I. Sam 2:25-35

I. Sam 2:25-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji, onidajọ yio ṣe idajọ rẹ̀: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣẹ̀ sí Oluwa, tani yio bẹ̀bẹ fun u? Nwọn kò si fi eti si ohùn baba wọn, nitoriti Oluwa nfẹ pa wọn. Ọmọ na Samueli ndagba, o si ri ojurere lọdọ Oluwa, ati enia pẹlu. Ẹni Ọlọrun kan tọ Eli wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Gbangba ki emi fi ara hàn ile baba rẹ, nigbati nwọn mbẹ ni Egipti ninu ile Farao? Emi ko si yàn a kuro larin gbogbo ẹya Israeli lati jẹ alufa mi, lati rubọ lori pẹpẹ mi, lati fi turari jona, lati wọ efodi niwaju mi, emi si fi gbogbo ẹbọ ti ọmọ Israeli ima fi iná sun fun idile baba rẹ? Eṣe ti ẹnyin fi tapa si ẹbọ ati ọrẹ mi, ti mo pa li aṣẹ ni ibujoko mi: iwọ si bu ọla fun awọn ọmọ rẹ jù mi lọ, ti ẹ si fi gbogbo ãyo ẹbọ Israeli awọn enia mi mu ara nyin sanra? Nitorina Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti wi nitotọ pe, ile rẹ ati ile baba rẹ, yio ma rin niwaju mi titi: ṣugbọn nisisiyi Oluwa wipe, ki a má ri i; awọn ti o bu ọla fun mi li emi o bu ọla fun, ati awọn ti kò kà mi si li a o si ṣe alaikasi. Kiye si i, ọjọ wọnni mbọ̀, ti emi o ke iru rẹ kurò, ati iru baba rẹ, kì yio si arugbo kan ninu ile rẹ. Iwọ o ri wahala ti Agọ, ninu gbogbo ọlà ti Ọlọrun yio fi fun Israeli: kì yio si si arugbo kan ninu ile rẹ lailai. Ọkunrin ti iṣe tirẹ, ẹniti emi kì yio ke kuro ni ibi pẹpẹ mi, yio wà lati ma pọn ọ loju, lati ma bà ọ ninu jẹ; gbogbo iru ọmọ ile rẹ ni yio kú li abọ̀ ọjọ wọn. Eyi li o jẹ àmi fun ọ, ti yio wá si ori ọmọ rẹ mejeji, si ori Hofni ati Finehasi, ni ọjọ kanna li awọn mejeji yio kú. Emi o gbe alufa olododo kan dide, ẹniti yio ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu mi, ati ọkàn mi; emi o si kọ ile kan ti yio duro ṣinṣin fun u; yio si ma rin niwaju ẹni-ororo mi li ọjọ gbogbo.

I. Sam 2:25-35 Yoruba Bible (YCE)

Bí ẹnìkan bá ṣẹ eniyan, Ọlọrun lè parí ìjà láàrin wọn; ṣugbọn bí eniyan bá ṣẹ OLUWA, ta ni yóo bá a bẹ̀bẹ̀?” Ṣugbọn àwọn ọmọ Eli kò gbọ́ ti baba wọn, nítorí pé OLUWA ti pinnu láti pa wọ́n. Samuẹli ń dàgbà sí i, ó sì ń bá ojurere OLUWA ati ti eniyan pàdé. OLUWA rán wolii kan sí Eli, kí ó sọ fún un pé, “Mo fara han ìdílé baba rẹ nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹrú Farao ọba ní ilẹ̀ Ijipti. Ninu gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní Israẹli, ìdílé baba rẹ nìkan ni mo yàn láti jẹ́ alufaa mi, pé kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ alufaa níbi pẹpẹ, kí ẹ máa sun turari kí ẹ máa wọ ẹ̀wù efodu, kí ẹ sì máa wádìí nǹkan lọ́wọ́ mi. Mo fún wọn ní gbogbo ẹbọ sísun tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí mi. Kí ló dé tí o fi ń ṣe ojúkòkòrò sí ọrẹ ati ẹbọ tí mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn eniyan mi, tí o sì gbé àwọn ọmọ rẹ ga jù mí lọ; tí wọn ń jẹ àwọn ohun tí ó dára jùlọ lára ohun tí àwọn eniyan mi bá fi rúbọ sí mi ní àjẹyọkùn? Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ni mo sọ pé, mo ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀ pé, ìdílé rẹ ati ìdílé baba rẹ ni yóo máa jẹ́ alufaa mi títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, èmi OLUWA náà ni mo sì tún ń sọ pé, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n bá bu ọlá fún mi ni n óo máa bu ọlá fún, àwọn tí wọn kò bá kà mí sí, n kò ní ka àwọn náà sí. Wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí n óo run gbogbo àwọn ọdọmọkunrin ìdílé rẹ ati ti baba rẹ kúrò, débi pé kò ní sí àgbà ọkunrin kan ninu ìdílé rẹ mọ́. Pẹlu ìbànújẹ́ ni o óo máa fi ìlara wo bí OLUWA yóo ṣe bukun Israẹli, kò sì ní sí àgbàlagbà ọkunrin ninu ìdílé rẹ mọ́ lae. Ẹnìkan ninu ìdílé rẹ tí n kò ní mú kúrò ní ibi pẹpẹ mi, yóo sọkún títí tí ojú rẹ̀ yóo fi di bàìbàì, ọkàn rẹ̀ yóo sì kún fún ìbànújẹ́. Gbogbo ọmọ inú ilé rẹ ni wọn yóo fi idà pa ní ọjọ́ àìpé. Ní ọjọ́ kan náà ni àwọn ọmọ rẹ mejeeji, Hofini ati Finehasi, yóo kú. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fún ọ pé gbogbo ohun tí mo sọ ni yóo ṣẹ. N óo yan alufaa mìíràn fún ara mi, tí yóo ṣe olóòótọ́ sí mi, tí yóo sì ṣe gbogbo ohun tí mo bá fẹ́ kí ó ṣe. N óo fi ìdí ìdílé rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì máa ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú ẹni àmì òróró mi.

I. Sam 2:25-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí OLúWA, ta ni yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí OLúWA ń fẹ́ pa wọ́n. Ọmọ náà Samuẹli ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ OLúWA, àti ènìyàn pẹ̀lú. Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Eli wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni OLúWA wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ, nígbà tí wọ́n ń bẹ ní Ejibiti nínú ilé Farao. Èmi sì yàn án kúrò láàrín gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti jẹ́ àlùfáà mi, láti rú ẹbọ lórí pẹpẹ mi, láti fi tùràrí jóná, láti wọ efodu níwájú mi, èmi sì fi gbogbo ẹbọ tí ọmọ Israẹli máa ń fi iná sun fún ìdílé baba rẹ̀. Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo pàṣẹ ní ibùjókòó mi: ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jù mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Israẹli àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’ “Nítorí náà OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí OLúWA wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí. Kíyèsi i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ. Ìwọ yóò rí wàhálà ti Àgọ́, nínú gbogbo ọlá tí Ọlọ́run yóò fi fún Israẹli; kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ láéláé. Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ní ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sọkún yọ lójú àti láti banújẹ́: Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn. “ ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, Hofini àti Finehasi, yóò jẹ́ ààmì fún ọ—àwọn méjèèjì yóò kú ní ọjọ́ kan náà. Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi: Èmi yóò fi ẹsẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo.