ́n sá pamọ́ sí.

I. Sam 24:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Saulu padà kúrò lẹ́yìn àwọn Filistini a sì sọ fún un pé, “Wò ó, Dafidi ń bẹ́ ni aginjù En-Gedi.” Saulu sì mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Israẹli ó sì lọ láti wá Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lórí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó. Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà. Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí OLúWA wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu. Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu. Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ OLúWA wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi ààmì òróró OLúWA yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni ààmì òróró OLúWA ni.” Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un. Dafidi sì wí fún Saulu pé, “Èéha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dafidi ń wa ẹ̀mí rẹ́’? Wò ó, ojú rẹ́ rí i lónìí, bí OLúWA ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò; àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ; ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí; ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni ààmì òróró OLúWA ni òun jẹ́.’ Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mí mi láti gbà á. Kí OLúWA ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, àti kí OLúWA ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ. Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwà búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ. “Nítorí ta ni ọba Israẹli fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin? Kí OLúWA ó ṣe onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, kí ó sì gbèjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.” Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Saulu, Saulu sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sọkún. Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ìre san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ. Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, OLúWA ti fi ẹ̀mí mi lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì pa mí. Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? OLúWA yóò sì fi ìre san èyí ti ìwọ ṣe fún mi lónìí. Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Israẹli yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ. Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ OLúWA, pé, ìwọ kì yóò gé irú-ọmọ mi kúrò lẹ́yìn mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orúkọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.” Dafidi sì búra fún Saulu. Saulu sì lọ sí ilé rẹ̀; ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ sí ihò náà.