I. Sam 18:5-30

I. Sam 18:5-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

Dafidi a si ma lọ si ibikibi ti Saulu rán a, a ma huwa ọlọgbọ́n: Saulu si fi i jẹ olori ogun, o si dara loju gbogbo awọn enia, ati pẹlupẹlu loju awọn iranṣẹ Saulu. O si ṣe, bi nwọn ti de, nigbati Dafidi ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, awọn obinrin si ti gbogbo ilu Israeli jade wá, nwọn nkọrin nwọn si njo lati wá ipade Saulu ọba, ti awọn ti ilù, ati ayọ̀, ati duru. Awọn obinrin si ndá, nwọn si ngbe orin bi nwọn ti nṣire, nwọn si nwipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirẹ̀. Saulu si binu gidigidi, ọ̀rọ na si buru loju rẹ̀ o si wipe, Nwọn fi ẹgbẹgbarun fun Dafidi, nwọn si fi ẹgbẹgbẹrun fun mi, kili o si kù fun u bikoṣe ijọba. Saulu si nfi oju ilara wo Dafidi lati ọjọ na lọ. O si ṣe ni ijọ keji, ti ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá si ba le Saulu, on si sọtẹlẹ li arin ile; Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ ṣire lara duru bi igba atẹhinwa; ẹṣín kan mbẹ lọwọ Saulu. Saulu si sọ ẹṣín ti o wà lọwọ rẹ̀ na; o si wipe, Emi o pa Dafidi li apa mọ́ ogiri. Dafidi si yẹra kuro niwaju rẹ lẹ̃meji. Saulu si bẹ̀ru Dafidi, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa kọ̀ Saulu. Nitorina Saulu si mu u kuro lọdọ rẹ̀, o si fi i jẹ olori ogun ẹgbẹrun kan, o si nlọ, o si mbọ̀ niwaju awọn enia na. Dafidi si ṣe ọlọgbọ́n ni gbogbo iṣe rẹ̀; Oluwa si wà pẹlu rẹ̀. Nigbati Saulu ri pe, o nhuwa ọgbọ́n gidigidi, o si mbẹ̀ru rẹ̀. Gbogbo Israeli ati Juda si fẹ Dafidi, nitoripe a ma lọ a si ma bọ̀ niwaju wọn. Saulu si wi fun Dafidi pe, Wo Merabu ọmọbinrin mi, eyi agbà, on li emi o fi fun ọ li aya: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alagbara fun mi, ki o si ma ja ija Oluwa. Nitoriti Saulu ti wi bayi pe, Màṣe jẹ ki ọwọ́ mi ki o wà li ara rẹ̀; ṣugbọn jẹ ki ọwọ́ awọn Filistini ki o wà li ara rẹ̀. Dafidi si wi fun Saulu pe, Tali emi, ati ki li ẹmi mi, tabi idile baba mi ni Israeli, ti emi o fi wa di ana ọba. O si ṣe, li akoko ti a ba fi Merabu ọmọbinrin Saulu fun Dafidi, li a si fi i fun Adrieli ara Meholati li aya. Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹran Dafidi, nwọn si wi fun Saulu: nkan na si tọ li oju rẹ̀. Saulu si wipe, Emi o fi i fun u, yio si jẹ idẹkùn fun u, ọwọ́ awọn Filistini yio si wà li ara rẹ̀. Saulu si wi fun Dafidi pe, Iwọ o wà di ana mi loni, ninu mejeji. Saulu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ lọ ba Dafidi sọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ pe, Kiyesi i, inu ọba dùn si ọ jọjọ, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ li o si fẹ ọ, njẹ nitorina jẹ ana ọba. Awọn iranṣẹ Saulu si sọ̀rọ wọnni li eti Dafidi. Dafidi si wipe, O ha ṣe nkan ti o fẹrẹ loju nyin lati jẹ ana ọba? Talaka li emi ati ẹni ti a kò kà si. Awọn iranṣẹ Saulu si wa irò fun u, pe, Ọrọ bayi ni Dafidi sọ. Saulu si wipe, Bayi li ẹnyin o sọ fun Dafidi, ọba kò sa fẹ ohun-ana kan bikoṣe ọgọrun ẹfa abẹ Filistini, ati lati gbẹsan lara awọn ọta ọba; ṣugbọn Saulu rò ikú Dafidi lati ọwọ́ awọn Filistini wá. Nigbati awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ̀rọ wọnyi fun Dafidi, ohun na si dara li oju Dafidi lati di ana ọba: ọjọ kò si iti pe. Dafidi si dide, o lọ, on ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, o si pa igba ọmọkunrin ninu awọn Filistini; Dafidi si mu ẹfa abẹ wọn wá, nwọn si kà wọn pe fun ọba, ki on ki o le jẹ ana ọba. Saulu si fi Mikali ọmọ rẹ obinrin fun u li aya. Saulu si ri o si mọ̀ pe, Oluwa wà pẹlu Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹ ẹ. Saulu si bẹ̀ru Dafidi siwaju ati siwaju: Saulu si wa di ọtá Dafidi titi. Awọn ọmọ-alade Filistini si jade lọ: o si ṣe, lẹhin igbati nwọn lọ, Dafidi si huwa ọlọgbọ́n ju gbogbo awọn iranṣẹ Saulu lọ; orukọ rẹ̀ si ni iyìn jọjọ.

