I. Sam 21:1-6
I. Sam 21:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?” Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí. Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn-ún tàbí ohunkóhun tí o bá rí.” Àlùfáà náà sí dá Dafidi lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́; Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!” Dafidi sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin láti ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta wá, tí èmí ti jáde. Gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, àti àkàrà náà sì wá dàbí àkàrà mìíràn, pàápàá nígbà tí ó jẹ́ pé òmíràn wà tí a yà sí mímọ́ lónìí nínú ohun èlò náà!” Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fi àkàrà mímọ́ fún un; nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn níbẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú OLúWA, láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò.
I. Sam 21:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si wá si Nobu sọdọ Ahimeleki alufa; Ahimeleki si bẹ̀ru lati pade Dafidi, o si wi fun u pe, Eha ti ri ti o fi ṣe iwọ nikan, ati ti kò si fi si ọkunrin kan ti o pẹlu rẹ? Dafidi si wi fun Ahimeleki alufa pe, ọba paṣẹ iṣẹ kan fun mi, o si wi fun mi pe, Máṣe jẹ ki ẹnikan mọ̀ idi iṣẹ na ti mo rán ọ, ati eyi ti emi ti paṣẹ fun ọ; emi si yàn awọn iranṣẹ mi si ibi bayi. Njẹ kili o wà li ọwọ́ rẹ? fun mi ni ìṣu akara marun li ọwọ́ mi, tabi ohunkohun ti o ba ri. Alufa na si da Dafidi lohùn o si wipe, Kò si akara miran li ọwọ́ mi bikoṣe akara mimọ́; bi awọn ọmọkunrin ba ti pa ara wọn mọ kuro lọdọ obinrin. Dafidi si da alufa na lohùn, o si wi fun u pe, Nitotọ a ti pa ara wa mọ kuro lọdọ obinrin lati iwọn ijọ mẹta wá, ti emi ti jade; gbogbo nkan awọn ọmọkunrin na li o mọ́, ati akara na si wa dabi akara miran, ye e pãpã nigbati o jẹ pe omiran wà ti a yà si mimọ́ loni ninu ohun elo na. Bẹ̃ni alufa na si fi akara mimọ́ fun u; nitoriti kò si akara miran nibẹ bikoṣe akara ifihan ti a ti ko kuro niwaju Oluwa, lati fi akara gbigbona sibẹ li ọjọ ti a ko o kuro.
I. Sam 21:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki alufaa, ní Nobu. Ahimeleki sì jáde pẹlu ìbẹ̀rù láti pàdé rẹ̀, ó sì bi í pé, “Ṣé kò sí nǹkan tí ìwọ nìkan fi dá wá, tí kò sí ẹnikẹ́ni pẹlu rẹ?” Ó dáhùn pé, “Ọba ni ó rán mi ní iṣẹ́ pataki kan, ó sì ti sọ fún mi pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ tí òun rán mi. Mo sì ti sọ fún àwọn iranṣẹ mi pé kí wọ́n pàdé mi ní ibìkan. Kí ni ẹ ní lọ́wọ́? Fún mi ní ìṣù burẹdi marun-un tabi ohunkohun tí o bá ní.” Alufaa náà sì dáhùn pé, “N kò ní burẹdi lásán, àfi èyí tí ó jẹ́ mímọ́. Mo lè fún ọ tí ó bá dá ọ lójú pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pa ara wọn mọ́, tí wọn kò sì bá obinrin lòpọ̀.” Dafidi dáhùn pé, “Àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi a máa pa ara wọn mọ́ nígbà tí a bá ń lọ fún iṣẹ́ tí kò ṣe pataki, kí á tó wá sọ ti iṣẹ́ yìí, tí ó jẹ́ iṣẹ́ pataki?” Alufaa kó àwọn burẹdi mímọ́ náà fún Dafidi, nítorí pé kò sí òmíràn níbẹ̀, àfi burẹdi ìfihàn tí wọ́n kó kúrò níwájú OLUWA láti fi òmíràn rọ́pò rẹ̀.