I. Sam 16:12-13
I. Sam 16:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ranṣẹ, o si mu u wá. On si jẹ ẹnipupa, ti o lẹwà loju, o si dara lati ma wò. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si fi ororo sà a li àmi: nitoripe on na li eyi. Nigbana ni Samueli mu iwo ororo, o si fi yà a si ọ̀tọ larin awọn arakunrin rẹ̀; Ẹmi Oluwa si bà le Dafidi lati ọjọ na lọ, Samueli si dide, o si lọ si Rama.
I. Sam 16:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Jese ranṣẹ lọ mú un wá. Ọmọ náà jẹ́ ọmọ pupa, ojú rẹ̀ dára ó sì lẹ́wà. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Dìde, kí o ta òróró sí i lórí nítorí pé òun ni mo yàn.” Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo tí òróró wà ninu rẹ̀, ó ta òróró náà sí i lórí láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, Ẹ̀mí OLUWA sì bà lé Dafidi láti ọjọ́ náà lọ. Samuẹli bá gbéra, ó pada sí Rama.
I. Sam 16:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi. Nígbà náà ni OLúWA wí pé, “Dìde kí o sì fi òróró yàn án, òun ni ẹni náà.” Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mí mímọ́ OLúWA wá sí orí Dafidi nínú agbára. Samuẹli sì lọ sí Rama.