I. Sam 17:36-37
I. Sam 17:36-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iranṣẹ rẹ pa ati kiniun ati amọtẹkun na: alaikọla Filistini yi yio si dabi ọkan ninu wọn, nitoripe on ti pe ogun Ọlọrun alãye ni ijà. Dafidi si wipe, Oluwa ti o gbà mi lọwọ́ kiniun ati lọwọ́ amọtẹkun, on na ni yio gbà mi lọwọ́ Filistini yi. Saulu si wi fun Dafidi pe, Lọ, Oluwa yio si pẹlu rẹ.

I. Sam 17:36-37 Yoruba Bible (YCE)
Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà. OLUWA tí ó gbà mí lọ́wọ́ kinniun ati beari yóo gbà mí lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “Máa lọ, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ.”
I. Sam 17:36-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Filistini yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà. OLúWA tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu wí fún Dafidi pé, “Lọ kí OLúWA wà pẹ̀lú rẹ.”