I. Sam 18:5-30 Yoruba Bible (YCE)

Dafidi ń ṣe àṣeyọrí ninu àwọn iṣẹ́ tí Saulu ń rán an. Nítorí náà, Saulu fi ṣe ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun rẹ̀. Èyí sì tẹ́ àwọn olórí yòókù lọ́rùn. Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin. Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé, “Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀, ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.” Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.” Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi. Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu. Ó ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi ní àgúnmọ́ ògiri. Ó ju ọ̀kọ̀ náà nígbà meji, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́ lẹẹmejeeji. Saulu bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn OLUWA kọ òun sílẹ̀. Saulu mú un kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó fi ṣe olórí ẹgbẹrun ọmọ ogun, Dafidi sì ń darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀. Saulu tún bẹ̀rù Dafidi sí i nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀. Ṣugbọn gbogbo àwọn ará Israẹli ati Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó jẹ́ olórí tí ń ṣe àṣeyọrí. Saulu sọ fún Dafidi pé, “Merabu ọmọbinrin mi àgbà nìyí, n óo fún ọ kí o fi ṣe aya, ṣugbọn o óo jẹ́ ọmọ ogun mi, o óo sì máa ja ogun OLUWA.” Nítorí Saulu rò ninu ara rẹ̀ pé, àwọn Filistini ni yóo pa Dafidi, òun kò ní fi ọwọ́ ara òun pa á. Dafidi dáhùn pé, “Ta ni èmi ati ìdílé baba mi tí n óo fi di àna ọba?” Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó yẹ kí Saulu fi Merabu fún Dafidi, Adirieli ará Mehola ni ó fún. Ṣugbọn Mikali ọmọbinrin Saulu nífẹ̀ẹ́ Dafidi; nígbà tí Saulu gbọ́, inú rẹ̀ dùn sí i. Ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo fi Mikali fún Dafidi kí ó lè jẹ́ ìdẹkùn fún un, àwọn Filistini yóo sì rí i pa.” Saulu ṣèlérí fún Dafidi lẹẹkeji pé, “O óo di àna mi.” Saulu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ lọ bá Dafidi sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ pé, inú ọba dùn sí i lọpọlọpọ, ati pé gbogbo àwọn iranṣẹ ọba fẹ́ràn rẹ̀, nítorí náà ó yẹ kí ó fẹ́ ọmọ ọba.” Nígbà tí wọ́n sọ èyí fún Dafidi, ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe nǹkan kékeré ni láti jẹ́ àna ọba, talaka ni mí, èmi kì í sì í ṣe eniyan pataki.” Àwọn iranṣẹ náà sọ èsì tí Dafidi fún wọn fún Saulu. Saulu sì rán wọn pé kí wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Ọba kò bèèrè ẹ̀bùn igbeyawo kankan lọ́wọ́ rẹ ju ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san lára àwọn ọ̀tá ọba.” Saulu rò pé àwọn ará Filistia yóo tipa bẹ́ẹ̀ pa Dafidi. Nígbà tí àwọn iranṣẹ Saulu jíṣẹ́ fún Dafidi, inú rẹ̀ dùn, ó sì gbà láti di àna ọba. Kí ó tó di ọjọ́ igbeyawo, Dafidi ati àwọn jagunjagun rẹ̀ lọ pa igba (200) Filistini, ó sì kó awọ adọ̀dọ́ wọn wá fún ọba, kí ó lè fẹ́ ọmọ ọba. Saulu sì fi ọmọbinrin rẹ̀, Mikali, fún Dafidi. Saulu rí i dájúdájú pé OLUWA wà pẹlu Dafidi ati pé Mikali ọmọ òun fẹ́ràn Dafidi. Nítorí náà, ó bẹ̀rù Dafidi sí i, ó sì ń bá Dafidi ṣe ọ̀tá títí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ninu gbogbo ogun tí wọ́n bá àwọn ara Filistia jà, Dafidi ní ìṣẹ́gun ju gbogbo àwọn olórí ogun Saulu yòókù lọ. Ó sì jẹ́ olókìkí láàrin wọn.

