I. Sam 17:34-37
I. Sam 17:34-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si wi fun Saulu pe, Nigbati iranṣẹ rẹ nṣọ agutan baba rẹ̀, kiniun kan si wá, ati amọtẹkun kan, o si gbe ọdọ agutan kan lati inu agbo. Mo si jade tọ̀ ọ, mo si lù u, mo si gbà a kuro li ẹnu rẹ̀: nigbati o si dide si mi, mo gbá irugbọ̀n rẹ̀ mu, mo si lù u, mo si pa a. Iranṣẹ rẹ pa ati kiniun ati amọtẹkun na: alaikọla Filistini yi yio si dabi ọkan ninu wọn, nitoripe on ti pe ogun Ọlọrun alãye ni ijà. Dafidi si wipe, Oluwa ti o gbà mi lọwọ́ kiniun ati lọwọ́ amọtẹkun, on na ni yio gbà mi lọwọ́ Filistini yi. Saulu si wi fun Dafidi pe, Lọ, Oluwa yio si pẹlu rẹ.
I. Sam 17:34-37 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi dáhùn pé, “Ìgbàkúùgbà tí èmi iranṣẹ rẹ bá ń ṣọ́ agbo aguntan baba mi, tí kinniun tabi ẹranko beari bá gbé ọ̀kan ninu aguntan náà, n óo tẹ̀lé e lọ, n óo lù ú, n óo sì gba aguntan náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Bí ó bá sì kọjú ìjà sí mi, n óo di ọ̀fun rẹ̀ mú, n óo sì pa á. Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà. OLUWA tí ó gbà mí lọ́wọ́ kinniun ati beari yóo gbà mí lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu bá sọ fún Dafidi pé, “Máa lọ, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ.”
I. Sam 17:34-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀. Nígbà tí kìnnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó. Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á. Ìránṣẹ́ rẹ ti pa kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn, aláìkọlà Filistini yìí yóò jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pe ogun Ọlọ́run alààyè ní ìjà. OLúWA tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìhàlẹ̀ kìnnìún àti ti ìhàlẹ̀ àmọ̀tẹ́kùn yóò gbà mí kúrò lọ́wọ́ Filistini yìí.” Saulu wí fún Dafidi pé, “Lọ kí OLúWA wà pẹ̀lú rẹ.”