I. Sam 2:8-9
I. Sam 2:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
O gbe talaka soke lati inu erupẹ wá, o gbe alagbe soke lati ori ãtan wá, lati ko wọn jọ pẹlu awọn ọmọ-alade, lati mu wọn jogun itẹ ogo: nitori pe ọwọ̀n aiye ti Oluwa ni, o si ti gbe aiye ka ori wọn. Yio pa ẹṣẹ awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ, awọn enia buburu ni yio dakẹ li okunkun; nipa agbara kò si ọkunrin ti yio bori.
I. Sam 2:8-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀; ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀, láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba, kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá. Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé, òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn. “Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́, ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn; nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun.
I. Sam 2:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo: “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti OLúWA ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.