I. Sam 18:5-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ohunkóhun tí Saulu bá rán an láti ṣe, Dafidi máa ṣe ní àṣeyọrí, Saulu náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrín àwọn ológun. Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Saulu lọ́rùn pẹ̀lú. Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti pa Filistini, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Israẹli wá láti pàdé ọba Saulu pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tambori àti ohun èlò orin olókùn. Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé: “Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀ Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbàárún ní tirẹ̀.” Saulu sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dafidi pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárún” ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?” Láti ìgbà náà lọ ni Saulu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlara wo Dafidi. Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Saulu, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dafidi sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Saulu sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dafidi pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dafidi yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì. Saulu sì ń bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLúWA wà pẹ̀lú Dafidi, ṣùgbọ́n ó ti fi Saulu sílẹ̀. Ó sì lé Dafidi jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dafidi ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun. Dafidi sì ṣe ọlọ́gbọ́n ní gbogbo ìṣe rẹ̀, nítorí tí OLúWA wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí Saulu rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli àti Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó darí wọn lọ ní ìgbòkègbodò ogun wọn. Saulu wí fún Dafidi pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Merabu. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun OLúWA.” Nítorí tí Saulu wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí i. Jẹ́ kí àwọn Filistini ṣe èyí.” Ṣùgbọ́n Dafidi wí fún Saulu pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Israẹli, tí èmi yóò di àna ọba?” Nígbà tí àkókò tó fún Merabu, ọmọbìnrin Saulu, láti fi fún Dafidi, ni a sì fi fún Adrieli ará Mehola ní aya. Nísinsin yìí ọmọbìnrin Saulu Mikali sì fẹ́ràn Dafidi, nígbà tí wọ́n sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn. Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ ìkẹ́kùn fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Filistini lè wà lára rẹ̀.” Nígbà náà ni Saulu wí fún Dafidi pé, “Nísinsin yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna án mi.” Saulu pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dafidi ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsin yìí jẹ́ àna ọba.’ ” Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dafidi. Ṣùgbọ́n Dafidi wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.” Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Saulu sọ fún un ohun tí Dafidi sọ, Saulu dáhùn pé, “Sọ fún Dafidi pé, ‘ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn-ún Filistini lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ ” Èrò Saulu ni wí pé kí Dafidi ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Filistini. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dafidi, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá, Dafidi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Filistini. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó ba à lè jẹ́ àna ọba. Saulu sì fi ọmọ obìnrin Mikali fún un ní aya. Nígbà tí Saulu sì wá mọ̀ pé OLúWA wà pẹ̀lú Dafidi tí ọmọbìnrin rẹ̀ Mikali sì fẹ́ràn Dafidi, Saulu sì tún wá bẹ̀rù Dafidi síwájú àti síwájú, Saulu sì wá di ọ̀tá Dafidi fún gbogbo ọjọ́ rẹ̀ tókù. Àwọn ọmọ-aládé Filistini tún tẹ̀síwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dafidi ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Saulu lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀.