I. Sam 22:1-23
I. Sam 22:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si kuro nibẹ, o si sa si iho Adullamu; nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ati idile baba rẹ̀ si gbọ́ ọ, nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ nibẹ. Olukuluku ẹniti o ti wà ninu ipọnju, ati olukuluku ẹniti o ti jẹ gbesè, ati olukuluku ẹniti o wà ninu ibanujẹ, si ko ara wọn jọ sọdọ rẹ̀, on si jẹ olori wọn: awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ si to iwọn irinwo ọmọkunrin. Dafidi si ti ibẹ̀ na lọ si Mispe ti Moabu: on si wi fun ọba Moabu pe, Jẹ ki baba ati iya mi, emi bẹ̀ ọ, wá ba ọ gbe, titi emi o fi mọ̀ ohun ti Ọlọrun yio ṣe fun mi. O si mu wọn wá siwaju ọba Moabu; nwọn si ba a gbe ni gbogbo ọjọ ti Dafidi fi wà ninu ihò na. Gadi woli si wi fun Dafidi pe, Máṣe gbe inu ihò na; yẹra, ki o si lọ si ilẹ Juda. Nigbana ni Dafidi si yẹra, o si lọ sinu igbo Hareti. Saulu si gbọ́ pe a ri Dafidi ati awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀; Saulu si ngbe ni Gibea labẹ igi kan ni Rama; ọkọ̀ rẹ̀ si mbẹ lọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ si duro tì i; Nigbana ni Saulu wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o duro tì i, pe, Njẹ, ẹ gbọ́, ẹnyin ara Benjamini, ọmọ Jesse yio ha fun olukuluku nyin ni oko ati ọgba ajara bi, ki o si sọ gbogbo nyin di olori ẹgbẹgbẹrun ati olori ọrọrun bi? Ti gbogbo nyin fi dimọlù si mi, ti kò fi si ẹnikan ti o sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi ti ba ọmọ Jesse mulẹ, bẹ̃ni kò si si ẹnikan ninu nyin ti o ṣanu mi, ti o si sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi mu ki iranṣẹ mi dide si mi lati ba dè mi, bi o ti ri loni? Doegi ara Edomu ti a fi jẹ olori awọn iranṣẹ Saulu, si dahun wipe, Emi ri ọmọ Jesse, o wá si Nobu, sọdọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu. On si bere lọdọ̀ Oluwa fun u, o si fun u li onjẹ o si fun u ni idà Goliati ara Filistia. Ọba si ranṣẹ pe Ahimeleki alufa, ọmọ Ahitubu ati gbogbo idile baba rẹ̀, awọn alufa ti o wà ni Nobu: gbogbo wọn li o si wá sọdọ ọba. Saulu si wipe, Njẹ gbọ́, iwọ ọmọ Ahitubu. On si wipe, Emi nĩ, oluwa mi. Saulu si wi fun u pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi dimọlù si mi, iwọ ati ọmọ Jesse, ti iwọ fi fun u li akara, ati idà, ati ti iwọ fi bere fun u lọdọ Ọlọrun, ki on ki o le dide si mi, lati ba dè mi, bi o ti ri loni? Ahimeleki si da ọba lohun, o si wipe, Tali oluwa rẹ̀ ti o ṣe enia re ninu gbogbo awọn iranṣẹ rẹ bi Dafidi, ẹniti iṣe ana ọba, ẹniti o ngbọ́ tirẹ, ti o si li ọla ni ile rẹ? Oni li emi o ṣẹṣẹ ma bere li ọwọ́ Ọlọrun fun u bi? ki eyini jinà si mi: ki ọba ki o máṣe ka nkankan si iranṣẹ rẹ̀ lọrùn, tabi si gbogbo idile baba mi: nitoripe iranṣẹ rẹ kò mọ̀ kan ninu gbogbo nkan yi, diẹ tabi pupọ. Ọba si wipe, Ahimeleki, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo idile baba rẹ. Ọba si wi fun awọn aṣaju ti ima sare niwaju ọba, ti o duro tì i, pe, Yipada ki ẹ si pa awọn alufa Oluwa; nitoripe ọwọ́ wọn wà pẹlu Dafidi, ati nitoripe, nwọn mọ̀ igbati on sa, nwọn kò si sọ ọ li eti mi. Ṣugbọn awọn iranṣẹ ọba ko si jẹ fi ọwọ́ wọn le awọn alufa Oluwa lati pa wọn. Ọba si wi fun Doegi pe, Iwọ, yipada, ki o si pa awọn alufa. Doegi ara Edomu si yipada, o si kọlu awọn alufa, o si pa li ọjọ na, àrunlelọgọrin enia ti nwọ aṣọ ọgbọ̀ Efodu. O si fi oju ida pa ara Nobu, ilu awọn alufa na ati ọkunrin ati obinrin, ọmọ wẹrẹ, ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agutan. Ọkan ninu awọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ti a npè ni Abiatari si bọ́; o si sa asala tọ Dafidi lọ. Abiatari si fi han Dafidi pe, Saulu pa awọn alufa Oluwa tan. Dafidi si wi fun Abiatari pe, emi ti mọ̀ ni ijọ na, nigbati Doegi ara Edomu nì ti wà nibẹ̀ pe, nitotọ yio sọ fun Saulu: nitori mi li a ṣe pa gbogbo idile baba rẹ. Iwọ joko nihin lọdọ mi, máṣe bẹ̀ru, nitoripe ẹniti nwá ẹmi mi, o nwá ẹmi rẹ: ṣugbọn lọdọ mi ni iwọ o wà li ailewu.
