I. Sam 17:38-39
I. Sam 17:38-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Saulu si fi gbogbo ihamọra ogun rẹ̀ wọ̀ Dafidi, o si fi ibori idẹ kan bò o li ori; o si fi ẹwu ti a fi irin adarọ pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ. Dafidi si di ida rẹ̀ mọ ihamọra rẹ̀, on si gbiyanju lati lọ, on kò sa iti dan a wò. Dafidi si wi fun Saulu pe, Emi kò le ru wọnyi lọ, nitoripe emi kò idan a wò. Dafidi si tu wọn kuro li ara rẹ̀.
I. Sam 17:38-39 Yoruba Bible (YCE)
Saulu gbé ihamọra ogun rẹ̀ wọ Dafidi, ó fi àṣíborí idẹ kan dé e lórí, ó sì gbé ẹ̀wù tí a fi irin pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ́. Dafidi di idà Saulu mọ́ ihamọra náà, ó sì gbìyànjú láti rìn, ṣugbọn kò lè rìn nítorí pé kò wọ ihamọra ogun rí. Dafidi sọ fún Saulu pé, “N kò lè lo ihamọra yìí, nítorí pé n kò wọ̀ ọ́ rí.” Dafidi bá tú wọn kúrò lára rẹ̀.
I. Sam 17:38-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Saulu fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ wọ Dafidi, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìhámọ́ra ogun, ó sì fi ìbòrí idẹ kan bò ó ní orí. Dafidi si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára. Ó sọ fún Saulu pé, “Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára.” Ó sì bọ́ wọn kúrò.