I. Sam 2:1-10

I. Sam 2:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Hana bá gbadura báyìí pé: “Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA, Ó sọ mí di alágbára; mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín, nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là. “Kò sí ẹni mímọ́ bíi OLUWA, kò sí ẹlòmíràn, àfi òun nìkan ṣoṣo. Kò sí aláàbò kan tí ó dàbí Ọlọrun wa. Má sọ̀rọ̀ pẹlu ìgbéraga mọ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìgbéraga ti ẹnu rẹ jáde, nítorí Ọlọrun tí ó mọ ohun gbogbo ni OLUWA, gbogbo ohun tí ẹ̀dá bá ṣe ni ó sì máa ń gbéyẹ̀wò. Ọrun àwọn alágbára dá, ṣugbọn àwọn aláìlágbára di alágbára. Àwọn tí wọ́n rí oúnjẹ jẹ lájẹyó rí ti di ẹni tí ń fi ara wọn ṣọfà nítorí oúnjẹ, ṣugbọn àwọn tí ebi ti ń pa tẹ́lẹ̀ rí tí ń jẹ àjẹyó. Àgàn ti di ọlọ́mọ meje, ọlọ́mọ pupọ ti di aláìní. OLUWA ni ó lè pa eniyan tán, kí ó sì tún jí i dìde; òun ni ó lè múni lọ sinu isà òkú, tí ó sì tún lè fani yọ kúrò níbẹ̀. OLUWA ni ó lè sọni di aláìní, òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀. Òun ni ó ń gbéni ga, òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀. OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀; ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀, láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba, kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá. Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé, òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn. “Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́, ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn; nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun. Àwọn ọ̀tá OLUWA yóo parun; OLUWA yóo sán ààrá pa wọ́n láti ojú ọ̀run wá. OLUWA yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé, yóo fún ọba rẹ̀ lágbára, yóo sì fún ẹni tí ó yàn ní ìṣẹ́gun.”

I. Sam 2:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Hana sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí OLúWA; Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí OLúWA. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀. “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi OLúWA; kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ; kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa. “Má ṣe halẹ̀; má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni OLúWA, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà. “Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́, àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè. Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe, àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní. Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje. Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára. “OLúWA pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde. OLúWA sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè. Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo: “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti OLúWA ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn. “Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí. A ó fọ́ àwọn ọ̀tá OLúWA túútúú; láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn; OLúWA yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.

I. Sam 2:1-10

I. Sam 2:1-10 YBCVI. Sam 2:1-10 YBCVI. Sam 2:1-10 YBCVI. Sam 2:1-10 YBCV