I. Sam 22:1-23 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi sá kúrò ní ìlú Gati, lọ sinu ihò òkúta kan lẹ́bàá Adulamu. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀ gbọ́, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, ati àwọn tí wọ́n jẹ gbèsè ati àwọn tí wọ́n wà ninu ìbànújẹ́ sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400) ọkunrin, ó sì jẹ́ olórí wọn. Dafidi kúrò níbẹ̀ lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Moabu, ó sọ fún ọba Moabu pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí baba ati ìyá mi dúró lọ́dọ̀ rẹ títí tí n óo fi mọ ohun tí Ọlọrun yóo ṣe fún mi.” Dafidi fi àwọn òbí rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ọba Moabu, wọ́n sì wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Dafidi wà ní ìpamọ́. Wolii Gadi sọ fún Dafidi pé, “Má dúró níbi ìpamọ́ yìí mọ́, múra, kí o lọ sí ilẹ̀ Juda.” Dafidi bá lọ sí igbó Hereti. Nígbà tí Saulu jókòó ní abẹ́ igi tamarisiki ní orí òkè kan ni Gibea, ọ̀kọ̀ rẹ̀ wà ní ọwọ́ rẹ̀, àwọn olórí ogun rẹ̀ sì dúró yí i ká, ó gbọ́ pé wọ́n rí Dafidi ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ará Bẹnjamini, ṣé ọmọ Jese yìí yóo fún olukuluku yín ní oko ati ọgbà àjàrà? Ṣé yóo sì fi olukuluku yín ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀? Ṣé nítorí náà ni ẹ ṣe gbìmọ̀ burúkú sí mi, tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò fi sọ fún mi pé ọmọ mi bá ọmọ Jese dá majẹmu. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì káàánú mi láàrin yín, kí ó sì sọ fún mi pé, ọmọ mi ń ran iranṣẹ mi lọ́wọ́ láti ba dè mí, bí ọ̀rọ̀ ti rí lónìí yìí.” Doegi ará Edomu, tí ó dúró láàrin àwọn olórí ogun Saulu dáhùn pé, “Mo rí Dafidi nígbà tí ó lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ní Nobu. Ahimeleki bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA, lẹ́yìn náà ó fún Dafidi ní oúnjẹ ati idà Goliati, ará Filistia.” Nítorí náà Saulu ọba ranṣẹ pe Ahimeleki ati gbogbo ìdílé rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alufaa ní Nobu, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Saulu ní, “Gbọ́ mi! Ìwọ ọmọ Ahitubu.” Ó dáhùn pé, “Mò ń gbọ́, oluwa mi.” Saulu bi í pé, “Kí ló dé tí ìwọ ati ọmọ Jese fi gbìmọ̀ burúkú sí mi? Tí o fún un ní oúnjẹ ati idà, tí o sì tún bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun. Dafidi ti lòdì sí mi báyìí, ó sì ti ba dè mí, láti pa mí.” Ahimeleki dáhùn pé, “Ta ló jẹ́ olóòótọ́ bíi Dafidi láàrin gbogbo àwọn olórí ogun rẹ? Ṣebí àna rẹ ni, ó sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun tí wọn ń ṣọ́ ọ ati eniyan pataki ninu ilé rẹ. Ǹjẹ́ èyí ha ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Rárá o! Nítorí náà kí ọba má ṣe ka ẹ̀sùn kankan sí èmi ati ìdílé baba mi lẹ́sẹ̀, nítorí pé, èmi iranṣẹ rẹ, kò mọ nǹkankan nípa ọ̀tẹ̀ tí Dafidi dì sí ọ.” Ọba dáhùn pé, “Ahimeleki, ìwọ ati ìdílé baba rẹ yóo kú.” Ọba bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ pa àwọn alufaa OLUWA nítorí pé wọ́n wà lẹ́yìn Dafidi, wọ́n mọ̀ pé ó ń sá lọ, wọn kò sì sọ fún mi.” Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun náà kọ̀ láti pa àwọn alufaa OLUWA. Ọba bá pàṣẹ fún Doegi pé, “Ìwọ, lọ pa wọ́n.” Doegi ará Edomu sì pa alufaa marunlelọgọrin, tí ń wọ aṣọ efodu. Saulu pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Nobu, ìlú àwọn alufaa, atọkunrin atobinrin, àtọmọdé, àtọmọ ọwọ́, ati mààlúù, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati aguntan, wọ́n sì pa gbogbo wọn. Ṣugbọn Abiatari, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Ahimeleki sá àsálà, ó sì lọ sọ́dọ̀ Dafidi. Ó sọ fún un bí Saulu ṣe pa àwọn alufaa OLUWA. Dafidi dá a lóhùn pé, “Nígbà tí mo ti rí Doegi níbẹ̀ ní ọjọ́ náà ni mo ti fura pé yóo sọ fún Saulu. Nítorí náà, ẹ̀bi ikú àwọn eniyan rẹ wà lọ́rùn mi. Dúró tì mí, má sì ṣe bẹ̀rù, nítorí pé Saulu tí ó fẹ́ pa ọ́, fẹ́ pa èmi pàápàá, ṣugbọn o óo wà ní abẹ ààbò níbí.”
I. Sam 22:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Adullamu; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀. Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irínwó ọmọkùnrin. Dafidi sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mispa tí Moabu: ó sì wí fún ọba Moabu pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.” Ó sì mú wọn wá síwájú ọba Moabu; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dafidi fi wà nínú ihò náà. Gadi wòlíì sí wí fún Dafidi pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Juda.” Nígbà náà ni Dafidi sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hereti. Saulu si gbọ́ pé a rí Dafidi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Saulu sì ń bẹ ní Gibeah lábẹ́ igi tamariski ní Rama; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í. Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Benjamini, ọmọ Jese yóò ha fún olúkúlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí? Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jese mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.” Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu. Òun sì béèrè lọ́dọ̀ OLúWA fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.” Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Ahitubu.” Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.” Saulu sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ Jese, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèrè fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.” Ahimeleki sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dafidi, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ní ilé rẹ. Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.” Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.” Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà OLúWA; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà OLúWA láti pa wọ́n. Ọba sì wí fún Doegi pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” Doegi ará Edomu sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin (85) ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu. Ó sì fi ojú idà pa ara Nobu, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu tí a ń pè ní Abiatari sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ Dafidi lọ. Abiatari sì fihan Dafidi pé Saulu pa àwọn àlùfáà OLúWA tán. Dafidi sì wí fún Abiatari pé, “Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Doegi ará Edomu ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún Saulu: nítorí mi ni a ṣe pa gbogbo ìdílé baba rẹ. Ìwọ jókòó níhìn-ín lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mí mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ: Ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.”